Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Èrò àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì ni pé ohun tó dáa ni gbólóhùn yẹn gbé yọ, wọ́n ní tipẹ́tipẹ́ ni bí àwọn èèyàn ṣe ń kó iyọ̀ kí wọ́n lè fi máa pa nǹkan mọ́ ti ń mú èrè gọbọi wá fáwọn oníṣòwò tó wà ní agbègbè Òkun Òkú. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé, apá tá a tọ́ka sí nínú Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn ibi ẹrẹ̀ náà “kò . . . ní rí ìwòsàn.” Wọ́n á wà láìlẹ́mìí, wọn ò ní ṣeé wò sàn, torí omi ìyè tó ń ṣàn jáde láti ilẹ̀ Jèhófà kò ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn. Torí náà, ó dà bíi pé pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ohun tí kò dáa ni àwọn iyọ̀ tó wà níbi ẹrẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí.—Sm. 107:33, 34; Jer. 17:6.