Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Párádísè Tẹ̀mí” ni ibi tí ọkàn àwa èèyàn Jèhófà ti balẹ̀, tá a sì ń jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Nínú Párádísè tẹ̀mí yìí, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àtàwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì, tí kò sì sí ẹ̀kọ́ èké kankan nínú wọn. Yàtọ̀ síyẹn, à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń fún wa láyọ̀. Àjọṣe tó dáa tún wà láàárín àwa àti Jèhófà, àlàáfíà sì wà láàárín àwa àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa, ìyẹn sì ń mú ká láyọ̀. Ìgbà tá a wọnú Párádísè tẹ̀mí ni ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé e.