ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Níní Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́
    Jí!—1997 | February 22
    • Níní Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́

      Àkókò ìtàn kíkà ni David, ọmọ ọdún mẹ́fà, máa ń yàn láàyò lóòjọ́. Ó máa ń gbádùn rẹ̀ bí Mọ́mì bá ń kà á fún un, kì í sì í gbàgbé ohun tí ó bá gbọ́. Àmọ́ David níṣòro kan. Kò lè kàwé fúnra rẹ̀. Ní gidi, iṣẹ́ àyànfúnni yòó wù tí ó bá ti kan ìjáfáfá agbára ìríran máa ń tán an ní sùúrù.

      Sarah wà ní ọdún kẹta nílé ẹ̀kọ́, síbẹ̀, lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ìṣọwọ́kọ̀wé rẹ̀ kò gún régé. Kì í kọ àwọn wóró ọ̀rọ̀ rẹ̀ bó ṣe yẹ, ó sì ń dojú àwọn kan nínú wọn kọ ẹ̀yìn. Èyí tí ó jẹ́ àfikún sí ìdààmú tí àwọn òbí rẹ̀ ní ni pé, kò tilẹ̀ lè kọ orúkọ ara rẹ̀.

      Josh, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba, máa ń ṣe dáadáa nínú gbogbo ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́, àfi ìṣirò. Ohun tí ó bá ti ní ṣe pẹ̀lú iye nọ́ńbà máa ń dà á lọ́pọlọ rú pátápátá ni. Wíwo nọ́ńbà lásán máa ń bí Josh nínú, bí ó bá sì jókòó láti ṣe ìṣirò nínú iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀, ojú rẹ̀ máa ń rẹ̀wẹ̀sì kíákíá ni.

      KÍ NI ìṣòro David, Sarah, àti Josh? Ṣe ọ̀lẹ, olóríkunkun, aláìfẹ́kan-ánṣe lásán ni wọ́n ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wọ̀nyí ní làákàyè yíyẹ tàbí làákàyè tí ó kọjá abọ́ọ́dé. Síbẹ̀, ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ ń pààlà sí ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè ṣe. David ní ìṣòro dyslexia, ọ̀rọ̀ kan tí a ń lò láti tọ́ka sí àwọn ìṣòro ìwé kíkà mélòó kan. A ń pe ìṣòro lílégbákan tí Sarah ní ní dysgraphia. Ìṣòro tí Josh sì ní lórí mímọ àwọn kókó ìpìlẹ̀ ìṣirò ni a mọ̀ sí dyscalculia. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ mẹ́ta péré lára àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ ni. Ó tún ku púpọ̀ sí i, àwọn ògbóǹkangí mélòó kan sì fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ó kéré tán, lápapọ̀, wọ́n ń yọ ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé tí ó wà ní United States lẹ́nu.

      Títúmọ̀ Àwọn Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́

      Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èwe ń rí ẹ̀kọ́ kíkọ́ bí ìpèníjà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀síbẹ̀, èyí kì í fìgbà gbogbo tọ́ka sí ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wulẹ̀ ń fi hàn pé gbogbo ọmọ ló ní àgbègbè okun àti àìlera nípa ẹ̀kọ́ kíkọ́. Agbára ìgbọ́ròó àwọn kan jáfáfá gan-an; wọ́n lè gba ìsọfúnni dáadáa nípa títẹ́tí sílẹ̀. Agbára ìríran àwọn mìíràn túbọ̀ múná gan-an; ẹ̀kọ́ kíkọ́ wọn túbọ̀ dára sí i nípa kíkàwé. Bí ó ti wù kí ó rí, nílé ẹ̀kọ́, a ń kó àwọn ọmọ pọ̀ síyàrá ìkàwé ni, a sì retí pé kí gbogbo wọn kẹ́kọ̀ọ́ láìka ọ̀nà ìkọ́ni tí a lò sí. Nítorí náà, ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ ni pé àwọn kan yóò ní àwọn ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́.

      Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aláṣẹ kan sọ pé, ìyàtọ̀ kan wà láàárín ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ lásán àti ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n ṣàlàyé pé, a lè ṣẹ́pá àwọn ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ nípa sùúrù àti ìsapá. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, wọ́n sọ pé àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dókítà Paul Wender àti Dókítà Esther Wender kọ̀wé pé: “Ó jọ pé ọ̀nà tí ọpọlọ ọmọ tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́ gbà ń wòye àwọn oríṣi iṣẹ́ àyànfúnni àfọpọlọṣe kan, tí ó gbà ń ṣiṣẹ́ lórí wọn, tàbí tí ó gbà ń rántí wọn, lábùkù.”a

      Síbẹ̀, ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kan kò fi dandan túmọ̀ sí pé ọmọ kan ní àbùkù ọpọlọ. Láti ṣàlàyé èyí, àwọn Wender méjèèjì fi àwọn ènìyàn tí ó dití sí ìró ohùn, àwọn tí kò lè mọ̀yàtọ̀ ohùn orin, ṣàkàwé nínú àlàyé wọn. Àwọn Wender méjèèji kọ̀wé pé: “Ọpọlọ àwọn ènìyàn tí ó dití sí ìró ohùn kò bà jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan kan kò ṣe agbára ìgbọ́ròó wọn. Kò sí ẹni tí yóò sọ pé àìmọ̀yàtọ̀ ìró ohùn jẹ́ nítorí yíya ọ̀lẹ, àìkọ́ni dáradára, tàbí àìní ìsúnniṣe dáradára.” Wọ́n sọ pé, bákan náà ló rí fún àwọn tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣòro náà ń dá lórí apá kan pàtó nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́.

      Èyí ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ó ní àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ fi ń ní làákàyè lábọ́ọ́dé tàbí tí ó kọjá abọ́ọ́dé; ní gidi, àwọn kan ní làákàyè púpọ̀. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí ó jọ pé ó ta kora yìí ni ó sábà ń mú kí àwọn dókítà jí gìrì sí pé, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kan. Ìwé náà, Why Is My Child Having Trouble at School?, ṣàlàyé pé: “Ọpọlọ ọmọ kan tí ó ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó fi ọdún méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kéré sí ìwọ̀n tí a retí pé kí ó fi ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti ìpíndọ́gba ìwọ̀n làákàyè ọmọ náà.” Kí a sọ ọ́ lọ́nà míràn, ìṣòro náà kì í wulẹ̀ ṣe ti pé ọmọ náà kò lè bá àwọn ojúgbà rẹ̀ dọ́gba ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà ìṣeǹkan rẹ̀ kò bá agbára ìlèṣeǹkan tirẹ̀ fúnra rẹ̀ dọ́gba.

      Pípèsè Ìrànwọ́ Tí A Nílò

      Ipa tí ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ ń ní lórí ìmọ̀lára sábà máa ń mú kí ìṣòro náà díjú. Nígbà tí àwọn ọmọ tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́ kò bá ṣe dáadáa tó nílé ẹ̀kọ́, àwọn olùkọ́ àti ẹlẹgbẹ́ wọn, bóyá àwọn ẹbí wọn pàápàá lè máa wò wọ́n bí aláìlè-ṣàṣeyọrí. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ń mú ojú ìwòye òdì dàgbà nípa ara wọn, èyí tí ó lè máa wà lọ bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àníyàn tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nìyí, nítorí ní gbogbogbòò, àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kì í kásẹ̀ nílẹ̀.b Dókítà Larry B. Silver kọ̀wé pé: “Àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìṣòro àìlèṣeǹkan tí ń wà jálẹ̀ ìgbésí ayé. Ìṣòro àìlèṣeǹkan kan náà tí ń kọ lu ìwé kíkà, ìwé kíkọ, àti ìṣirò yóò tún kọ lu eré ìdárayá àti àwọn ìgbòkègbodò míràn, ìgbésí ayé ìdílé, àti bíbá àwọn ọ̀rẹ́ ṣe pọ̀.”

      Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé, kí àwọn ọmọdé tí ó ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ rí ìtìlẹ́yìn òbí gbà. Ìwé náà, Parenting a Child With a Learning Disability, sọ pé: “Àwọn ọmọ tí wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àwọn jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún àwọn ní ìpìlẹ̀ fún mímú ìmọ̀lára ìtóótun àti ìdára-ẹni-lójú dàgbà.”

      Ṣùgbọ́n láti jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ìmọ̀lára tiwọn fúnra wọn ná. Àwọn òbí kan ń nímọ̀lára ẹ̀bi, bíi pé àwọn ni wọ́n ni ẹ̀bi ipò tí ọmọ wọn wà. Àwọn mìíràn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, àwọn ìpèníjà tí ń bẹ níwájú wọn sì ń mú wọn pòrúurùu. Ìhùwàpadà méjèèjì wọ̀nyí kò wúlò. Wọn kì í jẹ́ kí àwọn òbí ṣe nǹkan nípa ìṣòro náà, wọ́n sì ń dí ọmọ náà lọ́wọ́ rírí ìrànwọ́ tí ó nílò gbà.

      Nítorí náà, bí ògbóǹtagí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan bá sọ pé ọmọ rẹ ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kan, má sọ̀rètí nù. Rántí pé àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ wulẹ̀ nílò àfikún ìtìlẹ́yìn nínú ìjáfáfá agbára ìkẹ́kọ̀ọ́ pàtó kan ni. Lo àkókò láti mọ̀ nípa ìṣètò èyíkéyìí tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àdúgbò rẹ fún àwọn ọmọ tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ ti ní àwọn ohun èlò tí ó dára ju ti àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn lọ láti fi kojú ipò náà.

