Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristẹni lo orúkọ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú “Májẹ̀mú Láéláé” tó ní orúkọ náà nínú. Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Nígbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun, ẹ̀rí wà pé lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn Yahweh, fara hàn nínú díẹ̀ tàbí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Tuntun tá a fà yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé.” (Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 392) Fún àlàyé síwájú sí i, wo “Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì” nínú àfikún A5 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.