Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert L. Thomas náà kọ̀wé lórí ọ̀rọ̀ nọ́ńbà tí ìwé Ìṣípayá 7:4 mẹ́nu bà yìí, ó ní: “Iye kan pàtó ni nọ́ńbà yìí, tá a bá fi wé àwọn tí ò níye tí orí keje ẹsẹ kẹsàn-án sọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá sọ pé ṣe ni nọ́ńbà yìí ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan míì, a jẹ́ pé kò sí nọ́ńbà kankan nínú ìwé Ìṣípayá tó jẹ́ iye kan pàtó nìyẹn.”—Ìwé Revelation 1-7: An Exegetical Commentary, ojú ìwé 474.