      Àwọn ògbóǹkangí ń tẹnu mọ́ ọn pé, o gbọ́dọ̀ máa yin ọmọ rẹ fún àṣeyọrí yòó wù kí ó ṣe, bó ti wù kí ó mọ. Máa fún un níṣìírí gan-an. Nígbà kan náà, má ṣe pa ìbáwí tì sápá kan. Àwọn ọmọdé nílò ìṣètò, èyí sì túbọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn ọmọ tí kò lè kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ohun tí o ń retí lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó sì rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tí o gbé kalẹ̀.

      Ní paríparí rẹ̀, kọ́ láti wo ipò rẹ bí ó ṣe rí gan-an. Ìwé náà, Parenting a Child With a Learning Disability, ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yí pé: “Finú rò ó pé o lọ sí ilé àrójẹ tí o yàn láàyò, o sì béèrè fún veal scallopini [ègé pẹlẹbẹ ẹran ara màlúù]. Nígbà tí agbáwo gbáwo kalẹ̀ níwájú rẹ, o rí i pé ègé egungun ìhà ọ̀dọ́ àgùntàn ni wọ́n gbé wá. Oúnjẹ aládùn ni méjèèjì, ṣùgbọ́n ẹran ara lo ti ń retí. Ọ̀pọ̀ òbí ní láti yí ìrònú wọn pa dà. O lè ṣàìretí ọ̀dọ́ àgùntàn náà, ṣùgbọ́n o rí i pé ó dùn gan-an. Bẹ́ẹ̀ ló rí nígbà tí o bá ń tọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n ní àìní àrà ọ̀tọ̀.”

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Àwọn ìwádìí kan dábàá pé, àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ lè jẹ́ àjogúnbá tàbí kí àwọn kókó abájọ àyíká, bíi májèlé òjé, lílo oògùn líle tàbí ohun ọlọ́tí líle nígbà tí a lóyún, kó ipa kan. Síbẹ̀, a kò mọ ohun tàbí àwọn ohun tí ń fà á gan-an.

      b Nínú àwọn ọ̀ràn díẹ̀, àwọn ọmọdé ń ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ fúngbà díẹ̀ nítorí pé ìdàgbàsókè wọn ní àwọn àgbègbè kan falẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn àmì àrùn náà.

  • “Jókòó Jẹ́ẹ́, Kí O Sì Fetí Sílẹ̀!”
    Jí!—1997 | February 22
    • “Jókòó Jẹ́ẹ́, Kí O Sì Fetí Sílẹ̀!”

      Níní Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Àìlèpọkànpọ̀

      “Látìgbà yí wá, Jim ti sọ pé Cal bà jẹ́ ni, àti pé bí a —ìyẹn èmi—bá gbé ìgbésẹ̀ ìbáwí yíyẹ, yóò ṣàtúnṣe ìwà rẹ̀. Nísinsìnyí, dókítà wá sọ fún wa pé ẹ̀bi mi kọ́, ẹ̀bi wa kọ́, ẹ̀bi àwọn olùkọ́ Cal kọ́: nǹkan kan ló kù díẹ̀ káà tó nínú ọmọkùnrin wa kékeré.”

      CAL ní Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Àìlèpọkànpọ̀ (ADHD), ipò kan tí ó ní àbùdá àìbaralẹ̀, ìwà abẹbẹlúbẹ, àti araàbalẹ̀. A fojú díwọ̀n pé àrùn yí ń yọ ìpín 3 sí 5 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ tí ó ti tó ilé ẹ̀kọ́ lọ lẹ́nu. Ògbóǹtagí onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ kíkọ́ náà, Priscilla L. Vail, sọ pé: “Ìrònú wọn dà bí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n tí bọ́tìnnì tí a fi ń pààrọ̀ ìkànnì rẹ̀ ní àléébù. Èrò kan ń ṣamọ̀nà sí òmíràn láìsí ìṣètò tàbí ìkálọ́wọ́kò kankan.”

      Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò mẹ́ta pàtàkì nínú àwọn àmì àrùn ADHD ní ṣókí.

      Àìbaralẹ̀: Ọmọdé alárùn ADHD kì í lè mọ́kàn kúrò lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò ṣe pàtàkì, kí ó sì pọkàn pọ̀ sórí kókó kan. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tí ó ń rí, ìró, àti òórùn, tí kò bá ohun tí ń lọ lọ́wọ́ tan, máa ń tètè pín ọkàn rẹ̀ níyà.a Ó ń fetí sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn nínú gbogbo ohun tí ń lọ láyìíká rẹ̀. Kò lè pinnu èyí tí ó yẹ kí ó gbà á lọ́kàn jù lọ.

      Ìwà abẹbẹlúbẹ: Ọmọdé alárùn ADHD máa ń hùwà kí ó tó ronú, láìṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó lè yọrí sí. Ìwéwèé àti ìpinnu rẹ̀ kì í mọ́yán lórí, àwọn ìwà rẹ̀ sì máa ń léwu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Dókítà Paul Wender kọ̀wé pé: “Ó máa ń sáré já títì, ó máa ń sáré lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, ó máa ń sáré gungi. Bí ìyọrísí rẹ̀, nǹkan ń gé e lára, nǹkan ń ha á lára, ara rẹ̀ ń bó, ó sì máa ń lọ rí dókítà ju bó ti yẹ lọ.”

      Araàbalẹ̀: Ara kì í rọ àwọn ọmọ tí ara wọn kò balẹ̀ nígbà kankan. Wọn kì í lè jókòó jẹ́ẹ́. Dókítà Gordon Serfontein kọ̀wé nínú ìwé rẹ̀, The Hidden Handicap, pé: “Nígbà tí wọ́n bá tilẹ̀ dàgbà díẹ̀ sí i pàápàá, bí o bá kíyè sí wọn dáradára, ìwọ yóò rí i pé wọ́n ń yiiri ẹsẹ̀, apá, ọwọ́, ètè tàbí ahọ́n léraléra.”

      Síbẹ̀, àwọn ọmọ kan tí ara wọn kì í lélẹ̀, tí wọ́n sì ń hùwà abẹbẹlúbẹ kì í ṣe aláraàbalẹ̀. A wulẹ̀ ń tọ́ka sí àrùn tiwọn bí Àrùn Àìlèpọkànpọ̀, tàbí àrùn ADD. Dókítà Ronald Goldberg ṣàlàyé pé, àrùn ADD “lè ṣẹlẹ̀ láìsí araàbalẹ̀ rárá. Tàbí ó lè ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú araàbalẹ̀ ní ìwọ̀n èyíkéyìí—láti orí èyí tí a kò lè fura sí, dé orí èyí tó ń múni bínú, dé orí èyí tó ń sọni di aláìlè-ṣeǹkan.”

      Kí Ní Ń Fa Àrùn ADHD?

      Jálẹ̀jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti gbé ẹ̀bi àwọn ìṣòro àìlèpọkànpọ̀ karí gbogbo nǹkan, bẹ̀rẹ̀ láti orí òbí tí kò ṣe iṣẹ́ bí iṣẹ́ dé orí lílo iná mànàmáná. Nísinsìnyí, a ronú pé àrùn ADHD ní ṣe pẹ̀lú àwọn ìdíwọ́ nínú àwọn ìṣiṣẹ́ kan nínú ọpọlọ. Ní 1990, Ibùdó Orílẹ̀-Èdè fún Ẹ̀kọ́ Ìlera Ọpọlọ ṣàyẹ̀wò àwọn àgbàlagbà 25 tí wọ́n ní àwọn àmì àrùn ADHD, ó sì rí i pé ìfọ́síwẹ́wẹ́ ṣúgà ń falẹ̀ gan-an ní apá tí ń darí ìyírapadà àti ìpọkànpọ̀ nínú ọpọlọ. Nínú nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ADHD, ó jọ pé àpapọ̀ apilẹ̀ àbùdá ẹni náà ń kó ipa kan. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Hyperactive Child Book, ṣe sọ, àwọn kókó abájọ mìíràn tí ó lè ní ṣe pẹ̀lú àrùn ADHD ni bí ìyá náà bá lo ọtí líle tàbí oògùn líle ní àkókò tó lóyún, májèlé òjé, àti, nínú àwọn ọ̀ràn kan, oríṣi oúnjẹ.

      Aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà àti Àgbàlagbà Alárùn ADHD

      Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn dókítà ti rí i pé àrùn ADHD kì í ṣe àrùn ìgbà ọmọdé lásán. Dókítà Larry Silver sọ pé: “Bí ó ti sábà ń rí, àwọn òbí yóò mú ọmọ kan wá fún ìtọ́jú, wọn yóò sì sọ pé, ‘Bó ṣe ń ṣe èmi náà lọ́mọdé nìyẹn.’ Wọn yóò sì gbà pé, àwọn ṣì ń ní ìṣòro láti dúró lórí ìlà, láti jókòó jẹ́ẹ́ jálẹ̀ àwọn ìpàdé, láti parí àwọn ìdáwọ́lé.” A wá gbà gbọ́ nísinsìnyí pé nǹkan bí ìdajì àwọn ọmọdé tí ó ní àrùn ADHD máa ń ní àwọn àmì àrùn díẹ̀, ó kéré tán, títí wọ ìgbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà àti ìgbà àgbàlagbà.

      Nígbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà, àwọn tí ó ní àrùn ADHD lè ṣí láti orí ìhùwà eléwu sí orí ìwà tí kò ṣètẹ́wọ́gbà. Ìyá aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà alárùn ADHD kan sọ pé: “Mo máa ń dààmú tẹ́lẹ̀ pé kò ní lè wọ kọ́lẹ́ẹ̀jì. Ní báyìí, mo wulẹ̀ ń gbàdúrà pé kó má wẹ̀wọ̀n ni.” Ìwádìí kan tí ó ṣe àfiwéra 103 èwe aláraàbalẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ 100 ọmọ tí kò ní àrùn náà fi ẹ̀rí hàn pé irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ìwé ìròyìn Newsweek ròyìn pé: “Nígbà tí ọjọ́ orí wọn bá lé díẹ̀ ní 20 ọdún, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ inú àwùjọ aláraàbalẹ̀ ní àkọsílẹ̀ ìfòfinmúni ní ìlọ́po méjì, kí wọ́n gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n tàbí ikú ní ìlọ́po márùn-ún, kí wọ́n sì ti ṣẹ̀wọ̀n ni ìlọ́po mẹ́sàn-án ju àwọn ti àwùjọ kejì lọ.”

      Fún àgbàlagbà kan, àrùn ADHD máa ń gbé ọ̀wọ́ àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan kalẹ̀. Dókítà Edna Copeland sọ pé: “Ọmọkùnrin tí ó ní àrùn araàbalẹ̀ lè di àgbàlagbà tí ń pa iṣẹ́ dà lemọ́lemọ́, tí a ń lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ń fàkókò ṣòfò ní gbogbo ọjọ́, tí kì í sì í nísinmi.” Bí a kò bá mọ ohun tí ń fà á, àwọn àmì àrùn wọ̀nyí lè da ìgbéyàwó kan rú. Ìyàwó ọkùnrin alárùn ADHD kan sọ pé: “Nínú ìjíròrò lásán, kì yóò tilẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun tí mo wí. Ńṣe ló sábà máa ń dà bíi pé ibòmíràn ló wà.”

      Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ní àwọn àmì wọ̀nyí—ó kéré tán, dé àyè kan. Ọ̀mọ̀wé George Dorry sọ pé: “O gbọ́dọ̀ béèrè bóyá àwọn àmì àrùn náà ti fìgbà gbogbo wà bẹ́ẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ìgbà tí ọkùnrin kan ti pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ tàbí láti ìgbà tí ìyàwó rẹ̀ ti bímọ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbàgbé nǹkan, ìyẹn kì í ṣe àrùn.

      Síwájú sí i, bí ẹnì kan bá ní àrùn ADHD ní tòótọ́, àwọn àmì àrùn náà máa ń rinlẹ̀—ìyẹn ni pé, wọ́n máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ kan gbogbo apá ìgbésí ayé ẹni náà. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn ṣe rí fún Gary, ẹni ọdún 38, onílàákàyè ọkùnrin kan, tí ó lágbára, tí kò jọ pé ó lè parí ìdáwọ́lé kankan láìsí ìpínyà ọkàn. Ó ti ṣe iṣẹ́ tí ó lé ní 120. Ó sọ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fara mọ́ òtítọ́ náà pé n kò lè ṣàṣeyọrí rárá ni.” Ṣùgbọ́n a ti ran Gary, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn—ọmọdé, aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà, àti àgbàlagbà—lọ́wọ́ láti kojú àrùn ADHD. Lọ́nà wo?

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Ó ń yọ àwọn ọkùnrin lẹ́nu ju àwọn obìnrin lọ.

  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
    Jí!—1997 | February 22
    • Kíkojú Ìpèníjà Náà

      LÁTỌDÚNMỌDÚN, àwọn ènìyàn ti dábàá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtọ́jú fún àrùn ADHD. Àwọn kan lára ìwọ̀nyí dá lórí oúnjẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìwádìí díẹ̀ fi hàn pé àwọn èròjà tí a ń fi sínú oúnjẹ kì í sábà fa araàbalẹ̀, àti pé, àwọn ojútùú tí a gbé karí oríṣi oúnjẹ kì í sábà gbéṣẹ́. Àwọn ọ̀nà míràn láti ṣètọ́jú àrùn ADHD ni lílo egbòogi, ètò ìyíwàpadà, àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ òye ìdáǹkanmọ̀.a

      Lílo egbòogi. Níwọ̀n bí àrùn ADHD ti kan ìṣiṣẹ́gbòdì kan nínú ọpọlọ ni kedere, lílo egbòogi láti ṣe àdápadà ọ̀nà ìṣiṣẹ́ yíyẹ ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.b Bí ó ti wù kí ó rí, lílo egbòogi kì í gba ipò ẹ̀kọ́ kíkọ́. Ó wulẹ̀ ń ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ ni, nípa fífún un ní ìpìlẹ̀ kan tí yóò kọ́ ẹ̀kọ́ agbára ìṣeǹkan tuntun lé lórí.

      Bákan náà, lílo egbòogi ti ran ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà alárùn ADHD lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gba ìṣọ́ra—fún tèwetàgbà—nítorí àwọn egbòogi arùmọ̀lára-sókè kan tí a ń lò fún ìtọ́jú àrùn ADHD lè di bárakú.

