ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
    • ORÍ 34

      Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?

      Ká sọ pé ìwọ àtàwọn ọmọbìnrin méjì kan jọ wà níbi tẹ́ ẹ ti ń jẹun níléèwé yín, lọmọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé bá wọlé wá.

      Èyí àkọ́kọ́ sọ fún ẹ pé: “Ṣó o mọ̀ pé Brett gba tìẹ gan-an. Bó ṣe wò ẹ́ ni mo ti mọ̀. Ńṣe ló ń fojú bá ẹ sọ̀rọ̀!”

      Èkejì ẹ̀ wá sọ sí ẹ létí pé: “Wò ó, jẹ́ n sọ fún ẹ, bọ̀bọ́ yẹn ò tíì lẹ́ni tó ń fẹ́!”

      Ìwọ náà ti rò bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Torí pé, lọ́jọ́ kan báyìí, Brett ti pè ẹ́ pé kó o wá síbi àpèjẹ kan nílé wọn. O ò lọ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ o ti ń ro ibi tí gbogbo ẹ̀ ì bá ti já sí ká ló o lọ ni.

      Ọmọbìnrin àkọ́kọ́ yẹn bá já lu nǹkan tó ò ń rò lọ́kàn.

      Ó sọ pé: “Ó mà dùn mí pé mo ti ní bọ̀bọ́ tèmi o, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, lọ́wọ́ kan ni màá wọlé sí Brett lára.”

      Ó wá wò ẹ́ bákan bákan. O ti ń ronú ibi tọ́rọ̀ yẹn ń lọ.

      Ó bá sọ pé, “Kí ló dé tíwọ ò tiẹ̀ fi ní bọ̀bọ́ kankan?”

      O kì í fẹ́ gbọ́ ìbéèrè yẹn! Ká sòótọ́, ó wù ẹ́ kí ìwọ náà ní bọ̀bọ́ kan tí wàá máa fẹ́. Àmọ́, wọ́n ti kọ́ ẹ pé ṣe ló yẹ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣe tán láti ṣègbéyàwó kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ọkùnrin. Ká ní ò síyẹn ni . . .

      Ọmọbìnrin kejì wá béèrè pé, “Ẹ kì í ṣerú ẹ̀ ní ìjọ yín, àbí?”

      O wá rò ó lọ́kàn ara ẹ pé, ‘Àbó mọ nǹkan tó wà lọ́kàn mi ni?’

      Ó wá fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ìwọ ò tiẹ̀ mọ̀ ju Bíbélì lọ láyé ẹ. Ṣó ò tiẹ̀ lè máa jayé orí ẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni?”

      ṢÉ WỌ́N ti fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ rí torí pé ò ń gbìyànjú láti fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè ti máa rò ó pé ìlànà Bíbélì tó o fi ń ṣèwà hù yìí ni ò jẹ́ kó o lè jayé orí ẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah pàápàá ti rò bẹ́ẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Àwọn ìlànà Bíbélì ká mi lọ́wọ́ kò. Ó wù mí pé kémi náà máa ṣe nǹkan tí mo bá fẹ́ bíi tàwọn ọmọléèwé mi.”

      Ṣàyẹ̀wò Ara Ẹ

      Kò dìgbà téèyàn bá jìyà kó tó gbọ́n. Ká sòótọ́, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì tún bá Ìwé Mímọ́ mu pẹ̀lú pé ká máa fọ̀rọ̀ ẹlòmíì kọ́gbọ́n, bí Ásáfù tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù ti ṣe. Ìgbà kan wà tó ronú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ti ń káni lọ́wọ́ kò jù. Àmọ́ nígbà tó rí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó pa ọ̀nà Ọlọ́run tì, ó túnnú ẹ̀ rò. Ó wá sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà tó yá pé “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” ni wọ́n wà.—Sáàmù 73:18.

      Bó o ti ń fọ̀rọ̀ Ásáfù yìí sọ́kàn, wá gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ, ìyẹn àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti fìgbà kan rí kọ àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀, tí wọ́n sì ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó.

      ● Àwọn nǹkan wo ló mú kó o ronú bẹ́ẹ̀ yẹn tó sì mú kó o hùwà tó o hù?

