Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìwé Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” ń ṣàpèjúwe “kòtò tí kò ní ìsàlẹ̀.” Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ pè é ní “ọ̀gbun jíjìn.” Ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí nínú Bíbélì ni ipò àìlè ṣe ohunkóhun, á wá dà bí ẹni tí kò lè ṣe nǹkan kan.