ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | April 1
    • Korinti: “[Satani] ti sọ ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ di afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tíí ṣe àwòrán Ọlọrun, kí ó máṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.” (2 Korinti 4:⁠4) Satani yóò fẹ́ láti sọ àwọn Kristian tòótọ́ di afọ́jú ní ọ̀nà yìí pẹ̀lú. Nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní Edeni, ó lo ejò kan láti ṣi ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lọ́nà. Lónìí, ó ń lo fídíò oníwà-ipá tàbí oníwà pálapàla àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n. Ó ń lo rédíò, ìwé, àti orin. Ohun ìjà lílágbára tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ẹgbẹ́ búburú. (Owe 4:14; 28:7; 29:⁠3) Fi ìgbà gbogbo mọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ohun tí wọ́n jẹ́​—⁠àwọn ìhùmọ̀ àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.

      21 Rántí, àwọn ọ̀rọ̀ Satani ní Edeni jẹ́ irọ́; àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa jẹ́ òtítọ́. Láti ìgbà ìjímìjí yẹn, ọ̀ràn náà ti ń báa lọ bákan náà. Satani ti fìgbà gbogbo jásí òpùrọ́, tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sì ti jẹ́ òtítọ́ láìkùnà. (Romu 3:⁠4) Bí a bá rọ̀mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àwa yóò fìgbà gbogbo wà ní ìhà tí ń borí nínú ogun láàárín òtítọ́ àti èké. (2 Korinti 10:​4, 5) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti kọ gbogbo ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Ní ọ̀nà yẹn àwa yóò forítì títí di àkókò náà nígbà tí ogun láàárín òtítọ́ àti èké yóò parí. Òtítọ́ yóò ti borí. Satani yóò ti di àfẹ́kù, tí a óò sì máa gbọ́ kìkì ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lórí ilẹ̀-ayé.​—⁠Isaiah 11:⁠9.

      Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?

      ◻ Nígbà wo ni a kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù?

      ◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn irọ́ tí Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gbélékè?

      ◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Satani fi jẹ́ aláápọn lọ́nà lílégbákan lónìí?

      ◻ Kí ni Satani ń lò láti gbé ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù lékè?

      ◻ Àwọn ìbùkún wo ni ó jẹ́ ti àwọn tí wọ́n rọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?

  • Ìwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | April 1
    • Ìwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?

      “Àwa ti gbà, kìí ṣe ẹ̀mí ti ayé, bíkòṣe Ẹ̀mí tíí ṣe ti Ọlọrun.”​—⁠1 KORINTI 2:⁠12.

      1, 2. Ìṣẹ̀lẹ̀ abaninínújẹ́ tí ó nííṣe pẹ̀lú gáàsì olóró wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bhopal, India, ṣùgbọ́n “gáàsì” aṣekúpani jù bẹ́ẹ̀ lọ́ wo ni a ń mí sínú kárí ayé?

      NÍ ALẸ́ píparọ́rọ́ kan ní December 1984, ohun amúnigbọ̀nrìrì kan ṣẹlẹ̀ ní Bhopal, India. Ilé-iṣẹ́ kẹ́míkà kan wà ní ìlú-ńlá yẹn, fáàbù kan sì ṣiṣẹ́gbòdì nínú ọ̀kan lára àwọn táńkà tí wọ́n ń tọ́jú gáàsì sí, ní alẹ́ oṣù December yẹn. Lójijì, ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù gáàsì methyl isocyanate bẹ̀rẹ̀ síí tú sínú afẹ́fẹ́. Bí atẹ́gùn ti gbé e, gáàsì aṣekúpani yìí jà rànyìn wọ inú ilé lọ bá àwọn ìdílé tí ń sùn. Àwọn tí wọn kú wọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí púpọ̀ síi sì di aláàbọ̀ ara. Òun ni ìjábá ilé-iṣẹ́ tí o tíì burú jùlọ títí di àkókò yẹn.

      2 Àwọn ènìyàn banújẹ́ nígbà tí wọn gbọ́ nípa Bhopal. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe jẹ́ aṣekúpani tó, gáàsì tí ó tú jáde níbẹ̀ pa ènìyàn kíkéré jọjọ ju iye tí ń kú nípa tẹ̀mí nítorí “gáàsì” kan tí àwọn ènìyàn kárí ayé ń mí sínú lójoojúmọ. Bibeli pè é ní “ẹ̀mí ti ayé.” Afẹ́fẹ́ aṣekúpani yẹn ni aposteli Paulu fi ìyàtọ̀ rẹ̀ wéra pẹ̀lú ẹ̀mí tí ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá nígbà tí ó wí pé: “Ṣùgbọ́n àwa ti gbà, kìí ṣe ẹ̀mí ti ayé, bíkòṣe Ẹ̀mí tíí ṣe ti Ọlọrun; kí àwa kí ó lè mọ ohun tí a fifún wa ní ọ̀fẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.”​—⁠1 Korinti 2:⁠12.

      3. Kí ni “ẹ̀mí ti ayé”?

      3 Kí ni “ẹ̀mí ti ayé” náà gan-⁠an? Bí ìwé The New Thayer’s Greek English Lexicon of

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́