ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Àwọn Tó Ń Pe Ara Wọn Ní Kristẹni Ni Kristẹni Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • Ǹjẹ́ Gbogbo Àwọn Tó Ń Pe Ara Wọn Ní Kristẹni Ni Kristẹni Tòótọ́?

      KRISTẸNI mélòó ló wà láyé? Ìwé Atlas of Global Christianity jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́dún 2010, iye Kristẹni tó wà láyé dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún àti ààbọ̀. Àmọ́ ìwé yìí sọ pé àwọn Kristẹni yẹn pín sí oríṣiríṣi ẹ̀ka ìsìn tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì [41,000] lọ, àti pé olúkúlùkù wọn ló ní ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìlànà ìwà híhù tirẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé táwọn èèyàn bá wo bí àwọn ẹ̀sìn tí à ń pè ní Kristẹni ṣe pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ó máa ń tojú sú wọn tàbí kó tiẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì báwọn. Wọ́n lè wá máa bi ara wọn pé, ‘Ṣé gbogbo àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni náà ni Kristẹni tòótọ́?’

      Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yìí. Arìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn sábà máa ń jẹ́ kí àwọn aṣọ́bodè mọ ọmọ orílẹ̀-èdè tóun jẹ́ kó tó lè kọjá. Ó sì ní láti fi ìwé àṣẹ ìrìnnà rẹ̀ hàn wọ́n láti fi jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, tí ẹnì kan bá kàn sọ pé òun gba Kristi gbọ́, ìyẹn nìkan kò tó láti fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni. Ó gbọ́dọ̀ tún ní ẹ̀rí tó máa fi hàn pé òótọ́ ló ń sọ. Kí wá ni ẹ̀rí náà?

      Ẹ̀yìn ọdún 44 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “Kristẹni.” Lúùkù tó jẹ́ òpìtàn kan nínú Bíbélì sọ pé: “Áńtíókù . . . ni a ti kọ́kọ́ tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.” (Ìṣe 11:26) Ṣàkíyèsí pé àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin Kristi ni wọ́n pè ní Kristẹni. Kí ló máa fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Tuntun, ìyẹn The New International Dictionary of New Testament Theology, sọ pé: “Ẹni tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ fi gbogbo ayé [rẹ̀] fún un pátápátá láìkù síbì kankan . . . jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.” Nítorí náà, ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ yóò máa tẹ̀ lé gbogbo ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni Jésù Olùdásílẹ̀ ìsìn Kristẹni, láì jẹ́ kó ṣẹ́ kù síbì kankan.

      Lónìí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí á rí àwọn èèyàn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lára àwọn tí à ń pè ní Kristẹni? Kí ni Jésù sọ pé a máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ mọ̀? Jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó ṣàyẹ̀wò nǹkan márùn-ún tí Jésù sọ, tí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa ṣe, èyí tá a fi máa dá wọn mọ̀ yàtọ̀. A ó sì wo ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń ṣe nǹkan wọ̀nyẹn. A tún máa wo àwọn tó ń ṣe bíi tiwọn lára àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn lónìí.

  • “Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • “Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”

      “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:31, 32.

      Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Ọ̀rọ̀ tí Jésù ń sọ pé kí wọ́n dúró nínú rẹ̀ ni àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòhánù 12:49) Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Jésù máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni lẹ́yìn nígbà gbogbo. (Jòhánù 17:17; Mátíù 4:4, 7, 10) Torí náà, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ máa ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,’ ìyẹn ni pé wọ́n á gbà pé ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá sọ ló jẹ́ “òtítọ́,” ohun tó wà nínú Bíbélì sì ni wọ́n máa ń gbé ìgbàgbọ́ wọn àti gbogbo ìṣe wọn kà.

      Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Bí Jésù ṣe bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bọ̀wọ̀ fún un. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá yàn pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn Kristẹni lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ “rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dájú tó sì ṣeé gbíyè lé.” (Títù 1:7, 9, Bíbélì The Amplified Bible) Bíbélì tún gba àwọn Kristẹni ìjímìjí níyànjú pé kí wọ́n má ṣe gba “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.

      Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Àkójọ òfin tí àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ṣe, ìyẹn Dogmatic Constitution on Divine Revelation, èyí tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ní ọdún 1965 tí wọ́n sì gbé jáde nínú ìwé katikísìmù ti ìjọ Kátólíìkì, sọ pé: “Kì í ṣe inú Ìwé Mímọ́ nìkan ṣoṣo ni Ṣọ́ọ̀ṣì [Kátólíìkì] ti ń rí ìdánilójú rẹ̀ nípa ohun gbogbo tí a ti fi hàn. Nítorí náà, gbogbo àṣà mímọ́ àti Ìwé Mímọ́ ni a ní láti tẹ́wọ́ gbà kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn pẹ̀lú ẹ̀mí ìjọsìn àti ìtẹríba kan náà.” (Catechism of the Catholic Church) Ìwé ìròyìn Maclean’s sọ pé obìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ìsìn ní ìlú Toronto ní orílẹ̀-èdè Kánádà béèrè pé: “Kí ló dé tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ ajàjàgbara ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn la tún ṣì ń tẹ̀ lé lónìí? Ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa gan-an làwa náà máa ń fẹ́ fi ọgbọ́n orí tiwa gbé kalẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tó máa ń bà á jẹ́ ni pé a ṣáà máa ń fẹ́ kó bá ọ̀rọ̀ Jésù àti Ìwé Mímọ́ mu.”

      Ohun tí Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé: “Wọ́n ka Bíbélì sí orísun kan ṣoṣo tí wọ́n ní fún ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìwà híhù wọn.” Láìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà dá ọ̀rọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu bí wọ́n ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, ó ní: “Mo kúkú mọ̀ yín dáadáa.” Ó wá nawọ́ sí Bíbélì ọwọ́ arábìnrin náà, ó ní, “ohun tí mo fi máa ń dá yín mọ̀ rèé,” ìyẹn ni pé wọ́n lo Bíbélì láti fi bá a sọ̀rọ̀.

  • “Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • “Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

      “Ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé.”—JÒHÁNÙ 17:14.

      Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Torí pé Jésù kì í ṣe apá kan ayé, kò dá sí gbogbo rògbòdìyàn tó ń lọ láwùjọ nígbà ayé rẹ̀, kò sì dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ó sọ pé: “Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Ó tún gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe fàyè gba ìwà, ọ̀rọ̀ àti àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.—Mátíù 20:25-27.

      Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Ohun tí Jonathan Dymond tó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ẹ̀sìn sọ ni pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ “kọ̀ láti lọ́wọ́ sí [ogun]; láìka ohun yòówù kó yọrí sí, wọn ì báà pẹ̀gàn wọn, wọn ì báà sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n.” Wọ́n gbà láti jìyà dípò tí wọ́n fi máa lọ́wọ́ sí ogun. Ìwà àti ìṣe àwọn Kristẹni sì tún mú kí wọ́n dá yàtọ̀ gédégbé. Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.” (1 Pétérù 4:4) Òpìtàn náà, Will Durant, sọ pé: ‘Ìwà mímọ́ àti ìwà ọmọlúwàbí àwọn Kristẹni máa ń múnú bí àwọn abọ̀rìṣà ayé ìgbà yẹn tí ayé ìjẹkújẹ ti fọ́ lórí.’

      Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Lórí ọ̀rọ̀ pé kí Kristẹni kọ̀ láti dá sí ogun jíjà, ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, sọ ni pé: “Kò tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí rárá pé kí ẹnì kan sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò jẹ́ kóun lọ́wọ́ sí ogun jíjà.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Reformierte Presse sọ pé àjọ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílẹ̀ Áfíríkà, ìyẹn African Rights, fi ẹ̀rí hàn pé gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì pátá ló lọ́wọ́ nínú ìpẹ̀yàrun tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Rùwáńdà lọ́dún 1994, “àyàfi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo.”

