Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣeé ṣe kí àkàwé Jésù yìí rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ákíláọ́sì ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá. Kí Hẹ́rọ́dù tó kú, ó yan Ákíláọ́sì pé òun ló máa jọba lórí Jùdíà àtàwọn àgbègbè míì lẹ́yìn òun. Àmọ́ kí Ákíláọ́sì tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ó ní láti kọ́kọ́ rìnrìn àjò lọ sí iyànníyàn ìlú Róòmù láti lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì.