-
Kí Nìdí Táwọn Kan Ò Fi Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2013 | November 1
-
-
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Kí Nìdí Táwọn Kan Ò Fi Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
“‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”—Jésù Kristi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí ní 33 Sànmánì Kristẹni.a
Kò rọrùn fún àwọn kan láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí pé lójú tiwọn àdììtú ni Ọlọ́run jẹ́. Wọ́n gbà pé ó jìnnà sí àwa ẹ̀dá àti pé ìkà ni. Ohun tí àwọn míì sọ rèé:
“Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi, ó ń ṣe mí bíi pé kò lè gbọ́ àdúrà mi. Lójú tèmi, Ọlọ́run ò mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa rárá.”—Marco ọmọ ilẹ̀ Ítálì.
“Ó wù mí gan-an kí n sin Ọlọ́run, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi. Mo rò pé ìkà kan tó kàn ń fojú wa gbolẹ̀ lásán ni. Mi ò gbà pé ó láàánú rárá.”—Rosa ọmọ ilẹ̀ Guatemala.
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo rò pé àṣìṣe wa nìkan ni Ọlọ́run máa ń wá, á sì máa ṣọ́ wa títí tá a máa fi ṣẹ̀ kó lè fìyà jẹ wá. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo Ọlọ́run bíi ẹni tó kàn ta kété sí wa. Lójú mi, ó jọ pé Ọlọ́run dà bí olórí ìjọba tó kàn ń ṣàkóso àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ rẹ̀, àmọ́ tí kò bìkítà rárá nípa wọn.”—Raymonde ọmọ ilẹ̀ Kánádà.
Kí ni èrò rẹ? Ṣé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni àwọn Kristẹni ti ń béèrè ìbéèrè yìí. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì kì í gbàdúrà sí Ọlọ́run Olódùmarè. Ìdí ni pé wọ́n kà á sí ẹni tó ń dẹ́rù bani tí kò ṣeé sún mọ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant tiẹ̀ sọ pé: “Báwo ni ẹlẹ́ṣẹ̀ lásánlàsàn ṣe lè gbójú gbóyà gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ń dẹ́rù bani tí ó sì jìnnà réré sí àwa èèyàn?”
Kí ló fà á tí àwọn kan fi ka Ọlọ́run sí “ẹni tó ń dẹ́rù bani tó sì jìnnà réré sí wa”? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Ọlọ́run? Tó o bá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, báwo ni ìyẹn ṣe lè mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
-
-
Wọ́n Parọ́ Pé Ọlọ́run Kò LórúkọIlé Ìṣọ́—2013 | November 1
-
-
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Wọ́n Parọ́ Pé Ọlọ́run Kò Lórúkọ
OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́
“Kò dájú pé àwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run ní orúkọ àti pé tó bá ní, a ò tíì mọ orúkọ yẹn.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n David Cunningham, nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn.
ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀
Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Lédè Hébérù, “Jèhófà” ni orúkọ Ọlọ́run, ó túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.”—Ẹ́kísódù 3:14.
Jèhófà fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Bíbélì sọ pé: “Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.”—Aísáyà 12:4.
Jésù lo orúkọ Ọlọ́run. Nígbà tó ń gbàdúrà, ó sọ fún Jèhófà pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn [àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù], ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.” Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run? Ó sọ pé: “Kí ìfẹ́ tí ìwọ [Ọlọ́run] fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Jòhánù 17:26.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Walter Lowrie sọ pé: “Ẹni tí kò bá mọ orúkọ Ọlọ́run kò tíì mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, kò sì lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó bá jẹ́ pé ńṣe ló kàn mọ̀ ọ́n lóréfèé.”
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Victor kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń ṣe é bíi pé kò mọ Ọlọ́run rárá. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wá mọ orúkọ Ọlọ́run, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú mi mọ̀ ọ́n. Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ ọ́n báyìí. Mo ti wá mọ irú Ẹni tó jẹ́ gan-an, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n di ọ̀rẹ́ rẹ̀.”
Bí wọ́n ṣe fi orúkọ mìíràn rọ́pò orúkọ Ọlọ́run dà bí ìgbà tí wọ́n gé orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì
Jèhófà máa ń sún mọ́ àwọn tó bá ń lo orúkọ rẹ̀. Ó ṣèlérí fún “àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀” pé: “Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.” (Málákì 3:16, 17) Ọlọ́run máa ń san èrè fún àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Róòmù 10:13.