      Deborah: “Mo máa ń rí i pé gbogbo àwọn ọmọ iléèwé mi ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́, ó sì dà bíi pé, ìyẹn ń múnú wọn dùn. Bí mo bá wà láàárín wọn, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe ń so mọ́ra wọn tí wọ́n sì ń fẹnu kora wọn lẹ́nu, ńṣe ló máa ń dà bíi pé èmi nìkan ni ò dákan mọ̀. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ronú nípa ọmọkùnrin kan tí mo fẹ́ràn. Ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí láti máa wà lọ́dọ̀ ẹ̀.”

      Mike: “Mo máa ń kàwé tó dá lórí ìbálòpọ̀, mo sì máa ń wo àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n tó máa ń jẹ́ kí ìbálòpọ̀ wù mí. Sísọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ mi túbọ̀ máa ń jẹ́ kó wù mí láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Témi àtọmọge bá dá wà, mo máa ń rò pé mo kàn lè fara rò ó lára láìbá a sùn àti pé mo mọ̀gbà tó yẹ kí n dúró.”

      Andrew: “Mo máa ń wo àwòrán oníhòòhò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí lámujù. Mo sì máa ń lọ sóde àríyá pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà.”

      Tracy: “Mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé kò yẹ kí n ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, àmọ́ mi ò kórìíra ẹ̀. Kò wù mí pé kí n ṣe é, àmọ́ bọ́ràn náà ṣe rí lára mi ò jẹ́ kí n lè ronú jinlẹ̀. Ó wá di pé ẹ̀rí ọkàn mi ò dá mi lẹ́bi mọ́.”

      ● Ṣé inú rẹ dùn sóhun tó o ṣe yẹn?

      Deborah: “Inú mi kọ́kọ́ dùn pé kò sẹ́ni tó ń dí mi lọ́wọ́ mọ́ láti ṣe nǹkan tó wù mí àti pé èmi náà ti wá bẹ́gbẹ́ mu. Àmọ́ ayọ̀ yẹn ò tọ́jọ́. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ìṣekúṣe ni mo ṣe, mi ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé mi ò tíì níbàálòpọ̀ rí, mo wá rí i pé tèmi ti bá mi. Mo wá kábàámọ̀ pé mo ti jẹ́ kẹ́nì kan já ìbálé mi.”

      Andrew: “Ńṣe ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti máa hùwà àìtọ́. Síbẹ̀, mò ń dára mi lẹ́bi, ohun tí mo ṣe sì bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an.”

      Tracy: “Mo ti fi ìṣekúṣe bayé ara mi jẹ́. Ńṣe ni mo rò pé èmi àti bọ̀bọ́ tí mò ń fẹ́ yẹn máa gbádùn ara wa dọ́ba, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ìrora ọkàn, wàhálà àti ìbànújẹ́ la kàn kó ara wa sí. Òròòru ni mo máa ń wa ẹkún mu lórí bẹ́ẹ̀dì mi, mo máa ń kábàámọ̀ pé, ǹ bá sì ti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ o.”

      Mike: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé nǹkan kan ti bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Mo gbìyànjú láti gbójú fo ẹ̀dùn ọkàn tí mò ń kó bá àwọn ẹlòmíì, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Ó máa ń ká mi lára pé mò ń ba àwọn ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́ bí mo ṣe ń gbádùn ara mi.”

      ● Ìmọ̀ràn wo lo ní fáwọn ọ̀dọ́ tó bá ń ṣiyè méjì bóyá àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà ń káni lọ́wọ́ kò?

      Tracy: “Má ṣe fàwọn ìlànà Jèhófà ṣeré, àwọn tó fi ń ṣèwà hù ni kó o sì máa bá rìn. Ìyẹn ló lè fún ẹ láyọ̀.”

      Deborah: “Má ṣe ronú láé pé ọ̀rọ̀ ara ẹ nìkan ni, ohun tó bá sì wù ẹ́ lo lè ṣe. Ohun tó o bá ṣe máa nípa lórí àwọn ẹlòmíì. Bó o bá sì kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run, ìwọ lo máa jìyà tó pọ̀ jù.”

      Andrew: “Bó ò bá tíì gbọ́n, ṣe lo máa rò pé báwọn ojúgbà ẹ ṣe ń jayé orí wọn ló dáa. Nìwọ náà á bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tiwọn. Torí náà, fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o má bàa kábàámọ̀.”

      Mike: “Ọ̀wọ̀ ara ẹni wà lára nǹkan pàtàkì tí Jèhófà dá mọ́ wa, kò sì fẹ́ ká máa ṣèṣekúṣe. Ṣe lo máa tara ẹ lọ́pọ̀, bó o bá sọ àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí nù torí pé o ò kóra ẹ níjàánu. Fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí ẹ àtàwọn àgbàlagbà míì. Bó o bá ti ṣàṣìṣe, má bò ó mọ́ra, tètè sọ fún wọn, kó o sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Bó o bá ń ṣe àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn tòótọ́.”

