Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú aginjù, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” ló nílò mánà láti rí nǹkan jẹ kí wọ́n má bàa kú. (Ẹ́kísódù 12:37, 38; 16:13-18) Lọ́nà kan náà, láti wà láàyè títí láé, gbogbo Kristẹni, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́dọ̀ jẹ mánà náà tó ti ọ̀run wá nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú agbára tí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù tá a fi rúbọ ní fún ìgbàlà ẹ̀dá èèyàn.—Wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 1988, ojú ìwé 30 àti 31.