Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọjọ́ kejì lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà gbógun wọ Ukraine, Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Tó Ń Wá Ibi Ìsádi ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé (UNHCR) sọ pé àwọn tógun yìí máa lé kúrò nílùú kì í ṣe kékeré. Òótọ́ sì ló sọ torí pé láàárín ọjọ́ méjìlá (12) tógun yìí bẹ̀rẹ̀, ohun tó ju mílíọ̀nù méjì ló ti sá kúrò ní Ukraine lọ sórílẹ̀-èdè míì, àwọn mílíọ̀nù kan sì ti sá kúrò níbi tí wọ́n ń gbé lọ sí agbègbè míì lórílẹ̀-èdè yẹn.