-
Fún Àwùjọ Ní Ìṣírí Àti OkunJàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
-
-
èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ń bọ̀ wá, jẹ́ orísun ìṣírí pàtàkì fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ràn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ tiẹ̀ lè ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyẹn lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n fífi tí o fi ìmọrírì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí yìí lè mú kí o sọ ìlérí wọ̀nyí dọ̀tun lọ́kàn wọn. O lè mú kí ó túbọ̀ dá wọn lójú pé wọ́n á ṣẹ, kí o sì mú kí wọ́n túbọ̀ mọrírì rẹ̀ gidigidi lọ́kàn wọn. Bí o bá ń fi ohun tó o ti kọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò wàá lè ṣe èyí.
Ọ̀gá ni Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ nínú fífún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ìṣírí àti Òkun. Síbẹ̀, o ṣì lè bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i pé àwọn èèyàn rẹ̀ rí ìṣírí àti okun yìí gbà. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ, lo àǹfààní náà láti jẹ́ kí wọ́n rí ìṣírí àti okun gbà.
-
-
Máa Bá Ìtẹ̀síwájú Rẹ NìṣóJàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
-
-
Máa Bá Ìtẹ̀síwájú Rẹ Nìṣó
ǸJẸ́ ìwọ bí ẹnì kan tíì ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìmọ̀ràn inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ yìí látòkèdélẹ̀? Ǹjẹ́ o sì ti ṣe gbogbo ìdánrawò tí a dámọ̀ràn rẹ̀ tán pátá? Ǹjẹ́ ò ń fi kókó kọ̀ọ̀kan sílò nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, yálà ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí ní àwọn ìpàdé yòókù àti nígbà tí o bá wà lóde ẹ̀rí?
Máa bá a lọ láti jàǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Láìka bó ṣe wù kó ti pẹ́ tó tí o ti ń bá ọ̀rọ̀ sísọ bọ̀, àwọn ibi tí wàá ti lè tẹ̀ síwájú sí i ṣì wà.
-