      Ètò ìyíwàpadà. Pé ọmọ kan ní àrùn ADHD kò yọ àwọn òbí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrù iṣẹ́ wọn láti bá a wí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà lè ní àìní àrà ọ̀tọ̀ ní ìhà yí, Bíbélì gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Nínú ìwé rẹ̀, Your Hyperactive Child, Barbara Ingersoll sọ pé: “Òbí tí ó bá wulẹ̀ juwọ́ sílẹ̀, tí ó sì jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ aláraàbalẹ̀ ‘ya ewèlè’ kò ṣe ọmọ náà lóore kankan. Bíi ti àwọn ọmọ mìíràn, ọmọ aláraàbalẹ̀ kan nílò ìbáwí ṣíṣe déédéé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún ọmọ náà bí ẹnì kan. Èyí túmọ̀ sí àwọn ààlà ṣíṣe kedere, àti ẹ̀san òun ìjìyà yíyẹ.”

      Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí pèsè ìlànà kedere, kí wọ́n sì ṣe déédéé nínú bíbójútó ìhùwà ọmọ náà. Síwájú sí i, ìlànà àṣetúnṣe déédéé gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́. Àwọn òbí lè fẹ́ fún ọmọ náà ní òmìnira díẹ̀ nínú ṣíṣètò àwọn ohun tí ó bá fẹ́ ṣe, títí kan àkókò fún iṣẹ́ àṣetiléwá, ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, máa bójú tó o déédéé. Rí i dájú pé ó rọ̀ mọ́ ìlànà àṣetúnṣe déédéé ojoojúmọ́ náà. Ìwé ìròyìn Phi Delta Kappan sọ pé: “Àwọn oníṣègùn, onímọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà, aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn olùkọ́ ní iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe kan fún ọmọ náà àti àwọn òbí rẹ̀, láti ṣàlàyé pé jíjẹ́ alárùn ADD tàbí alárùn ADHD kò fún ọmọ náà lómìnira láti ṣe ohun tó bá ti fẹ́ ṣáá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó wà gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ó lè ṣamọ̀nà sí ṣíṣèrànwọ́ yíyẹ fún ọmọ tí ọ̀ràn kàn náà.”

      Ìdálẹ́kọ̀ọ́ òye ìdáǹkanmọ̀. Èyí kan ríran ọmọ náà lọ́wọ́ láti yí èrò rẹ̀ nípa ara rẹ̀ àti àrùn tí ó ní pa dà. Dókítà Ronald Goldberg sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn àìlèpọkànpọ̀ máa ń rò pé àwọ́n ‘burẹ́wà, àwọn ya òmùgọ̀, àwọn sì burú,’ kódà bí wọ́n bá rẹwà, tí wọ́n ní làákàyè, tí wọ́n sì níwà rere pàápàá.” Nítorí náà, ó yẹ kí ọmọ tí ó bá ní àrùn ADD tàbí àrùn ADHD ní èrò rere nípa ìníyelórí ara rẹ̀, ó sì yẹ kí ó mọ̀ pé àwọn ìṣòro àìlèpọkànpọ̀ òun ṣeé yanjú. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbà ọ̀dọ́langba. Nígbà tí alárùn ADHD kan bá fi di aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ojúgbà, olùkọ́, ọmọ ìyá, àti bóyá, àwọn òbí pàápàá, ti ṣàríwísí rẹ̀ púpọ̀. Ó wá yẹ fún un nísinsìnyí láti gbé àwọn góńgó tí ọwọ́ lè tẹ̀ kalẹ̀, kí ó sì pinnu ìníyelórí ara rẹ̀ bí ó ṣe yẹ, kì í ṣe lọ́nà líle koko.

      Àwọn àgbàlagbà alárùn ADHD pẹ̀lú lè lo àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tí a mẹ́nu bà lókè wọ̀nyí. Dókítà Goldberg kọ̀wé pé: “Ìyípadà tí a gbé karí ọjọ́ orí pọn dandan, àmọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ìgbàtọ́jú—lílo egbòogi níbi tó bá yẹ, ètò ìyíwàpadà, àti [ìdálẹ́kọ̀ọ́] òye ìdáǹkanmọ̀—jẹ́ ọ̀nà tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé.”

      Ṣíṣètìlẹ́yìn

      John, bàbá ọ̀dọ́langba alárùn ADHD kan, sọ fún àwọn òbí tí wọ́n wà nínú ipò jíjọra pé: “Mọ gbogbo ohun tí o bá lè mọ̀ nípa ìṣòro yìí. Ṣe àwọn ìpinnu ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o mọ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, fẹ́ràn ọmọ rẹ, mú kí iyì ara ẹni rẹ̀ dá a lójú. Fífojú àìjámọ́ǹkan wo ara rẹ̀ yóò mú un rẹ̀wẹ̀sì.”

      Kí ọmọdé alárùn ADHD lè níṣìírí púpọ̀ tó, àwọn òbí méjèèjì ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Dókítà Gordon Serfontein kọ̀wé pé ó yẹ kí ọmọdé alárùn ADHD “mọ̀ pé, a fẹ́ràn òun nínú ilé àti pé ìfẹ́ náà ń wá láti inú ìfẹ́ tí ó wà láàárín àwọn òbí náà.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ó bani nínú jẹ́ pé a kì í sábà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Dókítà Serfontein ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “A ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nínú ìdílé tí [ọmọdé alárùn ADHD kan] bá wà, àìṣọ̀kan àti ìwólulẹ̀ máa ń fi nǹkan bí ìdámẹ́ta pọ̀ ju ti inú ìdílé tí kò ti sí lọ.” Láti dènà irú àìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀, bàbá gbọ́dọ̀ kó ipa tó mọ́yán lórí nínú títọ́ ọmọdé alárùn ADHD. A kò gbọ́dọ̀ gbé ẹrù iṣẹ́ náà lé ìyá lórí pátápátá.—Éfésù 6:4; Pétérù Kíní 3:7.

      Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kì í ṣe apá kan ìdílé náà, wọ́n lè ṣèrànwọ́ gidigidi. Lọ́nà wo? John tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Jẹ́ onínúure. Máa wò kọjá ohun tó hàn ní gbangba. Mọ ọmọ náà. Bá àwọn òbí náà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú. Báwo ni wọ́n ti ń ṣe sí? Kí ni wọ́n ń dojú kọ lójoojúmọ́?”—Òwe 17:17.

      Àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni lè ṣe púpọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún ọmọdé alárùn ADHD náà àti àwọn òbí rẹ̀ lápapọ̀. Lọ́nà wo? Nípa fífòye báni lò nínú ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. (Fílípì 4:5) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọmọdé alárùn ADHD kan lè máa da nǹkan rú. Kàkà kí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà àìgbatẹnirò pé, “O kò ṣe bójú tó ọmọ rẹ?” tàbí “O kò ṣe kúkú bá a wí?” òun yóò mọ̀ pé àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ tí títọ́ ọmọdé alárùn ADHD kan ní nínú lè ti mú ọkàn àwọn òbí náà pòrúurùu. Dájúdájú, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti mú kí ìwà ìbaǹkanjẹ́ ọmọ wọn mọ níwọ̀n. Síbẹ̀síbẹ̀, kàkà kí àwọn tí ó báni tan nínú ìgbàgbọ́ máa fìbínú jágbe mọ́ni, wọ́n gbọ́dọ̀ tiraka láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn, kí wọ́n sì “máa súre.” (Pétérù Kíní 3:8, 9) Ní tòótọ́, Ọlọ́run sábà máa “ń tu àwọn wọnnì tí a mú balẹ̀ nínú” nípasẹ̀ àwọn oníyọ̀ọ́nú onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn.—Kọ́ríńtì Kejì 7:5-7.

      Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé lọ́dọ̀ ọkùnrin kìíní, Ádámù, ni a ti jogún gbogbo àìpé ẹ̀dá ènìyàn, títí kan ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ àti àrùn ADHD. (Róòmù 5:12) Wọ́n tún mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà, yóò mú ìlérí rẹ̀, láti mú ayé tuntun òdodo kan wá, nínú èyí tí àwọn àìsàn tí ń fa ìrora ọkàn kì yóò sí mọ́, ṣẹ. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:1-4) Ìdánilójú yìí jẹ́ ìdákọ̀ró ìṣírí fún àwọn tí wọ́n ní àwọn àrùn bí àrùn ADHD. John sọ pé: “Ọjọ́ orí, ìdálẹ́kọ̀ọ́, àti ìrírí ń ran ọmọkùnrin wa lọ́wọ́ láti lóye àrùn tí ó ní, àti láti bójú tó o. Ṣùgbọ́n kò ní rí ìwòsàn pátápátá nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Ìtùnú wa ojoojúmọ́ ni pé, nínú ayé tuntun, Jèhófà yóò ṣàtúnṣe àrùn tí ọmọkùnrin wa ní, yóò sì mú kí ó lè gbádùn ìgbésí ayé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.”

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Jí! kò fọwọ́ sí ìtọ́jú pàtó kankan. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti rí i pé irú ìtọ́jú yòó wù kí wọ́n gbà kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

      b Àwọn kan ń nírìírí ìyọrísí búburú tí a kò fẹ́ nítorí lílo egbòogi, ó ní àníyàn àti àwọn ìṣòro ìmọ̀lára mìíràn nínú. Síwájú sí i, lílo egbòogi arùmọ̀lára-sókè lè mú kí ìfàro pọ̀ sí i fún àwọn olùgbàtọ́jú tí ó ní àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì ìfàro iṣan lójijì bí àwọn alárùn Tourette. Nítorí náà, lílo egbòogi ń béèrè àbójútó dókítà kan.