      Nígbà tí olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìpakúpa rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà ìjọba Násì, ó sọ pé ó dun òun pé “kò tiẹ̀ sí ẹgbẹ́ tàbí àjọ kankan tó jẹ́ ti àwọn ará ìlú, tó sọ̀rọ̀ lòdì sí gbogbo irọ́ burúkú, ìwà ìkà àti ìwà búburú jáì tí ìjọba Násì hù.” Lẹ́yìn tí olùkọ́ yìí ṣèwádìí ní ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan, ìyẹn United States Holocaust Memorial Museum, ó kọ̀wé pé: “Mo ti wá rí ohun tí mò ń wá báyìí.” Ó rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ìdúró wọn lòdì sí gbogbo ìwà burúkú yẹn nítorí ìgbàgbọ́ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fìyà jẹ wọ́n gan-an.

      Báwo làwọn tó sọ pé Kristẹni ni àwọn ṣe ń ṣe sí ní ti ìwà híhù? Ìwé ìròyìn U.S. Catholic tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀dọ́ òde òní tó wà nínú ìjọ Kátólíìkì ni kò fara mọ́ ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì wọn ń kọ́ni lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń gbé pọ̀ bíi tọkọtaya ṣáájú ìgbéyàwó.” Ìwé ìròyìn yẹn ní díákónì kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn sọ pé: “Èyí tó ju ìdajì nínú àwọn tí mo ń rí pé wọ́n ń wá ṣègbéyàwó wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì ló jẹ́ pé wọ́n ti ń gbé pọ̀ bíi tọkọtaya ṣáájú kí wọ́n tó wá.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “gbà pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa hùwà mímọ́ nígbà gbogbo.”

  • ‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • ‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’

      “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—JÒHÁNÙ 13:34, 35.

      Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Báwo ni Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìfẹ́ tí Jésù ní sí wọn kò dà bíi ti àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ tó ní ẹ̀mí ìran tèmi lọ̀gá. Gbogbo èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló fẹ́ràn ní tiẹ̀. (Jòhánù 4:7-10) Ìfẹ́ ló mú kí Jésù máa lo gbogbo àkókò, okun àti agbára rẹ̀ láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, títí kan ìgbà tó yẹ kó máa sinmi. (Máàkù 6:30-34) Paríparí rẹ̀, ó fi ìfẹ́ tó ga jù lọ hàn. Abájọ tó fi sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.”—Jòhánù 10:11.

      Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni máa ń pe ara wọn ní “arákùnrin” àti “arábìnrin.” (Fílémónì 1, 2) Wọ́n ń gba àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tọwọ́-tẹsẹ̀ sínú ìjọ Kristẹni nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé “kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn.” (Róòmù 10:11, 12) Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù “ń ta àwọn ohun ìní àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó ohun tí a tà fún gbogbo wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní olúkúlùkù bá ṣe rí.” Kí nìdí tí wọ́n fi ń pín nǹkan wọ̀nyẹn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ aláìní? Ìdí ni pé wọ́n ń fẹ́ kí àwọn ẹni tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi wọ̀nyẹn lè dúró ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n máa “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:41-45) Kí ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni Tertullian sọ ohun táwọn kan sọ nípa àwọn Kristẹni ní èyí tí kò tíì tó igba ọdún lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, pé: “Wọ́n mà nífẹ̀ẹ́ ara wọn o . . . kódà wọn ṣe tán láti kú fún ara wọn.”

      Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Ìwé kan tó sọ ìtàn nípa bí ilẹ̀ ọba Róòmù ṣe ṣubú sọ pé àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni “ń han ara wọn léèmọ̀ lọ́nà tó burú jáì ju èyí tí àwọn aláìgbàgbọ́ pàápàá ń ṣe sí wọn lọ.” (The History of the Decline and Fall of the Roman Empire [1837]) Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láìpẹ́ yìí fi hàn pé àárín àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ni ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti wọ́pọ̀ jù, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló sì pe ara wọn ní Kristẹni. Bákan náà, ẹ̀mí kóńkó jabele sábà máa ń wà láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ìjọ kan náà àmọ́ tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, torí náà nígbà ìṣòro, wọn kì í lè ṣèrànlọ́wọ́ fún ara wọn, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ fẹ́ ṣèrànwọ́ rárá.

