Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn kan ò fara mọ́ lílo ọ̀rọ̀ náà “Ọmọ Ọlọ́run,” wọ́n gbà pé ṣe nìyẹn túmọ̀ sí pé Ọlọ́run bá obìnrin kan lò pọ̀ ló fi bí ọmọ náà. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ ò fi kọ́ wa bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, ṣe ni Bíbélì pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” àti “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” torí pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni kàn ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ ara rẹ̀ dá. (Kólósè 1:13-15) Bíbélì tún pe Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ní “ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Ìdí ni pé Ọlọ́run ló dá Ádámù.