Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Tẹ́lẹ̀, àlàyé tá a ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé “ìdájọ́” tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn èèyàn yẹn túmọ̀ sí ìdálẹ́bi. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ náà “ìdájọ́” lè túmọ̀ sí ìdálẹ́bi. Àmọ́, ó jọ pé ọ̀rọ̀ náà “ìdájọ́” tí Jésù lò níbí ní ìtúmọ̀ tó jùyẹn lọ. Ohun tó túmọ̀ sí ni bí Jésù ṣe máa gbé àwọn èèyàn yẹn yẹ̀ wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì kan sọ pé ó túmọ̀ sí kí wọ́n “ṣàyẹ̀wò ìwà ẹnì kan fínnífínní.”