Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Orúkọ tí orílẹ̀-èdè Myanmar ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ ni Burma, torí pé ẹ̀yà Bamar (ìyẹn Burmese) làwọn tó pọ̀ jù níbẹ̀. Lọ́dún 1989, wọ́n yí orúkọ yẹn pa dà sí Union of Myanmar, láti fi hàn pé àwọn ẹ̀yà míì wà lórílẹ̀-èdè náà. Nínú ìwé yìí, Burma la ó pe orúkọ orílẹ̀-èdè yìí níbi tá a bá ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó wáyé ṣáájú ọdún 1989. Àmọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1989, a ó pè é ní Myanmar.