      Ṣé Ìlànà Bíbélì Ń Ká Ẹ Lọ́wọ́ Kò Ni àbí Ó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

      “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kíwọ náà láyọ̀. (1 Tímótì 1:11; Oníwàásù 11:9) Àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì máa ṣe ẹ́ láǹfààní. O lè máa rò pé àwọn ìlànà yẹn ń ká ẹ lọ́wọ́ kò. Àmọ́, ká sòótọ́, àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà wulẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ ni.

      Ó dájú pé o lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì. Bó o bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, wàá múnú Jèhófà dùn, wàá sì ṣera ẹ láǹfààní.—Aísáyà 48:17.

      NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

      O lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Wádìí bó o ṣe lè ṣe é.

      ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

      “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17.

      ÌMỌ̀RÀN

      Ronú nípa bó o ṣe lè ṣàlàyé fún àbúrò ẹ pé àwọn ìlànà Bíbélì bọ́gbọ́n mu. Bó o bá ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára sí i.

      ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

      Àjọṣe rere tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lè bà jẹ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, àmọ́ ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún láti tún un ṣe.

      OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

      Ohun tí màá ṣe kí n lè mọ báwọn ìlànà Bíbélì ṣe bọ́gbọ́n mu tó ni pé ․․․․․

      Bí ìwà àwọn tí kò fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù bá ń wù mí, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

      Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

      KÍ LÈRÒ Ẹ?

      ● Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn jìyà kó tó gbọ́n, bó bá dọ̀rọ̀ rírú òfin Ọlọ́run?

      ● Kí lo rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Deborah, Mike, Andrew àti Tracy?

      ● Kí nìdí táwọn kan fi lè máa ronú pé àwọn òfin Ọlọ́run ń ká àwọn lọ́wọ́ kò, àmọ́ kí nìdí tá a fi lè sọ pé wọn ò ro tọjọ́ ọ̀la mọ́ ọn?

      [Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 285]

      “Ìbẹ̀rù bí wọ́n ṣe máa báàyàn wí tó bá ṣe nǹkan tí kò dáa ò burú tó ìnira téèyàn máa ní tó bá ń bò ó mọ́ra.”—Donna

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 288]

      Àwọn ìlànà Bíbélì ò ká ẹ lọ́wọ́ kò; wọ́n wulẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ ni

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
    • ORÍ 35

      Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

      Nígbà tí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Jeremy ló tó mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé, “Dádì mi fi wá sílẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12]. Mo wá ń gbàdúrà sí Jèhófà lórí bẹ́ẹ̀dì mi lọ́jọ́ kan pé kó jẹ́ kí dádì mi pa dà wá sílé.”

      Nígbà tọ́kàn Jeremy dà rú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Nígbà tó ka Sáàmù 10:14, nǹkan tó kà níbẹ̀ wú u lórí gan-an. Ẹsẹ yẹn sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ni aláìrìnnàkore, ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́. Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.” Jeremy sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ tó sì ń sọ fún mi pé òun ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun sì ni Bàbá mi. Bàbá míì wo ni mo tún lè ní tó máa dà bíi Jèhófà?”

      BÓYÁ irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremy yìí ló ń ṣẹlẹ̀ síwọ náà tàbí irú ẹ̀ kọ́, Bíbélì fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Ó sọ pé kó o ‘sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ ẹ.’ (Jákọ́bù 4:8) Ronú nípa ohun táwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí: Bó ò tiẹ̀ lè rí Ọlọ́run sójú, tí kì í sì í ṣe ẹgbẹ́ ẹ lọ́nàkọnà, Jèhófà Ọlọ́run ń pè ẹ́ pé kó o wá jẹ́ ọ̀rẹ́ òun!

      Àmọ́ tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àfi kó o ṣe àwọn nǹkan kan. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Bó o bá gbin òdòdó sínú ilé, o mọ̀ pé kò kàn lè máa dàgbà fúnra ẹ̀. Àfi kó o máa bomi sí i déédéé, kó o sì gbé e síbi tó ti máa lè hù dáadáa. Béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run náà nìyẹn. Báwo lo ṣe lè máa bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́?

      Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Pàtàkì

      Téèyàn bá ń bá ẹlòmíì ṣọ̀rẹ́, èèyàn á máa fetí sílẹ̀, èèyàn á sì máa sọ tinú ẹ̀. Ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe tó bá ń bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ náà nìyẹn. Bá a bá ń ka Bíbélì, inú ẹ̀ la ti máa ń gbọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní í sọ fún wa.— Sáàmù 1:2, 3.

      Ká sòótọ́, o lè máà nífẹ̀ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ó tẹ́ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́rùn láti máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n máa ṣeré, tàbí kí wọ́n kàn máa ṣe fàájì láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wọn ju kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ. Àmọ́, tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kò sọ́gbọ́n tó o lè dá sí i. Àfi kó o máa fetí sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

      Fọkàn ẹ balẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò dà bí iṣẹ́ ilé. O lè gbádùn ẹ̀ kódà tó ò bá kí í kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀. Nǹkan tó o ní láti kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lais sọ pé: “Mo ní ètò tí mo ṣe. Mo máa ń ka orí kọ̀ọ̀kan látinú Bíbélì láràárọ̀.” Bí Maria tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ṣe ṣètò ara ẹ̀ yàtọ̀ síyẹn. Ó sọ pé: “Mo máa ń ka Bíbélì kí n tó sùn lálaalẹ́.”

      Bó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láyè ara ẹ, wo àpótí tó wà lójú ìwé 292. Kó o wá kọ ìgbà tó o lè máa lo nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sórí ìlà yìí:

      ․․․․․

      Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni wíwá àkókò láti máa ka Bíbélì jẹ́ o. Bó o bá ti bẹ̀rẹ̀, wàá wá rí i pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló rọrùn láti máa ka Bíbélì. O lè fara mọ́ ohun tí Jezreel, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá [11], sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, pé “Àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì ṣòro lóye, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ò sì dùn.” Bó bá jẹ́ pé ohun tíwọ náà rò nìyẹn, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Máa wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ, ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Bó pẹ́ bó yá, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á bẹ̀rẹ̀ sí dùn mọ́ ẹ, wàá sì máa jàǹfààní ẹ̀ bó o bá ṣe fẹ́ ẹ sí!

      Àdúrà Ṣe Pàtàkì

      Àdúrà la fi ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ìwọ náà wo irú ẹ̀bùn àtàtà tí àdúrà jẹ́! O lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, bóyá lọ́sàn-án tàbí lóru. Kò sígbà tá ò lè bá a sọ̀rọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó tún fẹ́ láti gbọ́ ohun tó o bá ní í sọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà ẹ́ níyànjú pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

      Ẹsẹ Bíbélì yẹn fi hàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè bá Jèhófà sọ. Títí kan àwọn ìṣòro tó o bá ní àti ohunkóhun tó bá ń gbé ẹ lọ́kàn. Ó sì tún yẹ kó o dúpẹ́ fáwọn nǹkan tó bá ṣe fún ẹ. Ó ṣe tán, o ṣáà máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá ṣe ẹ́ lóore. Ó yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà náà, ẹni tó ti ṣohun tí ọ̀rẹ́ kan ò lè ṣe fún ẹ.—Sáàmù 106:1.

      Kọ àwọn nǹkan tó ò ń dúpẹ́ pé Jèhófà ti ṣe fún ẹ sórí ìlà yìí.✎

      ․․․․․

      Kò sí àníàní pé o máa ń ṣàníyàn, àwọn nǹkan kan sì máa ń gbé ẹ lọ́kàn sókè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”

      Kọ àwọn nǹkan tó ń gbé ẹ lọ́kàn sókè, tó o fẹ́ fi sínú àdúrà ẹ sórí ìlà yìí.

      ․․․․․

      Ìrírí Tó O Ní

      Nǹkan kan tún wà nípa jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tí kò yẹ kó o gbójú fò dá. Dáfídì, tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù, kọ̀wé pé: “Tọ́ ọ wò, [kó o] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” (Sáàmù 34:8) Dáfídì ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ nǹkan kan tí ò bá ti gbẹ̀mí ẹ̀ ni nígbà tó kọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n [34]. Ibi tó ti ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba tó fẹ́ pa á, ló bá sá lọ sáàárín àwọn Filísínì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá rẹ̀. Nígbà tó rí i pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa òun, ló bá ṣe bí ẹni tórí ẹ̀ ti yí, kó lè bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.—1 Sámúẹ́lì 21:10-15.

