ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 53 ojú ìwé 268-ojú ìwé 271 ìpínrọ̀ 2
  • Fún Àwùjọ Ní Ìṣírí Àti Okun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fún Àwùjọ Ní Ìṣírí Àti Okun
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Máa Fúnni Níṣìírí Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Jèhófà Máa Fún Ẹ Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ Máa “Gbé Ara Yín Ró”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 53 ojú ìwé 268-ojú ìwé 271 ìpínrọ̀ 2

Ẹ̀KỌ́ 53

Fún Àwùjọ Ní Ìṣírí Àti Okun

Kí ló yẹ kí o ṣe?

O yẹ́ kí o gbin ìrètí tàbí ìgboyà sí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ lọ́kàn. Ta wọ́n jí kí o sì fún wọn lókun.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ojú àwọn èèyàn ń rí màbo nítorí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà nínú ayé yìí. Ìrẹ̀wẹ̀sì sì ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ kan sọ àti ọ̀nà tó gbà sọ ọ́ lè fún àwùjọ lókun gidigidi tàbí kó bu ìrẹ̀wẹ̀sì lù wọ́n.

IRÚ ìṣòro yòówù kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní, ó yẹ kí wọ́n lè rí ìṣírí gbà nínú ìjọ Kristẹni. Nítorí náà, àwọn alàgbà ní pàtàkì gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ràn tí wọ́n bá pèsè jẹ́ èyí tí ń fúnni níṣìírí. Ńṣe ló yẹ kí àwọn alàgbà “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.”—Aísá. 32:2.

Bó bá jẹ́ pé alàgbà ni ọ́, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ máa ń fún àwọn èèyàn ní ìtura àti ìtùnú? Ṣé wọ́n máa ń fún àwọn tó ń sapá láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà lókun? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ máa ń fúnni lókun láti tẹra mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tiẹ̀ ń dágunlá tàbí tí wọ́n ń ṣàtakò? Bí àwọn kan nínú àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ bá ní ìdààmú ọkàn ńkọ́, tàbí tí bùkátà ńlá já lé wọn léjìká, tàbí tí àìsàn tí kò gbóògùn ń pọ́n wọn lójú? O lè ‘fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.’—Jóòbù 16:5.

Lo àǹfààní ọ̀rọ̀ sísọ tí o ní láti mú kí àwọn arákùnrin rẹ gba ìrètí àti okun látọ̀dọ̀ Jèhófà àti látinú àwọn ìpèsè tó ṣe fún wa.—Róòmù 15:13; Éfé. 6:10.

Rán Àwùjọ Létí Ohun Tí Jèhófà Ti Ṣe. Ọ̀nà pàtàkì kan láti gbà fúnni lókun ni sísọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lákòókò ìṣòro ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá.—Róòmù 15:4.

Jèhófà sọ pé kí Mósè “fún” Jóṣúà “ní ìṣírí” àti ‘okun’ ṣáájú kí Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí táwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá ṣì ń gbé nígbà yẹn. Báwo ni Mósè ṣe wá fún un ní ìṣírí? Níṣojú Jóṣúà, Mósè rán gbogbo orílẹ̀-èdè náà létí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò ní Íjíbítì. (Diu. 3:28; 7:18) Mósè tún sọ ìtàn àwọn ìgbà tí Jèhófà mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn Ámórì. Lẹ́yìn náà, Mósè wá rọ Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára.” (Diu. 31:1-8) Nígbà tí o bá fẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ lókun, ǹjẹ́ o máa ń mú kí wọ́n rántí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn sẹ́yìn kí ìyẹn lè fún wọn lókun?

Nígbà mìíràn, ìṣòro àwọn kan lè kà wọ́n láyà débi pé wọ́n á máa rò ó pé àfàìmọ̀ ni ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run á fi lè kan àwọn. Ńṣe ni kó o máa rán àwọn yẹn létí pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣeé gbíyè lé.—Jóṣ. 23:14.

Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìṣòro àwọn arákùnrin wa ni pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. Ní irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ lè mú kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn rí okun gbà látinú ìrírí àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. (Ìṣe 4:1–5:42) Bí a bá sì pàfiyèsí wọn sí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń darí àwọn nǹkan gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ẹ́sítérì, ó dájú pé ìyẹn náà yóò túbọ̀ fún àwọn ará ní ìgboyà.

Nígbà mìíràn, àwọn kan lè máa wá sí ìpàdé ìjọ kí wọ́n má sì tẹ̀ síwájú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n lè máa rò ó pé irú ìgbésí ayé tí àwọn ti gbé sẹ́yìn burú jáì débi pé Ọlọ́run ò ní lè dárí ji àwọn. O lè sọ ìtàn ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀ràn Mánásè Ọba fún wọn. (2 Kíró. 33:1-16) O sì lè sọ ìtàn tàwọn èèyàn ìlú Kọ́ríńtì àtijọ́, tí wọ́n yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà láti di Kristẹni, tí Ọlọ́run sì polongo wọn pé wọ́n jẹ́ olódodo.—1 Kọ́r. 6:9-11.

Ǹjẹ́ ó láwọn kan tó ń ronú pé ìṣòro tó bá àwọn fi hàn pé àwọn ti pàdánù ojú rere Ọlọ́run? O lè rán wọn létí ohun tó dé bá Jóòbù àti bí Ọlọ́run ṣe bù kún un jìngbìnnì nítorí pé kò yẹsẹ̀ nínú ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. (Jóòbù 1:1-22; 10:1; 42:12, 13; Sm. 34:19) Àwọn olùtùnú èké tó tọ Jóòbù wá ló ń ṣàlàyé òdì pé ó ní láti jẹ́ pé Jóòbù ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan ni. (Jóòbù 4:7, 8; 8:5, 6) Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́kàn le tí wọ́n sì “ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́,” ńṣe ni wọ́n sọ fún wọn pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 14:21, 22) Lónìí bákan náà, o lè mú àwọn tó ń kojú àdánwò lọ́kàn le bí o bá fi yé wọn pé gbogbo Kristẹni ni yóò ní láti lo ìfaradà lójú inúnibíni, àti pé ẹ̀mí ìfaradà tí wọ́n ní ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.—Òwe 27:11; Mát. 24:13; Róòmù 5:3, 4; 2 Tím. 3:12.

Gba àwọn olùgbọ́ rẹ níyànjú láti ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nínú ìgbésí ayé tiwọn fúnra wọn. Bí o bá rán wọ́n létí díẹ̀, wọ́n lè wá fúnra wọn rí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. A kà á nínú Sáàmù 32:8 pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Bí o bá mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ rántí ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà ṣamọ̀nà wọn tàbí bó ṣe fún wọn lókun, wàá jẹ́ kí wọ́n lè rí i pé lóòótọ́ Jèhófà dìídì ń tọ́jú àwọn gan-an alára àti pé kò ní ṣàì ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣòro kíṣòro tí wọ́n lè wà nísinsìnyí.—Aísá. 41:10, 13; 1 Pét. 5:7.

Fìdùnnú Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tí Ọlọ́run Ń Gbé Ṣe Nísinsìnyí. Nígbà tí o bá ń wá ọ̀nà láti fún àwọn arákùnrin rẹ níṣìírí, pàfiyèsí wọn sí ohun tí Jèhófà ń ṣe nísinsìnyí. Tí o bá sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n dùn mọ́ ọ, wàá mú kí irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀ sọ lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ pẹ̀lú.