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

      Ọ̀rọ̀ Ìṣọ́ra fún Àwọn Òbí

      Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọmọdé ni kì í pọkàn pọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n ń ṣe nǹkan láìròówò, tí ara wọn kì í sì í balẹ̀. Níní àwọn àbùdá wọ̀nyí kì í fìgbà gbogbo tọ́ka sí àrùn ADHD. Nínú ìwé rẹ̀, Before It’s Too Late, Ọ̀mọ̀wé Stanton E. Samenow sọ pé: “Mo ti rí àìníye ìgbà tí a kì í bá ọmọ kan tí kò fẹ́ ṣe nǹkan kan wí nítorí pé a rò pé ó ní àìpé ara tàbí pé ó wà ní ipò kan tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ̀.”

      Ọ̀mọ̀wé Richard Bromfield pẹ̀lú rí i pé ó yẹ láti ṣọ́ra. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, àwọn ènìyàn kan tí ọpọlọ wọn ti dà rú, tí wọ́n sì nílò egbòogi, ni a ti sọ pé àrùn ADHD ni wọ́n ní. Ṣùgbọ́n a ń fi àṣìṣe dárúkọ àrùn náà bíi pé òun ni gbogbo onírúurú ìṣekúṣe, ìwà àgàbàgebè, ìyẹǹkansílẹ̀ àti àwọn ìwà búburú mìíràn tí ń bẹ láàárín àwùjọ, tí wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú àrùn ADHD nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ. Ní tòótọ́, ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àìnílànà nínú ìgbésí ayé òde òní—ìwà ipá àtìgbàdégbà, ìjoògùnyó àti, àwọn kókó abájọ tí kò múni gbọ̀n rìrì tó bẹ́ẹ̀, bí àwọn ilé tí kò ní ìṣètò, tí wọ́n kún fún ìdàrúdàpọ̀—fún araàbalẹ̀ tí ó fara jọ àrùn ADHD lágbára ju bí ìbàjẹ́ èyíkéyìí nínú ọpọlọ ti lè ṣe lọ.”

      Nípa bẹ́ẹ̀, Dókítà Ronald Goldberg kìlọ̀ lòdì sí wíwo àrùn ADHD gẹ́gẹ́ bíi “kókó abájọ kan fún gbogbo àmì àrùn.” Ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé, kí a “máa rí i dájú pé gbogbo ìgbésẹ̀ yíyẹ ni a gbé láti ṣàwárí àrùn kí a lè dé orí ìpinnu títọ̀nà.” Àwọn àmì àrùn tí ó fara jọ ti àrùn ADHD lè jẹ́ ti èyíkéyìí lára ọ̀pọ̀ ìṣòro ti ara ìyára tàbí ti ìmọ̀lára. Nítorí náà, a nílò ìrànlọ́wọ́ dókítà tí ó nírìírí gan-an láti ṣàwárí àrùn lọ́nà pípéye.

      Kódà, bí a bá tilẹ̀ ṣàwárí àrùn, yóò dára kí àwọn òbí ṣàgbéyẹ̀wò tibitire tí lílo egbòogi ní nínú. Egbòogi Ritalin lè mú àwọn àmì àrùn tí a kò fẹ́ kúrò, ṣùgbọ́n ó tún lè ní ìyọrísí tí a kò retí tẹ́lẹ̀, bí àìróorun-sùntó, hílàhílo tí ó pọ̀ sí i, àti ojora. Nípa bẹ́ẹ̀, Dókítà Richard Bromfield kìlọ̀ pé, kí a má ṣe kánjú jù láti lo egbòogi fún ọmọ kan nítorí kí a lè mú àwọn àmì àrùn rẹ̀ kúrò. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ọmọdé, àti àwọn àgbà tí ń pọ̀ sí i, ni a ń lo Ritalin fún láìyẹ. Nínú ìrírí mi, ó jọ pé lílo Ritalin sinmi lórí bí àwọn òbí àti olùkọ́ bá ti lè fàyè gba ìhùwà ọmọ tó. Mo mọ̀ nípa àwọn ọmọ kan tí a ti lò ó fún, kìkì láti jẹ́ kí ara rọ̀ wọ́n, kì í ṣe láti bójú tó àìní wọn.”

      Nítorí náà, àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ yára jù láti sọ pé ọmọ àwọn ní àrùn ADHD tàbí ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí náà, kí wọ́n sì gba ìrànwọ́ amọṣẹ́dunjú kan. Bí ó bá ṣe kedere pé ọmọ kan ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ tàbí àrùn ADHD, àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò láti ní ìmọ̀ dáradára nípa ìṣòro náà, kí wọ́n lè gbégbèésẹ̀ lọ́nà tí yóò ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní jù lọ.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

      Ọmọdé alárùn ADHD nílò ìbáwí onínúure tí ó ṣe déédéé

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

      Ìgbóríyìnfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí ń kópa pàtàkì gan-an

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́