Tuesday, October 21
Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.—Mát. 24:13.
Wo àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ní sùúrù. Tá a bá ń ní sùúrù, a máa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀. Torí náà, sùúrù máa ń jẹ́ ká ní ìlera tó jí pépé. Tá a bá ń ní sùúrù fáwọn èèyàn, àárín wa á túbọ̀ gún régé, ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn ará ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, àmọ́ tá ò tètè bínú, kò ní jẹ́ kọ́rọ̀ náà dìjà. (Sm. 37:8, àlàyé ìsàlẹ̀; Òwe 14:29) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ṣe là ń fara wé Bàbá wa ọ̀run, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ẹ ò rí i pé ìwà tó dáa gan-an ni sùúrù, ó sì ń ṣeni láǹfààní! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ní sùúrù, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, àá máa ní sùúrù. Bákan náà, bá a ṣe ń ní sùúrù kí ayé tuntun dé, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 33:18) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fi sùúrù wọ ara wa láṣọ. w23.08 22 ¶7; 25 ¶16-17
Wednesday, October 22
Ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.—Jém. 2:17.
Jémíìsì jẹ́ ká mọ̀ pé ọkùnrin kan lè sọ pé òun nígbàgbọ́, àmọ́ kò ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. (Jém. 2:1-5, 9) Jémíìsì tún sọ nípa ẹnì kan tó rí ‘arákùnrin tàbí arábìnrin tí ò láṣọ, tí ò sì ní oúnjẹ,’ àmọ́ tí ò ràn án lọ́wọ́. Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ pé òun nígbàgbọ́ àmọ́ tí ò ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ò wúlò. (Jém. 2:14-16) Jémíìsì wá sọ̀rọ̀ nípa Ráhábù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. (Jém. 2:25, 26) Ráhábù ti gbọ́ nípa Jèhófà, ó sì mọ̀ pé òun ló ń ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. (Jóṣ. 2:9-11) Ó ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tí wọ́n lọ ṣe amí nígbà tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu. Torí ohun tí obìnrin aláìpé tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ṣe, a pè é ní olódodo bíi ti Ábúráhámù. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. w23.12 5 ¶12-13
Thursday, October 23
Kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.—Éfé. 3:17.
Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló yẹ káwa Kristẹni mọ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń jẹ́ kó wù wá láti lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:9, 10) O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn apá kan nínú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó ṣe fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fún ìwọ náà báyìí tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn òun, kó o wá fi wé báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé. Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan yìí nínú Watch Tower Publications Index lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹ máa lágbára, wàá sì “rí ìmọ̀ Ọlọ́run.”—Òwe 2:4, 5. w23.10 18-19 ¶3-5