      Dáfídì ò sọ pé mímọ̀ ọ́n ṣe òun ni. Àmọ́, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ó sọ nínú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n yẹn pé: “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, Ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi. (Sáàmù 34:4) Ìrírí tí Dáfídì fúnra ẹ̀ ní ló jẹ́ kó sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.”a

      Ṣó o lè rántí ohun kan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, tó fi hàn pé Jèhófà ò fi ẹ́ sílẹ̀? Bó o bá rántí, kọ ọ́ sínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí. Fi sọ́kàn pé: Kì í ṣe dandan pé kó jẹ́ nǹkan àràmàǹdà. Gbìyànjú láti ronú lórí àwọn nǹkan kan, tó o tiẹ̀ lè má kà sí pàápàá, èyí tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ lójoojúmọ́.

      ․․․․․

      Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ ti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹn dáa gan-an. Àmọ́, ìwọ fúnra ẹ ṣì ní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bó ò bá tíì di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àwọn nǹkan tá a sọ nínú orí yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jèhófà máa bù kún ìsapá ẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.”—Mátíù 7:7.

      KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 38 ÀTI 39 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

      NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

      Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn? Kọ́ bó o ṣe lè ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́.

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Àwọn Bíbélì kan túmọ̀ “tọ́ ọ wò” kó o “sì rí i” sí, “wádìí fúnra ẹ,” “wá a rí fúnra ẹ” àti “tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wàá rí i.”—Ìtumọ̀ Contemporary English Version, Today’s English Version àti The Bible in Basic English.

      ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

      “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn”—Mátíù 5:3.

      ÌMỌ̀RÀN

      Bó o bá ń ka ojú ìwé mẹ́rin péré nínú Bíbélì lójoojúmọ́, wàá parí odindi Bíbélì láàárín ọdún kan.

      ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

      Bó o ṣe ń kàwé yìí, tó o sì ń fàwọn ìmọ̀ràn tá à ń mú jáde látinú Bíbélì ṣèwà hù fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ.—Jòhánù 6:44.

      OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

      Kí n lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ sí i kọ́ bí mo bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, màá ․․․․․

      Ohun tí màá ṣe kí n bàa lè túbọ̀ máa gbàdúrà déédéé ni pé ․․․․․

      Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

      KÍ LÈRÒ Ẹ?

      ● Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa gbádùn dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      ● Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fẹ́ láti gbọ́ àdúrà àwa èèyàn aláìpé?

      ● Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àdúrà tó ò ń gbà túbọ̀ máa nítumọ̀?

      [Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 291]

      “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń sọ àsọtúnsọ bí mo bá ń gbàdúrà. Àmọ́ ní báyìí, àwọn nǹkan tó dáa àtàwọn nǹkan tí kò dáa tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń fi sínú àdúrà. Níwọ̀n bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ ò sì ti dọ́gba, mi ò sọ àsọtúnsọ mọ́.”—Eve

      [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 292]

      Mọ Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Ẹ

      1. Yan ìtàn Bíbélì tó bá wù ẹ́ láti kà. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ lọ́gbọ́n kóun tó o bá kà lè yé ẹ.

      2. Fara balẹ̀ ka ìtàn náà. Má ṣe sáré kà á. Bó o bá ṣe ń kà á, máa fọkàn yàwòrán nǹkan tó o bá ń kà. Pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ò ń kà, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn, bíi pé ò ń gbọ́ ohùn àwọn èèyàn yẹn, bíi pé ò ń gbóòórùn tí wọ́n ń gbọ́, ò ń bá wọn jẹun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jẹ́ kó dà bíi pé ìtàn yẹn ń ṣẹlẹ̀ lójú ẹ!

      3. Ronú nípa ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yẹn. Kó o máa bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi:

      ● Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí wọ́n kọ ìtàn yìí sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀?

      ● Àpẹẹrẹ ta ni mo lè tẹ̀ lé nínú ìtàn yìí, àpẹẹrẹ ta ló sì yẹ kí n fi ṣàríkọ́gbọ́n?

      ● Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mo lè rí kọ́ nínú ìtàn tí mo kà yìí?

      ● Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan?

      4. Gbàdúrà ṣókí sí Jèhófà. Sọ ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ látinú Bíbélì fún Jèhófà nígbà tó o bá ń gbàdúrà, àti bó o ṣe fẹ́ fi sílò. Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn tó fún ẹ, ìyẹn Bíbélì Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀!

      [Àwòrán]

      “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” —Sáàmù 119:105.

