Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà tí Ìwé Mímọ́ máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jónátánì, ìyẹn nígbà tí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ọ̀gágun ni nígbà yẹn, torí náà ó kéré tán, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ ogún (20) ọdún nígbà yẹn. (Númérì 1:3; 1 Sámúẹ́lì 13:2) Ogójì (40) ọdún ni Sọ́ọ̀lù fi jọba. Torí náà, nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú, Jónátánì ti tó nǹkan bí ọgọ́ta (60) ọdún. Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Dáfídì nígbà tí Sọ́ọ̀lù kú. (1 Sámúẹ́lì 31:2; 2 Sámúẹ́lì 5:4) Ó ṣe kedere nígbà náà pé nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ.