ORIN 79
Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Inú wa dùn pé à ń kọ́ àwọn - Àgùntàn ti Jèhófà. - Ààbò rẹ̀ dájú fún àwọn tó - Sọ òtítọ́ di tiwọn. - (ÈGBÈ) - Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà, - Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n, - Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà; - Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí. 
- 2. Bá a ṣe ń kọ́ wọn lọ́rọ̀ Ọlọ́run, - A máa ń gbàdúrà fún wọn. - Wọ́n ń kojú àdánwò, wọ́n ńborí; - Wọ́n ń lókun, Jáà ń bù kún wọn. - (ÈGBÈ) - Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà, - Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n, - Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà; - Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí. 
- 3. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run - Àti Ọmọ rẹ̀ Jésù; - Ìgbọràn àti ìfaradà - Máa jẹ́ kí wọ́n rí ìyè. - (ÈGBÈ) - Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà, - Jọ̀ọ́, fẹ̀mí rẹ dáàbò bò wọ́n, - Lórúkọ Jésù Ọmọ Rẹ, là ń gbàdúrà; - Kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí. 
(Tún wo Lúùkù 6:48; Ìṣe 5:42; Fílí. 4:1.)