Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn Herodotus tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì sọ pé nígbà tí àwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ogun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà wọn.