      Lọ́dún 2004, lẹ́yìn tí ìjì líle ńláńlá jà ní ìpínlẹ̀ Florida lẹ́ẹ̀mẹrin láàárín oṣù méjì, alága ìgbìmọ̀ kan tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, ìyẹn Florida’s Emergency Operations Committee, ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀ láti lè rí i dájú pé àwọn èèyàn ń lo ohun tí àjọ náà ń pèsè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Alága náà sọ pé kò sí àwùjọ kankan tó wà létòlétò bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá sọ pé òun ṣe tán láti pèsè gbogbo ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn bá sọ pé àwọn nílò. Ṣáájú ìgbà yẹn, lọ́dún 1997, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kó oògùn, oúnjẹ àti aṣọ láti ilẹ̀ Yúróòpù lọ sí orílẹ̀-èdè Kóńgò láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn àti àwọn míì tó nílò ìrànlọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn ní ilẹ̀ Yúróòpù ló fún wọn ní àwọn ohun èlò náà, èyí tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́jọ ó lé mẹ́rin náírà.

  • ‘Mo Ti Sọ Orúkọ Rẹ Di Mímọ̀’
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • ‘Mo Ti Sọ Orúkọ Rẹ Di Mímọ̀’

      “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé. . . . Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.”—JÒHÁNÙ 17:6, 26.

      Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Jésù sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ ní ti pé ó ń lò ó bó ṣe ń wàásù. Jésù sábà máa ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sétí ìgbọ́ àwọn èèyàn, torí náà, láwọn ìgbà tó ń kà á yóò ti pe orúkọ Ọlọ́run níbi tó bá ti rí i nínú Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 4:16-21) Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Lúùkù 11:2.

      Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé Ọlọrun ti mú “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 15:14) Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn yòókù sì wàásù pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Ìṣe 2:21; Róòmù 10:13) Wọ́n tún lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ. Ìwé àkópọ̀ òfin àtẹnudẹ́nu tó ń jẹ́ The Tosefta, tí wọ́n parí kíkọ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 300 Sànmánì Kristẹni, sọ nípa bí àwọn ọ̀tá ṣe dáná sun ìwé àwọn Kristẹni, ó ní: “Ìwé àwọn Ajíhìnrere àti ìwé àwọn minim [èyí lè túmọ̀ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù] ni wọn kò yọ nínú iná. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí iná jó wọn mọ́ ibi tí wọ́n wà, . . . àwọn ìwé náà àti Orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú wọn.”

      Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Bíbélì Revised Standard Version, tí Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ní Amẹ́ríkà fàṣẹ sí, sọ nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀ pé: “Lílo orúkọ pàtó kan fún Ọlọ́run kan ṣoṣo náà, bí ẹni pé àwọn ọlọ́run mìíràn wà, tí a ní láti fi Ọlọ́run tòótọ́ hàn yàtọ̀ lára wọn, ni wọ́n ti ṣíwọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù ṣáájú sànmánì àwọn Kristẹni, àti pé kò tiẹ̀ yẹ kó wáyé rárá nínú ìgbàgbọ́ àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ní gbogbo gbòò.” Wọ́n wá fi orúkọ oyè náà, “OLÚWA,” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì yẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì pàṣẹ fún àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run, tó jẹ mọ́ lẹ́tà mẹ́rin ti èdè Hébérù náà YHWHa yálà nínú orin tàbí nínú àdúrà, ẹ má sì pè é rárá.”

      Lóde òní, àwọn wo ló ń lo orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sọ ọ́ di mímọ̀ fún àwọn èèyàn? Nígbà tí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sergey ṣì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, ó wo fíìmù kan tí wọ́n ti sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Odindi ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, kò gbọ́ nǹkan kan nípa orúkọ yẹn mọ́. Lẹ́yìn tí Sergey wá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wàásù fún un nílé rẹ̀, wọ́n sì fi orúkọ Ọlọ́run hàn án nínú Bíbélì. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé òun rí àwọn èèyàn tó ń lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Ó sì dùn mọ́ni pé ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Third New International Dictionary, sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni “Ọlọ́run gíga jù lọ, òun sì ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn.”

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a “Jèhófà” ni wọ́n sábà máa ń pe orúkọ Ọlọ́run lédè Yorùbá.

