Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
f Ibi tí wọ́n ti ń sun pàǹtírí lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Orúkọ Gíríìkì tí wọ́n ń pe Àfonífojì Hínómù, ó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù àtijọ́. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ju ẹranko tàbí èèyàn sínú Gẹ̀hẹ́nà kí wọ́n lè jóná láàyè tàbí kí wọ́n lè máa joró. Torí náà, kì í ṣe ibi téèyàn ò lè rí ló ń ṣàpẹẹrẹ, níbi tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ti ń joró nínú iná títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi Gẹ̀hẹ́nà ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé tàbí ìparun yán-án yán-án.