Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Nígbà tí a fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì ní Róòmù, ó rọ Tímótì láti mú “àwọn àkájọ ìwé, ni pàtàkì àwọn ìwé awọ” wá. (2 Tímótì 4:13) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwọn apá kan Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Pọ́ọ̀lù ń béèrè fún, kí ó bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn nígbà tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Àpólà ọ̀rọ̀ náà, “ní pàtàkì àwọn ìwé awọ,” lè fi hàn pé àwọn àkójọ ìwé tí a fi òrépèté ṣe àti èyí tí a fi awọ ṣe ń bẹ.