Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ òye tuntun tá a ní nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó gbòòrò jù lọ tí Dáníẹ́lì 12:2, 3 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. A máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí máa wáyé, àwọn tó máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn tá a máa dá lẹ́kọ̀ọ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe máa múra àwọn tó wà láyé sílẹ̀ kí wọ́n lè yege ìdánwò ìkẹyìn lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí.