Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Jíjẹ́ tí Jòhánù jẹ́ ojúlùmọ̀ àlùfáà àgbà àti agbo ilé rẹ̀ ni a túbọ̀ fi hàn nínú àkọsílẹ̀ náà níwájú. Nígbà tí òmíràn lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà náà fẹ̀sùn kan Pétérù pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, Jòhánù ṣàlàyé pé ẹrú yìí jẹ́ “ìbátan ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dànù.”—Jòhánù 18:26.