      [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 294]

      Kọ́kọ́ Ṣohun Tó Yẹ

      Sọ́wọ́ ẹ máa ń dí jù láti gbàdúrà? Àbí o kì í ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ohun tó máa ń pinnu bóyá wàá ráyè ni ohun tó o bá kà sí pàtàkì.

      Gbìyànjú kiní yìí wò ná: Kó òkúta tó pọ̀ díẹ̀ sínú ike kan. Kó o wá rọ iyẹ̀pẹ̀ sínú ike náà títí tó fi máa kún. Ó túmọ̀ sí pé iyẹ̀pẹ̀ àti òkúta ló wà nínú ike náà.

      Wá kó gbogbo nǹkan tó wà nínú ike náà kúrò. Kó o sì tún kó gbogbo ẹ̀ padà sínú ẹ̀, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, iyẹ̀pẹ̀ ni kó o kọ́kọ́ kó sí i, kó o tó kó òkúta sínú ẹ̀. Ṣó gba gbogbo òkúta náà? Kò lè gbà á torí pé iyẹ̀pẹ̀ yẹn lo kọ́kọ́ kó sínú rẹ̀.

      Kí nìyẹn kọ́ wa? Bíbélì sọ pe ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Bó o bá lọ fàwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí eré ìtura sípò àkọ́kọ́, o ò ní ráyè fún nǹkan tó ṣe pàtàkì, ìyẹn àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́, bó o bá fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì, wàá rí i pé o máa ráyè fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wàá sì tún ráyè níwọ̀nba láti ṣeré ìtura. Ohun tó máa pinnu gbogbo ẹ̀ lohun tó o bá kọ́kọ́ kó sínú ike ẹ!

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 290]

      Béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ máa tọ́jú òdòdó tó bá gbìn sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kó o máa ṣàwọn ohun tá á mú kó o máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ọlọ́run?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
    • ORÍ 36

      Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ọlọ́run?

      Kí ló lè mú kó o máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ fọ́mọ kíláàsì ẹ?

      □ O ò ní ìmọ̀ Bíbélì

      □ Wọ́n lè fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́

      □ O ò mọ bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀

      Ọ̀nà wo ló máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn pé kó o gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́?

      □ Bíbá ẹnì kan ṣoṣo sọ̀rọ̀

      □ Bíbá gbogbo ọmọ kíláàsì mi sọ̀rọ̀

      □ Kíkọ àwọn nǹkan tí mo gbà gbọ́ sórí ìwé fáwọn èèyàn láti kà

      Kọ orúkọ ọmọléèwé yín kan tó o rò pé ó lè fetí sọ́rọ̀ Bíbélì tó o bá dá a sílẹ̀. ․․․․․

      Ó ṢEÉ ṢE kó jẹ́ pé àwọn ọmọléèwé ẹ kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Bó bá jẹ́ pé nǹkan míì bí eré ìdárayá, aṣọ, ọ̀rọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin lo dá sílẹ̀, inú wọn á dùn láti dá sí i. Àmọ́ bóyá lo máa rẹ́ni sún mọ́ ẹ, bó o bá ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lo fẹ́ bá wọn sọ.

      Kì í ṣe pé wọn ò gba Ọlọ́run gbọ́ o, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló tiẹ̀ gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn lojú máa ń tì láti sọ̀rọ̀ lọ sápá ibẹ̀ yẹn. Wọ́n máa ń rò pé ‘irú ọ̀rọ̀ yẹn kì í dùn.’

      Ìwọ Ńkọ́?

      Ó lè má máa yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn ọmọléèwé yín lóòótọ́. Torí kò sẹ́ni tí ò fẹ́ káwọn èèyàn gba tòun, tí wọ́n bá wá lọ ń fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́, ìyẹn ló burú jù! Ṣé ọ̀rọ̀ lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ọmọléèwé ẹ sì lè wá ṣe nǹkan tó máa yà ẹ́ lẹ́nu o. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí: Ibo lọ̀rọ̀ ayé yìí ń lọ gan-an? Àti pé, Kí nìdí tíṣòro fi pọ̀ láyé yìí? Ó ṣeé ṣe kó tẹ́ wọn lọ́rùn láti bá ọmọdé ẹgbẹ́ wọn sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ju àgbàlagbà lọ.

