Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ìwé ìléwọ́ náà, To Whom the Work Is Entrusted ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ tí The Golden Age [ìyẹn Jí! lóde òní] wà fún ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn ìjọba náà láti ilé délé. . . . Lẹ́yìn ìwàásù, a tún ní láti fún onílé kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà ìwé ìròyìn The Golden Age kan, yálà wọ́n ṣe ìdáwó fún un tàbí wọn kò ṣe.” Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ń gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa fi ìdáwó The Golden Age tí à ń pè ní Jí! báyìí, àti Ilé Ìṣọ́ lọ àwọn èèyàn. Bẹ̀rẹ̀ ní February 1, 1940, wọ́n ní kí àwọn èèyàn Jèhófà máa pín Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kí wọ́n sì máa ròyìn iye tí wọ́n bá fi sóde.