-
-
Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú Ni Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2013 | November 1
-
-
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú ni Ọlọ́run
OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n pín ẹ̀sìn Kristẹni sí, ìyẹn ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn àti ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà pé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run. Wọ́n ní Ọlọ́run Baba, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́ ló wà. Nínú ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Kristẹni, wọ́n gbà pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kì í ṣe ọlọ́run ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ńṣe ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ọlọ́run kan ṣoṣo.”
ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀
Ọmọ ni Jésù jẹ́ sí Ọlọ́run, kò sì sọ ọ́ rí pé òun bá Bàbá òun dọ́gba tàbí pé àwọn méjèèjì jẹ́ ọ̀kan-náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí pé Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ó tún sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.”—Jòhánù 20:17.
Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe Ọlọ́run. Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni “kún fún ẹ̀mí mímọ́,” Jèhófà tiẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara.” (Ìṣe 2:1-4, 17) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe Ọlọ́run. Agbára Ọlọ́run ni.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ
Ọ̀gbẹ́ni Karl Rahner àti ọ̀gbẹ́ni Herbert Vorgrimler, tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì ṣàlàyé pé: “Láìsí ìṣípayá a ò lè mọ Mẹ́talọ́kan, kódà lẹ́yìn ìṣípayá a ò lè lóye rẹ̀ ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́.” Ǹjẹ́ o lè nífẹ̀ẹ́ ẹni tí kò ṣe é mọ̀ tàbí ẹni tó ṣòro lóye? Bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó dà bí ohun ìdènà tí kò lè jẹ́ kéèyàn mọ Ọlọ́run tàbí kéèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Marco, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Mo rò pé Ọlọ́run ń fara pamọ́ fún mi, ìyẹn ló túbọ̀ jẹ́ kó jìnnà sí mi, ó sì wá dà bí àdììtú àti ẹni tí mi ò lè sún mọ́ rárá.” Àmọ́, “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Kò fi ara rẹ̀ pamọ́ fún wa. Ó fẹ́ kí a mọ òun. Jésù sọ pé: “Àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀.”—Jòhánù 4:22.
Marco tún sọ pé: “Ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe Mẹ́talọ́kan ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Dípò ká máa wo Ọlọ́run bí àdììtú, á dáa ká máa wò ó bí Ẹnì tá a lè mọ̀, èyí á mú kó rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.
-
-
Wọ́n parọ́ pé Ìkà ni Ọlọ́runIlé Ìṣọ́—2013 | November 1
-
-
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Wọ́n Parọ́ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run
OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́
Ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tó ń jẹ́ Catechism of the Catholic Church sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkàn àwọn tó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì níbi tí wọ́n á ti máa jìyà nínú ‘iná ayérayé.’” Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan sọ pé gbogbo ẹni tó wà nínú ọ̀run àpáàdì kò lè sún mọ́ Ọlọ́run, wọ́n ti jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run.
ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀
“Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀-òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọkàn máa ń kú, tí ẹni tó kú kò sì mọ nǹkan kan, ṣé ó wá ṣeé ṣe kí ẹni yẹn tún máa joró nínú “iná ayérayé” tàbí kó jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run?
Nínú Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n sábà máa ń tú sí “ọ̀run àpáàdì” dúró fún ipò òkú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jóòbù ń ṣàìsàn tó le koko, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ìwọ ìbá fi mi pamọ́ ní ipò òkú.” (Jóòbù 14:13, Bíbélì Mímọ́) Ibi ìsinmi ni Jóòbù ń wá, kì í ṣe ibi tí yóò ti máa joró tàbí ibi tí á ti jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run, inú sàréè ló ń sọ.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ
Àwọn tó ń sọ pé ìkà ni Ọlọ́run kò fẹ́ kí á sún mọ́ ọn, ńṣe ni wọ́n fẹ́ ká jìnnà sí i. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rocío, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Láti ìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọwọ́ ni wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì kọ́ mi. Ẹ̀rù bà mí débi pé mi ò tiẹ̀ rò pé Ọlọ́run ní ìwà rere kankan. Mo rò pé ó máa ń bínú gan-an, kò sì ní àmúmọ́ra.”