      Àmọ́ ṣá o, ó lè dà bíi pé ó ṣòro fún ẹ láti máa báwọn ojúgbà ẹ sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ká sòótọ́, kò dìgbà tó o bá sọra ẹ di aláṣejù, o ò sì ní láti rò pé o gbọ́dọ̀ sọ ohun tó tọ́ gan-an. Ṣíṣàlàyé nǹkan tó o gbà gbọ́ dà bí ìgbà tó o bá fẹ́ ta gìtá. Ó lè máà kọ́kọ́ rọrùn. Àmọ́ bó o bá ṣe fi ń dánra wò sí ló ṣe máa mọ́ ẹ lára sí, wàá sì wá mọ̀ ọ́n dáadáa tó bá yá. Báwo lo wá ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ?

      O lè kọ́kọ́ sọ nǹkan kan tínú àwọn ọmọléèwé ẹ máa dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ níléèwé yín, o lè sọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ fún wọn. O sì lè lọ bá ẹnì kan ṣoṣo péré sọ̀rọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì ẹ. Nǹkan míì tó sì tún rọrùn táwọn ọ̀dọ̀ kan ti ṣe ni pé, wọ́n kó àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sórí tábìlì wọn níléèwé, wọ́n sì wá wò ó bóyá ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì wọn máa wá wò ó. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n wá, ibẹ̀ sì lọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀!

      Èwo nínú àwọn ọ̀nà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí ni wàá fẹ́ láti lò? ․․․․․

      Ṣáwọn ọ̀nà míì wà tó o rò pé o lè gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ fáwọn ọmọ kíláàsì ẹ? Bó bá wà, kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

      ․․․․․

      Ìgbà míì wà tí iṣẹ́ iléèwé yín lè fún ẹ láǹfààní láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n nínú kíláàsì yín? Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé nǹkan tó o bá gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá?

      Bó O Ṣe Lè Ṣàlàyé Nípa Ìṣẹ̀dá

      Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé, “Nígbà tí wọ́n dá ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ ní kíláàsì wa, ó yàtọ̀ pátápátá gbáà sí gbogbo ohun tí wọ́n ti fi kọ́ mi. Wọ́n ṣàlàyé ẹ̀ bíi pé òótọ́ ni, ìyẹn sì dojú ọ̀rọ̀ náà rú mọ́ mi lọ́wọ́.” Ohun tọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Raquel náà sọ ò yàtọ̀ síyẹn. Ó ní: “Jìnnìjìnnì bò mí nígbà tí tíṣà tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ló kàn tá a máa kọ́. Mo mọ̀ pé ó máa di dandan pé kí n ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ lórí ọ̀ràn tó máa ń fa àríyànjiyàn yìí.”

      Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ bí wọ́n bá dá ọ̀rọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ nínú kíláàsì yín? O gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) O rí àwọn nǹkan mèremère láyìíká tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá olóye kan wà. Àmọ́ ohun tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ yín ni pé èèyàn kàn ṣàdédé wà ni, ohun tí tíṣà yín sì ń sọ náà nìyẹn. Ó wá lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kí lo mọ̀ débi tí wàá fi máa báwọn ògbógi jiyàn?

      Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ nìkan kọ́ ni kò gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Ká sòótọ́, àwọn kan wà lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kò gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́ pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ olùkọ́ àtàwọn ọmọléèwé ni kò sì gbà á gbọ́ pẹ̀lú.

      Àmọ́, bó o bá fẹ́ ṣàlàyé nǹkan tó o gbà gbọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an lórí kókó yìí. Kò sídìí láti máa jiyàn lórí àwọn ohun tí Bíbélì ò bá ti ṣàlàyé ẹ̀ ní tààràtà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

      Ìwé tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì sọ pé ilẹ̀ ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ti wà láti àìmọye ọdún sẹ́yìn. Bíbélì sọ pé ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan míì ti wà ṣáájú ọjọ́ àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá. Torí náà, ilẹ̀ ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ gbọ́dọ̀ ti wà fún àìmọye ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

      Tíṣà mi sọ pé kò sí ọ̀nà tí Ọlọ́run lè gbà dá ayé láàárín ọjọ́ mẹ́fà péré. Bíbélì ò sọ pé wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] ni gígùn “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.

      Nínú kíláàsì wa, a jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nípa ìyàtọ̀ tó ti bá àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn látìgbà yìí wá. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan alààyè “ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:20, 21) Kò fara mọ́ èrò tó sọ pé látinú àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí làwọn nǹkan alààyè ti wá tàbí pé látinú ohun tín-tìn-tín kan ni Ọlọrun ti dá èèyàn. Àmọ́ ṣá o, “oríṣi” nǹkan abẹ̀mí kọ̀ọ̀kan lágbára láti mú oríṣi irú tiẹ̀ jáde. Torí náà, Bíbélì gbà pé ó ṣeé ṣe kí ìyípadà wáyé nínú “oríṣi” nǹkan alààyè kọ̀ọ̀kan.

