-
1 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
1 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?
ÀDÚRÀ. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan wà táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí gan-an, wọ́n sì máa ń fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìbéèrè méje táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà, kó o sì máa fọkàn bá wa nìṣó bá a ṣe ń wá ìdáhùn sí wọn látinú Bíbélì. A kọ àwọn àpilẹ̀kọ yìí kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè gbàdúrà tàbí bí àdúrà rẹ ṣe lè sunwọ̀n sí i.
KÒ SÍ inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìsìn tí àwọn èèyàn kì í ti í gbàdúrà. Àwọn èèyàn máa ń dá gbàdúrà wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Wọ́n máa ń gbàdúrà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, tẹ́ńpìlì, sínágọ́gù, mọ́ṣáláṣí àti ní ojúbọ. Wọ́n lè tẹ́ ohun kan sílẹ̀ láti máa gbàdúrà lórí rẹ̀, wọ́n lè lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, àgbá àdúrà, ère, ìwé àdúrà tàbí ohun kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí tí wọ́n gbé kọ́.
Àdúrà táwa èèyàn máa ń gbà ló mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹ̀dá yòókù lórí ilẹ̀ ayé. Òótọ́ ni pé, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín àwa àtàwọn ẹranko. Àwa èèyàn nílò oúnjẹ, afẹ́fẹ́ àti omi bíi tàwọn ẹranko. Bákan náà, wọ́n bí wa, a wà láàyè, a sì ń kú bíi tiwọn. (Oníwàásù 3:19) Àmọ́ àwa ẹ̀dá èèyàn nìkan la máa ń gbàdúrà. Kí nìdí?
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí pé a ní láti gbàdúrà. Ó ṣe tán gbogbo èèyàn ló gbà pé àdúrà jẹ́ ọ̀nà tá a máa ń gbà bá ẹni mímọ́ àti ẹni tó ti wà láti ayérayé sọ̀rọ̀. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé, Ọlọ́run ti dá èèyàn pẹ̀lú ìfẹ́ láti gbàdúrà. (Oníwàásù 3:11) Jésù sọ nígbà kan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
Èèyàn lè sọ pé, nítorí ‘àìní nípa ti ẹ̀mí’ yìí làwọn ẹlẹ́sìn fi kọ́ àwọn ilé ìsìn ńláńlá tí wọ́n sì ṣe ọ̀ṣọ́ sí wọn, èyí ló tún mú kí wọ́n máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí gbàdúrà. Èrò àwọn kan ni pé àwọn fúnra àwọn tàbí àwọn míì ló máa bójú tó àìní àwọn nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé agbára èèyàn kò gbé e láti ranni lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn yìí? Aláìlera làwa èèyàn, a kì í pẹ́ láyé, a kò sì mọ ọ̀la. Ẹnì kan tó lọ́gbọ́n jù wá lọ, tó lágbára jù wá lọ, ẹni tó ti wà láti ayérayé ló lè fún wa lóun tá a nílò. Kí sì làwọn nǹkan tẹ̀mí tá a nílò, tó ń mú ká máa gbàdúrà?
Gbé èyí yẹ̀ wò: Ǹjẹ́ ìgbà kankan wà tó o nílò ìtọ́sọ́nà, ọgbọ́n tàbí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ju òye ẹ̀dá èèyàn lọ? Ǹjẹ́ ìgbà kan wà rí tó o nílò ìtùnú nítorí àdánù kan, tó o nílò ìtọ́sọ́nà nígbà tó o fẹ́ ṣe ìpinnu kan tó lágbára tàbí tó o nílò ìdáríjì nígbà tí ìbànújẹ́ bá ẹ nítorí àṣìṣe rẹ?
Bíbélì sọ pé ìwọ̀nyí jẹ́ ìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà. Bíbélì ni ìwé tó ṣeé gbára lé jù lọ tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, àkọsílẹ̀ àdúrà àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin sì wà nínú rẹ̀. Wọ́n gbàdúrà fún ìtùnú, ìtọ́sọ́nà, ìdáríjì àti ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó le gan-an.—Sáàmù 23:3; 71:21; Dáníẹ́lì 9:4, 5, 19; Hábákúkù 1:3.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdúrà yìí yàtọ̀, wọ́n fi nǹkan kan jọra. Àwọn tó gbàdúrà ń ṣe ohun tó yẹ kéèyàn ṣe kí àdúrà ẹni lè ní ìtẹ́wọ́gbà, èyí táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé tàbí kà sí lóde òní. Wọ́n mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n gbàdúrà sí.
-
-
2 Ta Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Sí?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
2 Ta Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Sí?
ǸJẸ́ ibì kan náà ni gbogbo àdúrà ń lọ láìka ẹni tí wọ́n darí àdúrà náà sí? Nínú ayé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sábà máa ń rò bẹ́ẹ̀. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i pé kí oríṣiríṣi ẹ̀sìn máa jọ́sìn pa pọ̀ fara mọ́ èrò yìí, wọ́n gbà pé gbogbo ẹ̀sìn ló ní ìtẹ́wọ́gbà láìka bí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra wọn sí. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í darí àdúrà wọn sí ibi tó tọ́. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa gbàdúrà sí àwọn ère. Léraléra ni Ọlọ́run dẹ́bi fún àṣà yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Sáàmù 115:4-6 sọ nípa àwọn òrìṣà pé: “Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ran.” Kókó náà ṣe kedere. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbọ́ ohun tó ò ń sọ.
Ìtàn kan nínú Bíbélì sọ ohun tó pọ̀ lórí kókó yìí. Èlíjà tó jẹ́ wòlíì tòótọ́ pe àwọn wòlíì Báálì níjà, ó ní kí wọ́n gbàdúrà sí ọlọ́run wọn, òun náà á sì gbàdúrà sí Ọlọ́run tòun. Èlíjà sọ pé Ọlọ́run tòótọ́ á dáhùn àdúrà, àmọ́ ọlọ́run èké kò ní dáhùn. Àwọn wòlíì Báálì gbà láti gbàdúrà, wọ́n fi taratara gbàdúrà fún àkókò gígùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń lọgun tòò, àmọ́ òfo ló já sí! Ìtàn náà sọ pé: “Kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn, kò sì sí fífetísílẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:29) Àmọ́, kí ni àbájáde àdúrà Èlíjà?
Lẹ́yìn tí Èlíjà gbàdúrà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ̀ dáhùn, ó jẹ́ kí iná bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó ẹbọ tí Èlíjà gbé kalẹ̀. Kí ni ìyàtọ̀ láàárín àdúrà méjèèjì? Àdúrà Èlíjà tó wà nínú 1 Àwọn Ọba 18:36, 37 jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan. Àdúrà yẹn kúrú gan-an torí pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀rọ̀ péré ni lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúrà yìí kúrú, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíjà dárúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà.
Báálì tó túmọ̀ sí “oní-nǹkan” tàbí “ọ̀gá,” ni ọlọ́run àwọn ọmọ Kénáánì, òrìṣà yìí sì wà lóríṣiríṣi lágbègbè náà. Àmọ́, Ẹnì kan ṣoṣo láyé àti lọ́run ló ń jẹ́ orúkọ àrà ọ̀tọ̀ náà, Jèhófà. Ọlọ́run yìí sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.”—Aísáyà 42:8.
Kí nìdí tí àdúrà Èlíjà fi ní ìtẹ́wọ́gbà nígbà tí tàwọn wòlíì Báálì kò ní ìtẹ́wọ́gbà? Ìbálòpọ̀ bíi tàwọn aṣẹ́wó tó máa ń wáyé nígbà ààtò ìjọsìn Báálì máa ń tàbùkù èèyàn, àní wọ́n tiẹ̀ máa ń fi àwọn èèyàn rúbọ pàápàá. Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Jèhófà yàtọ̀, ó kọ́ wọn pé kí wọ́n yàgò fún àwọn àṣà ìjọsìn tó ń tàbùkù ẹni. Nítorí náà, rò ó wò náà, ká sọ pé o kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o bọ̀wọ̀ fún gan-an, ǹjẹ́ wàá fẹ́ kí wọ́n mú lẹ́tà náà fún ẹlòmíì tí èrò rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀rẹ́ rẹ? Ó dájú pé o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!
Tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ Bàbá gbogbo ẹ̀dá lò ń gbàdúrà sí yẹn.a Wòlíì Aísáyà sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà, ni Baba wa.” (Aísáyà 63:16) Ẹni yìí gan-an ni Jésù Kristi ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” (Jòhánù 20:17) Jèhófà ni Bàbá Jésù. Ọlọ́run yìí ni Jésù gbàdúrà sí, òun náà ló sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí.—Mátíù 6:9.
Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé ká máa gbàdúrà sí Jésù, Màríà, àwọn ẹni mímọ́ tàbí àwọn áńgẹ́lì? Rárá, Jèhófà nìkan ló ní ká máa gbàdúrà sí. Wo ẹ̀rí méjì tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, àdúrà jẹ́ ara ìjọsìn wa, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn. (Ẹ́kísódù 20:5) Èkejì ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òun ló ń jẹ́ orúkọ oyè náà, “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gbé ohun tó pọ̀ fún àwọn ẹlòmíì láti bójú tó, kò gbé èyí fún ẹnikẹ́ni nígbà kankan. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí pé òun á máa gbọ́ àdúrà wa.
Nítorí náà, fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí sọ́kàn tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Ìṣe 2:21) Àmọ́, ṣé gbogbo àdúrà ni Jèhófà ń gbọ́ láì retí pé ká ṣe nǹkan kan? Àbí ohun kan wà tó yẹ ká mọ̀ tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kan sọ pé kò yẹ kéèyàn máa pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, àní nínú àdúrà pàápàá. Àmọ́, orúkọ náà fara hàn ní ohun tó lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ nínú àdúrà tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà gbà àti nínú àwọn sáàmù tí wọ́n kọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìpèníjà tí Èlíjà gbé síwájú àwọn wòlíì Báálì fi hàn pé kì í ṣe ibì kan náà ni gbogbo àdúrà ń lọ
-
-
3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?
Ọ̀PỌ̀ ẹ̀sìn ló máa ń rin kinkin mọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn wà téèyàn bá fẹ́ gbàdúrà, ọ̀rọ̀ tó yẹ kéèyàn lò àtàwọn ààtò tó yẹ ní ṣíṣe. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì, ó sì ràn wá lọ́wọ́ lórí kókó tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, ìyẹn ìbéèrè náà pé, “Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?”
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ibi táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti gbàdúrà àti bí wọ́n ṣe wà nígbà tí wọ́n fẹ́ gbàdúrà. Wọ́n máa ń gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tàbí kí wọ́n gbàdúrà sókè, ìyẹn sì sinmi lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n máa ń gbójú sókè tàbí tẹrí ba nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbàdúrà. Kàkà kí wọ́n máa lo ère, ìlẹ̀kẹ̀ tàbí ìwé àdúrà, ńṣe ni wọ́n máa ń gbàdúrà látọkàn wá, tí wọ́n á sì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Kí ló mú kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn?
Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Ọlọ́run kan ṣoṣo tó ń jẹ́ Jèhófà ni wọ́n máa ń gbàdúrà sí. Nǹkan míì wà tó tún ṣe pàtàkì. Ìwé 1 Jòhánù 5:14 sọ pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” Àdúrà wa ní láti bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?
Ká tó lè gbàdúrà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, a ní láti mọ ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́. Nítorí náà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe kókó nínú ọ̀ràn àdúrà gbígbà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó dìgbà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa? Rárá, àmọ́ Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ òun jẹ́, ká sapá láti lóye rẹ̀, ká sì fi ohun tá a bá kọ́ sílò. (Mátíù 7:21-23) A ní láti gbàdúrà tó bá ohun tá a kọ́ mu.
Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, èyí sì jẹ́ ohun míì tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn àdúrà. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ni ẹ óò rí gbà.” (Mátíù 21:22) Kéèyàn ní ìgbàgbọ́ kò túmọ̀ sí pé òpònú lèèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí kéèyàn gba ohun kan gbọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kò rí nǹkan náà sójú, àmọ́ táwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fi hàn pé nǹkan náà wà. (Hébérù 11:1) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà tí a kò lè rí jẹ́ ẹni gidi, pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ṣe tán láti dáhùn àdúrà àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Síwájú sí i, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i, ó sì ṣe tán láti fún wa lóhun tá a nílò.—Lúùkù 17:5; Jákọ́bù 1:17.
Ohun míì tún wà tó ṣe pàtàkì tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Nítorí náà, ipasẹ̀ Jésù la lè gbà dé ọ̀dọ̀ Bàbá, ìyẹn Jèhófà. Àmọ́ Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà lórúkọ òun. (Jòhánù 14:13; 15:16) Ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé Jésù la ó máa gbàdúrà sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù, má gbàgbé pé Jésù ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa tá a fi lè bá Bàbá wa pípé tó sì jẹ́ ẹni mímọ́ jù lọ sọ̀rọ̀.
Àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n sún mọ́ Jésù jù lọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà kan pé: “Kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Ó dájú pé kì í ṣe irú àwọn nǹkan tá a ti ń sọ bọ̀ yìí ni wọ́n béèrè nípa rẹ̀. Ohun tí wọ́n fẹ́ mọ̀ ní ti gidi ni, ‘Kí la lè gbàdúrà nípa rẹ̀?’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Àdúrà tó ní ìtẹ́wọ́gbà máa ń jẹ́ èyí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, téèyàn fi ìgbàgbọ́ gbà, tó sì jẹ́ lórúkọ Jésù
-
-
4 Kí La Lè Gbàdúrà Nípa Rẹ̀?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
4 Kí La Lè Gbàdúrà Nípa Rẹ̀?
ÀDÚRÀ Olúwa ni àdúrà tí wọ́n sọ pé àwọn Kristẹni máa ń gbà jù. Bóyá òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tàbí irọ́, ohun kan tó dájú ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn kò lóye àdúrà àwòkọ́ṣe náà tí Jésù kọ́ni, èyí tá a tún máa ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti sọ àdúrà yìí di àkọ́sórí tí wọ́n sì máa ń kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́ láì tiẹ̀ ronú lórí ìtúmọ̀ rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tí Jésù ní lọ́kàn nípa rẹ̀ nìyẹn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
Ṣáájú kí Jésù tó gba àdúrà náà, ó ní: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) Ṣé kì í ṣe pé Jésù ń ta ko ara rẹ̀ nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ téèyàn lè há sórí kéèyàn sì máa sọ lásọtúnsọ? Rárá! Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá a lè gbàdúrà nípa rẹ̀ àtàwọn ohun pàtàkì-pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà ni Jésù kọ́ni. Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ohun tó sọ yẹ̀ wò. Àdúrà náà wà nínú ìwé Mátíù 6:9-13.
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”
Jésù fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé, Bàbá, ìyẹn Jèhófà la gbọ́dọ̀ darí gbogbo àdúrà sí. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ ìdí tí orúkọ Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an àti ìdí tó fi yẹ ní yíyà sí mímọ́ tàbí sísọ di mímọ́?
