Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó bá kú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ló máa kọ́kọ́ jíǹde. Lẹ́yìn náà, àwọn tó kú ṣáájú wọn tí wọ́n sì gbé ayé lásìkò kan náà á máa jíǹde tẹ̀ léra wọn títí tó máa fi kan àwọn tó gbé ayé nígbà ayé Ébẹ́lì. Tó bá jẹ́ pé bí Jèhófà ṣe máa ṣe é nìyẹn, á jẹ́ pé àwọn tó gbé ayé lásìkò kan náà máa láǹfààní láti rí àwọn tí wọ́n mọ̀, wọ́n á sì lè kí wọn káàbọ̀. Èyí ó wù ó jẹ́, nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run, ó sọ pé kálukú máa jíǹde ní “àyè rẹ̀.” Torí náà, ó ṣeé ṣe káwọn tó máa jíǹde sí ayé náà jíǹde tẹ̀ léra wọn.—1 Kọ́r. 14:33; 15:23.