      Pẹ̀lú àwọn nǹkan tá a ti sọ nínú orí yìí, kí lo máa sọ bí tíṣà tàbí ọmọ kíláàsì yín kan bá sọ pé:

      “Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fi hàn pé látara ẹranko làwa èèyàn ti jáde wá.” ․․․․․

      “Mi ò gba Ọlọ́run gbọ́ torí pé mi ò lè rí i.” ․․․․․

      Jẹ́ Káwọn Nǹkan Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú!

      Bó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí ẹ, o lè gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo torí pé wọ́n ti fi kọ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tó o ti ń dàgbà, wàá fẹ́ fi “agbára ìmọnúúrò” tó o ní sin Ọlọ́run, ìyẹn sì máa fi hàn pé ohun tó o gbà gbọ́ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Róòmù 12:1) Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Kí nìdí tí mo fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?’ Nígbà tí Sam tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] wo bí ara àwa èèyàn ṣe rí, ó sọ pé: “Nǹkan tó wà ńbẹ̀ pọ̀ gan-an ni, ó sì díjú gan-an, gbogbo ẹ̀ ló sì ń bára wọn ṣiṣẹ́ láìtàsé. Ara àwa èèyàn ò kàn lè ṣàdédé wà!” Holly tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Látìgbà tí mo ti lárùn àtọ̀gbẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ nípa bí ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi láti mọ bí ẹ̀yà ara kékeré kan tó ń jẹ́ pancreas, tó wà nínú ikùn, ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà pípabanbarì, láti mú kí ẹ̀jẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní káwọn ẹ̀yà ara yòókù sì máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.”

      Kọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó mú kó o gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà síbí yìí.

      1. ․․․․․

      2. ․․․․․

      3. ․․․․․

      Kò yẹ kó o máa rò pé tìẹ yàtọ̀ tàbí kó o máa tijú torí pé o gba Ọlọ́run gbọ́, o sì gbà pé òun ló dá ohun gbogbo. Àwọn ẹ̀rí tó wà fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan tó lóye ló dá wa.

      Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gan-an ló gba kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tí ò ṣe é fẹ̀rí tì lẹ́yìn, torí òun lèèyàn lè rí bí iṣẹ́ ìyanu tí kò sẹ́ni tó ṣe é! Bó o bá ro ọ̀rọ̀ yìí jinlẹ̀, wàá lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run dáadáa.

      NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

      Àwọn ẹgbẹ́ ẹ ń ṣèrìbọmi. Ṣéwọ náà ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?

      ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

      “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 1:16.

      ÌMỌ̀RÀN

      Máa kíyè sí bó o ṣe ń ṣe nígbà tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Bó bá hàn lójú ẹ pé ò ń tijú, àwọn ojúgbà ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́, tó o bá jẹ́ kóun tó ò ń sọ dá ẹ lójú báwọn ọmọléèwé ẹ náà ṣe máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́.

      ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

      Nígbà míì tí wọ́n bá ní káwọn tíṣà wá ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, wọn kì í lè ṣàlàyé ẹ̀, wọ́n á wá rí i pé torí pé wọ́n fi kọ́ àwọn làwọn náà ṣe gbà á gbọ́.

      OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

      Bí n bá fẹ́ bá ọmọ kíláàsì mi kan sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, ohun tí mo lè ṣe ni pé ․․․․․

      Bí wọ́n bá bi mí pé kí nìdí tí mo fi gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ohun tí màá sọ ni pé ․․․․․

      Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

      KÍ LÈRÒ Ẹ?

      ● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o sọ nǹkan tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì?

      ● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá níléèwé yín?

      ● Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì àwọn nǹkan tí Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ṣe?—Ìṣe 17:26, 27.

      [Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 299]

      Ìpínlẹ̀ ìwàásù ni iléèwé wa, àwa nìkan la sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.’’—Iraida

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 298]

      Ṣíṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run dà bí ìgbà tó o fẹ́ máa ta gìtá, àfi kó o kọ́kọ́ kọ́ ọ, bó o bá sì ṣe ń lò ó sí, ni wàá máa mọwọ́ ẹ̀ sí

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 301]

      O lè borí ẹ̀rù tó máa ń bà ẹ́ láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́