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n ti fi irọ́ ba orúkọ mímọ́ Ọlọ́run jẹ́. Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run sọ pé, Jèhófà jẹ́ òpùrọ́ àti Alákòóso onímọtara-ẹni-nìkan, pé kò sì ní ẹ̀tọ́ láti darí àwọn ohun tó dá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ọ̀pọ̀ ló fara mọ́ èrò Sátánì, wọ́n sì ń kọ́ni pé, Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́, pé ìkà ni àti pé kò lẹ́mìí ìdáríjì, wọ́n tiẹ̀ sọ pé òun kọ́ ni Ẹlẹ́dàá. Àwọn kan ní tiwọn gbéjà ko orúkọ rẹ̀, wọ́n yọ orúkọ náà Jèhófà kúrò nínú ìtumọ̀ àwọn Bíbélì, wọ́n sì sọ pé kò yẹ láti máa lò ó.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ẹ̀gàn yìí kúrò. (Ìsíkíẹ́lì 39:7) Nípa báyìí, ó máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò, á sì mú ìṣòro wa kúrò. Lọ́nà wo? Ọ̀rọ̀ tó kàn nínú àdúrà Jésù dáhùn ìbéèrè yẹn.
“Kí ìjọba rẹ dé.”
Lóde òní, èdèkòyédè tí kì í ṣe kékeré ló wà láàárín àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́ àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé, ó ti pẹ́ táwọn wòlíì Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà náà, ìyẹn Olùgbàlà tí Ọlọ́run yàn máa ṣàkóso Ìjọba kan tó máa ṣàtúnṣe ayé. (Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yìí máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nípa títú àṣírí irọ́ Sátánì, á fòpin sí ìṣàkóso Sátánì àti iṣẹ́ rẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ogun, àìsàn, ìyàn, kódà ikú kò ní sí mọ́. (Sáàmù 46:9; 72:12-16; Aísáyà 25:8; 33:24) Tó o bá ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ńṣe lò ń gbàdúrà pé kí gbogbo ìlérí yẹn ṣẹ.
“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ láyé bí wọ́n ṣe ṣẹ ní ọ̀run níbi tí Ọlọ́run ń gbé. Kò sí ẹni tó lè dá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dúró ní ọ̀run, níbẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run bá Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ jagun, ó fi wọ́n sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:9-12) Bíi tí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ méjì tó ṣáájú nínú àdúrà àwòkọ́ṣe, ìkẹta yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ kì í ṣe ìfẹ́ tara wa. Gbogbo ìgbà ni ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń mú ohun tó dára jù lọ wá fún gbogbo ìṣẹ̀dá. Àní Jésù tó jẹ́ ẹni pípé pàápàá sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”—Lúùkù 22:42.
“Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.”
Jésù tún fi hàn pé a lè gbàdúrà nípa ohun tá a nílò. Kò sí ohun tó burú tá a bá béèrè fún ohun tá a nílò lóòjọ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kódà, ìyẹn ń rán wa létí pé Jèhófà ló ń “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òbí onífẹ̀ẹ́ ni, ó sì ṣe tán láti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ohun tí wọ́n nílò. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí òbí rere, kò ní fún wọn ní nǹkan èyíkéyìí tó lè ṣe ìpalára fún wọn.
“Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.”
Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé a jẹ Ọlọ́run ní gbèsè? Ǹjẹ́ a nílò pé kó dárí jì wá? Ọ̀pọ̀ lónìí ni kò mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, wọn ò sì kà á sí nǹkan kan. Àmọ́ Bíbélì kọ́ wa pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa gbogbo ìdààmú tó ń bá wa lónìí, òun ló ń fa ikú ẹ̀dá èèyàn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, á máa ń dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ìdáríjì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ló sì lè mú ká ní ìyè ayérayé. (Róòmù 3:23; 5:12; 6:23) Ó fọkàn ẹni balẹ̀ láti mọ̀ pé Bíbélì sọ pé: ‘Jèhófà ṣe tán láti dárí jini.’—Sáàmù 86:5.
“Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”
Ǹjẹ́ o kò rí i pé o nílò ààbò Ọlọ́run lójú méjèèjì! Ọ̀pọ̀ ni kò gbà pé Sátánì tó jẹ́ “ẹni burúkú náà” wà. Àmọ́ Jésù kọ́ni pé Sátánì wà, ó tiẹ̀ pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 16:11) Sátánì ti ba èrò àwọn èèyàn tó wà nínú ayé tó ń ṣàkóso lé lórí jẹ́, ó sì ń sapá láti ba èrò ìwọ náà jẹ́, kò fẹ́ kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, Bàbá rẹ. (1 Pétérù 5:8) Àmọ́, Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ fíìfíì, ó sì ṣe tán láti dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.
