ORIN 70
Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Kristi kọ́ wa bá a ṣe máa fòótọ́ kọ́ni - Àti bí a ó ṣe máa wàásù. - Ó sọ pé: ‘Ẹ wá àwọn ẹni yíyẹ - Tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ òótọ́. - Tẹ́ ẹ bá délé kan, kí ẹ kọ́kọ́ kí wọn, - Kí ẹ bá wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà. - Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá sọ pé àwọn ò gbọ́, - Ẹ kúrò, ẹ lọ síbòmíràn.’ 
- 2. Ẹ bá àwọn tó tẹ́wọ́ gbà yín sọ́rọ̀; - Ẹ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. - Wọ́n máa gbọ́ torí pé wọ́n lọ́kàn tó dáa. - Láìpẹ́, àwọn náà yóò wá sin Jáà. - Má ṣe dààmú torí ohun tó o máa sọ; - Jèhófà yóò fi sí ọ lẹ́nu. - Tó o bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa, tó ń tuni lára, - Yóò mú kí onírẹ̀lẹ̀ fẹ́ gbọ́. 
(Tún wo Ìṣe 13:48; 16:14; Kól. 4:6.)