Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kò pẹ́ kò jìnnà, a ń tẹ Fidei Defensor sára owó ilẹ̀ àkóso náà, Henry sì ní kí a máa fi oyè yìí da àwọn àtẹ̀lé òun lọ́lá. Lónìí ó yí orí aláyélúwà tí ó wà lára owó ilẹ̀ Britain ká gẹ́gẹ́ bíi Fid. Def., tàbí ní ṣókí F.D. Ó dùn mọ́ni pé, a tẹ “Agbèjà Ìgbàgbọ́” lẹ́yìn náà sínú Bibeli King James Version ti 1611, ní yíyà á sí mímọ́ fún Ọba James.