  • “A Ó sì Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Yìí”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | March 1
    • “A Ó sì Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Yìí”

      “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—MÁTÍÙ 24:14.

      Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ̀wé Ìhìn Rere sọ pé Jésù “ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere ní àwọn ìlú àti abúlé, lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rǐ mi . . . títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8, Ìròhìn Ayọ̀; Lúùkù 10:1.

      Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tó ní kí wọ́n ṣe láìjáfara. Bíbélì sọ pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi.” (Ìṣe 5:42) Gbogbo wọn ló ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, wọn kò fi mọ sí àárín àwùjọ pàtàkì kan. Ohun tí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Neander sọ ni pé, ọ̀gbẹ́ni “Celsus tó kọ́kọ́ kọ̀wé láti fi ta ko ìsìn Kristẹni fi àwọn Kristẹni ṣe yẹ̀yẹ́ lórí pé àwọn tó ń rànwú, àwọn tó ń ṣe bàtà, àwọn oníṣẹ́ awọ, àwọn tó ya púrúǹtù jù lọ àtàwọn gbáàtúù nínú ìràn ènìyàn ń fi ìtara wàásù ìhìnrere.” Ọ̀gbẹ́ni Jean Bernardi sọ nínú ìwé rẹ̀ The Early Centuries of the Church pé: “Ṣe ló yẹ káwọn [Kristẹni] máa lọ síbi gbogbo àti sọ́dọ̀ olúkúlùkù èèyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Lójú pópó àti láwọn ìlú ńlá, ní gbàgede ìlú àti nínú ilé àwọn èèyàn. Yálà àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà wọ́n tàbí wọn ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. . . . Kí wọ́n dé ìpẹ̀kun ayé.”

      Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Àlùfáà ìjọ Áńgílíkà kan tó ń jẹ́ David Watson sọ pé: “Bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kò ṣe fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó fà á tí àwọn èèyàn òde òní kò fi nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn Ọlọ́run.” Nínú ìwé tí ọ̀gbẹ́ni José Luis Pérez Guadalupe kọ láti fi sọ ìdí tí àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì fi ń fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó mẹ́nu kan ìgbòkègbodò àwọn ìjọ Ajíhìnrere, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ọjọ́ Ìsinmi (ìyẹn àwọn Adventist) àti àwọn míì, ó sí sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn “kì í lọ láti ilé dé ilé.” Àmọ́ ohun tó kọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé: “Wọ́n máa ń lọ láti ilé dé ilé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.”—Why Are the Catholics Leaving.

      Àkíyèsí pàtàkì kan tó wúni lórí tí ọ̀gbẹ́ni Jonathan Turley sọ, èyí tó wà nínú ìwé Cato Supreme Court Review, 2001-2002 ni pé: “Kó o máà tíì dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn á ti ronú kan àwọn oníwàásù kan tó máa ń wá sílé àwọn láwọn àsìkò tí kò rọgbọ. Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe torí pé wọ́n kàn fẹ́ tan ẹ̀sìn kálẹ̀ ni wọ́n ṣe ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà láti yíni lọ́kàn pa dà, àmọ́ ṣe ni wọ́n gbà pe iṣẹ́ yẹn jẹ́ ọ̀nà pàtàkì téèyàn gbà ń fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́.”

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

      Àwọn Wo Ni Ẹ̀rí Wọ̀nyẹn Fi Hàn Pé Ó Jẹ́ Kristẹni Tòótọ́?

      Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn kókó pàtàkì látinú Ìwé Mímọ́ tí a gbé yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, àwọn wo ni ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ lónìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ìjọ ló ń sọ pé Kristẹni ni àwọn, rántí ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mátíù 7:21) Tó o bá mọ àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Baba, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ni Kristẹni tòótọ́, tó o sì dara pọ̀ mọ́ wọn, ó lè yọrí sí ìbùkún ayérayé fún ọ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. A rọ̀ ọ́ pé kó o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mú ìwé yìí tọ̀ ọ́ wá pé kí wọ́n túbọ̀ ṣàlàyé fún ọ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bó ṣe máa ṣe wá láǹfààní.—Lúùkù 4:43.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́