Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó dájú pé Màríà ti fi ibojì náà sílẹ̀ kí àwọn obìnrin tí wọ́n jọ rìn náà tó pàdé áńgẹ́lì tó sọ fún wọn pé Jésù ti jíǹde. Ká sọ pé ó rí i ni, ó dájú pé kò bá ti sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé òun rí áńgẹ́lì kan tó ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ fún òun.—Mátíù 28:2-4; Máàkù 16:1-8.