Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn Farisí ní pàtàkì ni ó fa oríṣi Ìsìn Àwọn Júù tí ó wà lónìí, nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé síbẹ̀ Ìsìn Àwọn Júù ṣì ń wá ọ̀nà láti yẹ púpọ̀ nínú àwọn ìkálọ́wọ́kò Sábáàtì tí ó fi kún un sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, olùbẹ̀wò kan sí ilé ìwòsàn àwọn Júù ní ọjọ́ Sábáàtì lè rí i pé ẹ̀rọ agbéni-ròkè-rodò máa ń dúró fúnra rẹ̀ ní àjà kọ̀ọ̀kan kí àwọn èrò baà lè yẹra fún ṣíṣe “iṣẹ́” ẹ̀ṣẹ̀, ti títẹ bọ́tìnnì ẹ̀rọ agbéni-ròkè-rodò náà. Àwọn dókítà kan tí wọ́n jẹ́ Júù ń fi tàdáwà tí yóò parẹ́ láàárín ọjọ́ díẹ̀ kọ àwọn ìwé àmọ̀ràn egbòogi wọn. Èé ṣe? Mishnah ka kíkọ̀wé sí “iṣẹ́,” ṣùgbọ́n ó túmọ̀ “kíkọ̀wé” gẹ́gẹ́ bíi kíkọ àmì tí yóò wà pẹ́ títí sílẹ̀.