Kò túmọ̀ sí pé àwọn kókó tó wà nínú àdúrà àwòkọ́ṣe Jésù tá a ṣe àkópọ̀ rẹ̀ yìí nìkan lèèyàn lè gbàdúrà nípa rẹ̀. Rántí pé, 1 Jòhánù 5:14 sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” Nítorí náà, má ṣe rò pé ohun tó ń dà ẹ́ láàmú ti kéré jù láti sọ fún Ọlọ́run.—1 Pétérù 5:7.
Àmọ́, ọ̀rọ̀ nípa àkókò àti ibi tá a ti máa gbàdúrà ńkọ́? Ǹjẹ́ ó pọn dandan pé ká ní àkókò kan àti ibì kan pàtó tá a ti máa gbàdúrà?
-
-
5 Ibo La Ti Máa Gbàdúrà, Ìgbà Wo La sì Máa Gbà Á?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
5 Ibo La Ti Máa Gbàdúrà, Ìgbà Wo La sì Máa Gbà Á?
KÒ SÍ iyèméjì pé wàá ti rí i tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ilé ràgàjì kan jẹ́ ilé àdúrà, tí wọ́n sì máa ń sọ pé àkókò kan wà tó yẹ kéèyàn máa gbàdúrà lójúmọ́. Ǹjẹ́ Bíbélì sọ ibi pàtó kan tá a ti máa gbàdúrà àti ìgbà tá a máa gbàdúrà?
Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé àwọn àkókò kan wà tó yẹ kéèyàn gbàdúrà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹun, Jésù gbàdúrà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 22:17) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì péjọ fún ìjọsìn, wọ́n gbàdúrà. Ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣe yìí kì í ṣe tuntun, torí pé ó ti pẹ́ tí àwọn Júù ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí tẹ́ńpìlì jẹ́ “Ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Máàkù 11:17.
Nígbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá kóra jọ tí wọ́n sì gbàdúrà sí i, àdúrà wọn máa ń gbà. Bí èrò àwùjọ náà bá ṣọ̀kan, tí àdúrà tí wọ́n gbà bá sì bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, inú Ọlọ́run máa dùn sí i. Àdúrà bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè mú kí Ọlọ́run ṣe ohun tí kò fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀. (Hébérù 13:18, 19) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbàdúrà déédéé ní àwọn ìpàdé wọn. A rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ, kó o sì wá gbọ́ àwọn àdúrà náà.
Àmọ́ Bíbélì kò sọ pé àkókò kan pàtó tàbí ibì kan pàtó lèèyàn ti lè gbàdúrà. Nínú Bíbélì, a rí ìtàn nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n gbàdúrà ní oríṣiríṣi àkókò àti ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Jésù sọ pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.”—Mátíù 6:6.
Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn láti gbọ́ èyí? O lè bá Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, ní ìwọ nìkan, tó sì dájú pé á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Abájọ tí Jésù fi sábà máa ń fẹ́ dá wà kó bàa lè gbàdúrà! Lákòókò kan, ó lo gbogbo òru nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó ń béèrè ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fẹ́ ṣe.—Lúùkù 6:12, 13.
Àwọn ọkùnrin àti obìnrin míì nínú Bíbélì gbàdúrà nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìpinnu tó lágbára tàbí iṣẹ́ kan tó kà wọ́n láyà. Láwọn ìgbà míì, wọ́n gbàdúrà sókè, ìgbà míì sì rèé, ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa ń dá gbàdúrà, wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Kókó ibẹ̀ ni pé wọ́n máa ń gbàdúrà. Ọlọ́run tiẹ̀ ké sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Ọlọ́run ṣe tán láti máa gbọ́ àdúrà àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Èyí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.
