Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Erwin Schrödinger, ọmọ ilẹ̀ Austria tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ, tó sì tún gba àmì ẹ̀yẹ Nobel sọ pé sáyẹ́ǹsì “ò sọ nǹkan kan rárá nípa gbogbo ohun . . . tó ń jẹ wá lọ́kàn, tó sì ṣe pàtàkì sí wa gan-an.” Albert Einstein náà sọ pé: “Ojú wa ti rí màbo láyé yìí, ìyẹn sì ti jẹ́ ká mọ̀ pé èrò orí nìkan ò tó láti bá wa yanjú ìṣòro tá à ń ní nígbèésí ayé.”