Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Òfin tó wà nínú Diutarónómì 23:3-6 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò fàyè gba àwọn ọmọ Ámónì àtàwọn ọmọ Móábù pé kí wọ́n wá sínú ìjọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, ó jọ pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé lábẹ́ òfin, wọn ò ní lè di ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo nǹkan tí ọmọ Ísírẹ́lì kan lè ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jọ ṣe àwọn nǹkan kan tàbí kí wọ́n gbé pa pọ̀. Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 95.