Òótọ́ ni pé, nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ ń ṣe kàyéfì pé àdúrà kò wúlò. Ìwọ náà lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ àdúrà lè ràn mí lọ́wọ́?’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
A lè gbàdúrà nígbàkigbà àti níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
-
-
6 Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
6 Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?
ǸJẸ́ àdúrà lè ṣe wá láǹfààní kankan? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àdúrà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè ṣe wọ́n láǹfààní. (Lúùkù 22:40; Jákọ́bù 5:13) Kódà, àdúrà lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá dọ̀rọ̀ àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìmọ̀lára wa, títí kan ìlera wa pàápàá. Lọ́nà wo?
Ká ní ọmọ rẹ kan rí ẹ̀bùn kan gbà. Ṣé wàá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kọ́ ọ pé ó yẹ kó fi hàn pé òun mọyì nǹkan náà? Àbí wàá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ọ pé ó yẹ kó dúpẹ́? Tá a bá mọ inú rò, a ó lè mọ ohun tó tọ́, a ó sì máa ṣe wọ́n. Ǹjẹ́ òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tó bá kan bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ kan.
Àdúrà ọpẹ́. Tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá wa fún àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, ńṣe là ń sọ̀rọ̀ nípa ìbùkún rẹ̀ lórí wa. Èyí lè jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ẹni tó mọrírì, tó láyọ̀, ẹni tó túbọ̀ ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́.—Fílípì 4:6.
Àpẹẹrẹ: Jésù dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá rẹ̀ fún bó ṣe máa ń fetí sí àdúrà rẹ̀ tó sì máa ń dáhùn rẹ̀.—Jòhánù 11:41.
Àdúrà fún ìdáríjì. Tá a bá tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, èyí á mú kí ẹ̀rí ọkàn wa lágbára, a fi hàn pé a ti ronú pìwà dà, á sì fi hàn pé a mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe burú tó. Ara á tún tù wá lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
Àpẹẹrẹ: Dáfídì gbàdúrà láti sọ nípa ìrònúpìwàdà àti ìbànújẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 51.
Àdúrà fún ìtọ́sọ́nà àti ọgbọ́n. Bíbẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ìtọ́sọ́nà tàbí ọgbọ́n tá a nílò láti ṣe ìpinnu tó dára máa jẹ́ ká rẹ ara wa sílẹ̀ pátápátá. Èyí lè jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ibi tí agbára wa mọ, á sì jẹ́ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá wa ọ̀run.—Òwe 3:5, 6.
Àpẹẹrẹ: Sólómọ́nì fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè fún ìtọ́sọ́nà àti ọgbọ́n tó fẹ́ fi ṣàkóso Ísírẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 3:5-12.
Àdúrà nígbà wàhálà. Tá a bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú, ọkàn wa á balẹ̀, a ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò ara wa.—Sáàmù 62:8.
Àpẹẹrẹ: Ásà Ọba gbàdúrà nígbà táwọn ọ̀tá gbéjà kò ó.—2 Kíróníkà 14:11.
Gbígbàdúrà fún ire àwọn ẹlòmíì. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká borí ìmọtara-ẹni-nìkan, a ó sì wá dẹni tó ń káàánú àwọn ẹlòmíì tó sì ń fọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara wa wò.
Àpẹẹrẹ: Jésù gbàdúrà nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Jòhánù 17:9-17.
Àdúrà ìyìn. Tá a bá yin Jèhófà fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì wa fún un á máa pọ̀ sí i. Irú àdúrà yìí tún lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá wa.
Àpẹẹrẹ: Dáfídì yin Ọlọ́run látọkàn wá nítorí àwọn ohun tó dá. —Sáàmù 8.
Ìbùkún míì tó tún ní í ṣe pẹ̀lú àdúrà ni “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:7) Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ayé oníwàhálà yìí. Ó tiẹ̀ ńṣe ara ẹni lóore pàápàá. (Òwe 14:30) Àmọ́, ṣé ìsapá wa ló ń jẹ́ ká ní in? Àbí ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
Àdúrà lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an tó bá dọ̀rọ̀ ìlera, ìmọ̀lára àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run
-
-
7 Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa?Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
7 Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa?
