Friday, October 10
Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.—Òwe 9:10.
Kí ló yẹ ká ṣe tí àwòrán ìṣekúṣe bá ṣàdédé jáde lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa? Ṣe ló yẹ ká gbé ojú wa kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá rántí pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ló ṣeyebíye jù lọ. Kódà, àwọn àwòrán kan wà tí kì í ṣe àwòrán ìṣekúṣe tó lè mú ká máa ro èròkerò. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó lè mú ká ṣàgbèrè nínú ọkàn wa, a ò sì ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:28, 29) Alàgbà kan tó ń jẹ́ David lórílẹ̀-èdè Thailand sọ pé: “Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Tí àwòrán kan kì í bá tiẹ̀ ṣe àwòrán ìṣekúṣe, ṣé inú Jèhófà máa dùn sí mi tí mo bá ń wò ó?’ Ìbéèrè tí mo máa ń bi ara mi yìí kì í jẹ́ kí n wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀.” Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, a ò ní ṣe ohun tí ò fẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀” tàbí ìpìlẹ̀ “ọgbọ́n.” w23.06 23 ¶12-13
Saturday, October 11
Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú.—Àìsá. 26:20.
‘Yàrá inú lọ́hùn-ún’ tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ lè jẹ́ àwọn ìjọ wa. Jèhófà ṣèlérí pé tó bá dìgbà ìpọ́njú ńlá, òun máa dáàbò bò wá tá a bá ń jọ́sìn nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára báyìí kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa lè túbọ̀ lágbára láìka ìwà wọn sí. Ó lè jẹ́ ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là nìyẹn! Tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá dé, nǹkan máa nira fún gbogbo èèyàn. (Sef. 1:14, 15) Nǹkan sì máa nira fáwa èèyàn Jèhófà náà. Àmọ́ tá a bá ń múra sílẹ̀ báyìí, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì tún lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Á tún jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù kó dé bá wa. Táwọn ará wa bá níṣòro, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ká fàánú hàn sí wọn, ká sì fún wọn lóhun tí wọ́n nílò. Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa báyìí, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sí àjálù àti ìpọ́njú mọ́.—Àìsá. 65:17. w23.07 7 ¶16-17
Sunday, October 12
[Jèhófà] máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.—1 Pét. 5:10.
Bíbélì sábà máa ń sọ pé àwọn olóòótọ́ èèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà lẹni tó nígbàgbọ́ jù lára wọn máa ń rò pé òun lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì sọ pé òun “lágbára bí òkè,” àmọ́ nígbà kan, ó tún sọ pé “jìnnìjìnnì bá mi.” (Sm. 30:7) Sámúsìn ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lókun, síbẹ̀ ó mọ̀ pé láìsí agbára tí Ọlọ́run fún òun, òun ‘ò ní lókun mọ́, òun ò sì ní yàtọ̀ sí gbogbo ọkùnrin yòókù.’ (Oníd. 14:5, 6; 16:17) Agbára tí Jèhófà fún àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ló jẹ́ kí wọ́n lókun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òun nílò agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà. (2 Kọ́r. 12:9, 10) Ó ní àìsàn tó ń bá a fínra. (Gál. 4:13, 14) Nígbà míì, kì í rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́. (Róòmù 7:18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, ìdààmú máa ń bá a torí kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sóun. (2 Kọ́r. 1:8, 9) Síbẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ aláìlera, ó di alágbára. Lọ́nà wo? Jèhófà ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára tó nílò. Òun ló sì fún un lókun. w23.10 12 ¶1-2