APÁ 6
Ìgbà Ìbí Jésù sí Àkókò Ikú Rẹ̀
Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí ọmọbìnrin arẹwà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Ó sọ fún un pé ó máa bí ọmọ kan tó máa jọba títí láé. Ibùso ẹran ló bí ọmọ náà tó ń jẹ́ Jésù sí. Ibẹ̀ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Lẹ́yìn náà, ìràwọ̀ kan ṣamọ̀nà àwọn èèyàn kan láti Ìlà Oòrùn wá sí ọ̀dọ́ ọmọ náà. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹni tó mú kí wọ́n rí ìràwọ̀ náà àti bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ káwọn tó fẹ́ pa Jésù rí i pa.
Síwájú sí i, nígbà tí Jésù pé ọmọ ọdún méjìlá, a rí i tó ti ń bá àwọn olùkọ́ni jíròrò nínú tẹ́ńpìlì. Ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn náà, Jésù ṣèrìbọmi, lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti ti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Ọlọ́run rán an wá sáyé láti ṣe. Láti ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí, Jésù yan àwọn ọkùnrin méjìlá ó sì sọ wọ́n di àpọ́sítélì rẹ̀.
Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Ó fi àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ àti àkàrà díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, àní ó tiẹ̀ jí àwọn òkú dìde. Níkẹyìn, a máa kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà ọjọ́ ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe pa á. Jésù wàásù fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ nítorí náà APÁ 6 kárí àkókò tó fi díẹ̀ lé ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34].