Ó MÁA ń wu àwọn èèyàn gan-an láti mọ̀ nípa ìbéèrè tó wà lókè yìí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń fetí sí àdúrà lóde òní. Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló kù sí bóyá ó máa fetí sí àdúrà wa tàbí kò ní fetí sí i.
Jésù bá àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ wí nítorí pé wọ́n máa ń gbàdúrà àgàbàgebè, wọ́n ń ṣe àṣehàn pé àwọn jẹ́ olùfọkànsìn. Ó sọ pé, àwọn ọkùnrin yìí “ń gba èrè wọn ní kíkún,” èyí tó túmọ̀ sí pé, wọ́n á gbayì lójú àwọn èèyàn, ìyẹn sì ni ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jù, àmọ́ wọ́n pàdánù ohun tí wọ́n nílò, ìyẹn pé kí Ọlọ́run fetí sí wọn. (Mátíù 6:5) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ló ń gbàdúrà lọ́nà tó bá ìfẹ́ tara wọn mu, àmọ́ tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Wọ́n ń kọ etí dídi sí àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Ọlọ́run kì í sì í fetí sí àdúrà wọn.
Ìwọ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run á fetí sí àdúrà rẹ, tí á sì dáhùn rẹ̀? Kì í ṣe ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tàbí ipò rẹ láwùjọ ló máa pinnu bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà rẹ. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ǹjẹ́ irú ẹni tó o jẹ́ nìyẹn? Tó o bá bẹ̀rù Ọlọ́run, wàá kà á sí gan-an, o kò sì ní ṣe ohun tó máa dùn ún. Tó o bá ń ṣiṣẹ́ òdodo, wàá máa sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ dípò tí wàá fi máa ṣe ìfẹ́ ara rẹ tàbí tàwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o fẹ́ kí Ọlọ́run fetí sí àdúrà rẹ? Bíbélì sọ bá a ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tí Ọlọ́run á fi gbọ́.a
Òótọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ máa ń fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn lọ́nà ìyanu. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá, Ọlọ́run kì í sábà ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, àkọsílẹ̀ Bíbélì máa ń fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún máa ń kọjá lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìyanu kan bá ti ṣẹlẹ̀ kí òmíràn tó wáyé. Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu dópin lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti kú tán. (1 Kọ́ríńtì 13:8-10) Àmọ́, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà lóde òní? Rárá! Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àdúrà kan tó dáhùn.
Ọlọ́run ń fúnni ní Ọgbọ́n. Jèhófà ni Orísun ọgbọ́n gidi. Ó ṣe tán láti fi ọgbọ́n fún àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti máa fi gbé ìgbé ayé wọn.—Jákọ́bù 1:5.
Ọlọ́run ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn àǹfààní rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Kò sí nǹkan míì tó lágbára tó o. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò. Ó lè jẹ́ ká ní àlàáfíà ọkàn nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú. Ó tún lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó dára tó sì máa wà pẹ́. (Gálátíà 5:22, 23) Jésù fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run máa ń fúnni ní ẹ̀bùn yìí ní fàlàlà.—Lúùkù 11:13.
Ọlọ́run ń fún àwọn tó ń sapá láti mọ̀ ọ́n ní ìmọ̀. (Ìṣe 17:26, 27) Kárí ayé, àwọn èèyàn wà tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fẹ́ láti mọ òtítọ́. Wọ́n fẹ́ láti mọ̀ nípa Ọlọ́run, ìyẹn orúkọ rẹ̀, ohun tó fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé àti aráyé àti bí wọ́n ṣe lè sún mọ́ ọn. (Jákọ́bù 4:8) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé, inú wọn sì máa ń dùn láti fi Bíbélì dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
Ṣé ohun tó mú kó o gba ìwé ìròyìn yìí nìyẹn? Ṣé o fẹ́ láti mọ Ọlọ́run? Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà rẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
-