Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ọ̀rọ̀ náà, “owú” jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ka ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́ sí pàtàkì gan-an. A lè ronú nípa ìbínú àti owú tí ọkọ kan máa ní tí ìyàwó rẹ̀ bá dalẹ̀ rẹ̀. (Òwe 6:34) Bíi ti ọkọ ìyàwó yẹn, ìbínú Jèhófà bọ́gbọ́n mu nígbà tí àwọn èèyàn tó bá dá májẹ̀mú dalẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì lọ ń jọ́sìn òrìṣà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ . . . ló ṣe ń jowú. Torí pé Òun nìkan ni Ẹni Mímọ́ . . . , kò fàyè gba ọlọ́run míì.”—Ẹ́kís. 34:14.