Wo àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa forí ti àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé. Ó ń fọ̀nà tó dára jú lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé hàn wá. (Aísá. 30:21) Ó ṣàlàyé ohun tó fa ìwà ọ̀daràn, àìsí-ìdájọ́-òdodo, ipò òṣì, àìsàn àti ikú fún wa, ó sì sọ bí òun yóò ṣe mú gbogbo ìwọ̀nyí wá sópin. Ó mú ká wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará onífẹ̀ẹ́. Ó fún wa láǹfààní iyebíye ti àdúrà gbígbà. Ó gbé àǹfààní jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. Ó là wá lójú láti rí i pé Kristi ti gorí ìtẹ́ ní ọ̀run àti pé òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan búburú yìí ti dé tán.—Ìṣí. 12:1-12.

Fi àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè wa kún àwọn ìbùkún wọ̀nyí pẹ̀lú. Bí o bá sọ̀rọ̀ àwọn ìpèsè wọ̀nyí lọ́nà tó fi hàn pé o mọrírì wọn tọkàntọkàn, wàá jẹ́ kí ìpinnu àwọn yòókù láti máa pàdé pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ará túbọ̀ lágbára sí i.—Héb. 10:23-25.

Àwọn ìròyìn tó ń fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà ń bù kún ìsapá wa lóde ẹ̀rí tún ń fúnni lókun pẹ̀lú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ń mú “ìdùnnú ńlá bá gbogbo àwọn ará” bí wọ́n ṣe ń sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń yí padà di Kristẹni. (Ìṣe 15:3) Ìwọ náà lè mú ìdùnnú bá àwọn ará nípa sísọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró fún wọn.

Tó o bá mú kí olúkúlùkù àwọn ará rí bí ohun tí wọ́n ń ṣe ti ṣe pàtàkì tó á tún fún wọn láfikún ìṣírí. Yìn wọ́n fún ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Yin àwọn tó jẹ́ pé ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn kò jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn tó nǹkan mọ́ síbẹ̀ tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ fara dà á nìṣó. Rán wọn létí pé Jèhófà kò gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n ti fi hàn fún orúkọ rẹ̀. (Héb. 6:10) Bí ìgbàgbọ́ ẹni bá dúró gbọn-in gbọn-in nígbà ìdánwò, ohun iyebíye lonítọ̀hún ní yẹn. (1 Pét. 1:6, 7) Àwọn ará nílò irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀.

Sọ̀rọ̀ Tinútinú Nípa Ìrètí Ọjọ́ Iwájú. Àwọn ìlérí tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ń bọ̀ wá, jẹ́ orísun ìṣírí pàtàkì fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ràn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ tiẹ̀ lè ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyẹn lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n fífi tí o fi ìmọrírì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí yìí lè mú kí o sọ ìlérí wọ̀nyí dọ̀tun lọ́kàn wọn. O lè mú kí ó túbọ̀ dá wọn lójú pé wọ́n á ṣẹ, kí o sì mú kí wọ́n túbọ̀ mọrírì rẹ̀ gidigidi lọ́kàn wọn. Bí o bá ń fi ohun tó o ti kọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò wàá lè ṣe èyí.

Ọ̀gá ni Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ nínú fífún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ìṣírí àti Òkun. Síbẹ̀, o ṣì lè bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i pé àwọn èèyàn rẹ̀ rí ìṣírí àti okun yìí gbà. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ, lo àǹfààní náà láti jẹ́ kí wọ́n rí ìṣírí àti okun gbà.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Nígbà tí o bá ń múra ọ̀rọ̀ tí o máa sọ, gbìyànjú láti rántí àwọn ìṣòro tí àwọn tó wà nínú àwùjọ ní. Fara balẹ̀ ronú nípa bó o ṣe máa fún wọn níṣìírí àti okun.

  • Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko. Fi hàn bí ohun tó sọ ṣe kan àwọn ipò tí a máa ń dojú kọ.

  • Sọ̀rọ̀ tọkàntọkàn.

ÌDÁNRAWÒ: Nígbà tí o bá ń ka Bíbélì kíkà tàbí tí ò ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ ti ọ̀sẹ̀ yìí, yan apá kan tí o rò pé o lè lò láti fi fún àwọn èèyàn níṣìírí. Sọ ọ́ fún ẹnì kan nínú ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́