Àlàyé tó ṣe kedere tí Bíbélì ṣe nípa ìdájọ́ Ọlọ́run àti ipò tí àwọn òkú wà yí èrò tí Rocío ní nípa Ọlọ́run pa dà. Ó sọ pé: “Ará tù mí, àfi bíi pé wọ́n sọ ẹrù tó wúwo kalẹ̀ lórí mi. Ní báyìí, mo ti wá gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ ohun tó dára fún wa, ó nífẹ̀ẹ́ wa, èmi náà sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo wá rí i pé Ọlọ́run dà bí bàbá tó bìkítà nípa àwọn ọmọ rẹ̀, tó sì fẹ́ ire fún wọn.”—Aísáyà 41:13.
Ọ̀pọ̀ ló ń sin Ọlọ́run torí pé wọ́n ń bẹ̀rù iná ọ̀run àpáàdì, àmọ́ Ọlọ́run kò fẹ́ ká sin òun nítorí pé à ń bẹ̀rù òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:29, 30) Yàtọ̀ síyẹn, tí a bá gbà pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúṣàájú, àá lè gbára lé ìdájọ́ tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Àwa náà á sì lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú bíi ti ọ̀rẹ́ Jóòbù náà, Élíhù tó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe burúkú, Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.”—Jóòbù 34:12.
-
-
Òtítọ́ Lè Dá Ẹ Sílẹ̀ LómìniraIlé Ìṣọ́—2013 | November 1
-
-
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN
Òtítọ́ Lè Dá Ẹ Sílẹ̀ Lómìnira
Lọ́jọ́ kan, Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà Bàbá rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ó sì ń tú àṣírí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn. (Jòhánù 8:12-30) Ohun tí Jésù sọ lọ́jọ́ náà kọ́ wa bí a ṣe lè ṣàyẹ̀wò ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run lónìí. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.
Gbólóhùn tí Jésù sọ pé: “Dúró nínú ọ̀rọ̀ mi” jẹ́ ká mọ ìlànà tá a lè fi wádìí bóyá àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn ń kọ́ni jẹ́ “òtítọ́.” Tó o bá gbọ́ nǹkan kan nípa Ọlọ́run, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ yìí bá ohun tí Jésù sọ àti ohun tó wà nínú Bíbélì mu?’ Ìwọ náà lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn kan tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n “fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí [àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́] rí.”—Ìṣe 17:11.
Ṣé o rántí Marco, Rosa àti Raymonde tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́? Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ kí àwọn náà fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Báwo wá ni ohun tí wọ́n kọ́ yìí ṣe rí lára wọn?
Marco sọ pé: “Ẹni tó ń kọ́ èmi àti ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè wa. Bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jinlẹ̀ nínú wa nìyẹn, àárín èmi àti ìyàwó mi sì túbọ̀ gún régé!”
Rosa sọ ní tiẹ̀ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwé ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó kàn ṣàlàyé ohun tí àwọn èèyàn rò nípa Ọlọ́run ni mo ka Bíbélì sí. Àmọ́, díẹ̀díẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi nínú Bíbélì. Ní báyìí, mo ti wá mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Mo ti rí i pé mo lè gbẹ́kẹ̀ lé e.”
Raymonde náà sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mo fẹ́ mọ̀ ọ́n. Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn tní èmi àti ọkọ mi fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà! Inú wa sì dùn láti mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́.”
Yàtọ̀ sí pé Bíbélì tú àṣírí àwọn irọ́ tí àwọn èèyàn pa mọ́ Ọlọ́run, ó tún jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa àwọn ìwà dáadáa tí Ọlọ́run ní. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì, ó sì jẹ́ ká “mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Á dáa kí ìwọ fúnra rẹ mọ ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa Ọlọ́run, bí àwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe àti ohun tó fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ka ìdáhùn nípa díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè yìí lórí ìkànnì Wo abẹ́ “Ẹ̀kọ́ Bíbélì > Ohun Tí Bíbélì Sọ.” O tiẹ̀ lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa tàbí kí o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó dá wa lójú pé tí o bá kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, wàá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ju bí o ṣe rò lọ.
-