-
Ọ̀rẹ́ ÈkéJí!—2010 | July
-
-
Ọ̀rẹ́ Èké
O ní “ọ̀rẹ́” kan tẹ́ ẹ ti mọra láti ìgbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́. Ó máa ń jẹ́ kó o túbọ̀ rí ara rẹ bí ẹni tó ti gòkè àgbà, ó sì máa ń jẹ́ kó o lè bá ẹgbẹ́ pé. Kò sígbà tí nǹkan bá tojú sú ẹ, tí kì í wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti “tù ẹ́ lára.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ọ̀pọ̀ ìgbà lo máa ń gbára lé e fún ìrànlọ́wọ́.
Àmọ́ nígbà tó yá, o wá kíyè sí àwọn nǹkan kan tí kò dáa nípa ọ̀rẹ́ rẹ yìí. Ó fẹ́ máa wà pẹ̀lú rẹ ṣáá nígbà gbogbo, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé èyí ò ní jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dáa wò ẹ́ láwọn ibì kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mú kó o túbọ̀ rí ara rẹ bíi pé o ti gòkè àgbà, àkóbá tó ń ṣe fún ìlera rẹ kò kéré rárá. Paríparí rẹ̀, ó ti jí lára owó rẹ.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, o ti gbìyànjú láti fòpin sí àjọṣe yín, àmọ́ kò fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀. Ká kúkú sọ pé òun ló ń darí rẹ. O kábàámọ̀ pé o ní irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀.
IRÚ nǹkan tí ojú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń mu sìgá ń rí nìyí. Lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Earline ti ń mu sìgá, ó sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí sìgá máa ń ṣe fún mi ju èyí tí èèyàn èyíkéyìí lè ṣe fún mi lọ. Yàtọ̀ sí pé ó ti pẹ́ tá a ti ń bára wa bọ̀, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé òun nìkan ló máa ń kù mí kù.” Nígbà tó yá, obìnrin yìí wá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ èké àti apanilára ni sìgá. Kódà, ohun kan péré ni ọ̀rọ̀ obìnrin yìí fi yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Nígbà tó wá mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa kórìíra sìgá mímu, torí pé ó máa ń ṣàkóbá fún ara, ó jáwọ́ nínú àṣà yìí.—2 Kọ́ríńtì 7:1.
Bákan náà, ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frank pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, torí pé ó fẹ́ ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ tó pinnu pé òun kò ní mu sìgá mọ́, ńṣe ló tún bẹ̀rẹ̀ sí í rá pálá nínú yàrá rẹ̀ tó ń wá àwọn àmukù sìgá tó há sáwọn ibì kan ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Ọkùnrin náà sọ pé: “Èyí ló pe orí mi wálé tí mo sì ṣe ìpinnu. Bí mo ṣe ń rá pálá nínú ìdọ̀tí torí pé mò ń wá àmukù sìgá rí mi lára gan-an ni. Bó ṣe di pé mi ò fẹnu kan sìgá mọ́ nìyẹn o.”
Kí nìdí tó fi ṣòro tó bẹ́ẹ̀ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu? Àwọn olùṣèwádìí sọ àwọn ohun mélòó kan tó fà á. (1) Bíi ti oògùn olóró, àwọn ohun tí wọ́n ń mú jáde láti ara tábà lè di bára kú. (2) Béèyàn bá fa èròjà olóró inú sìgá sí agbárí, ó máa dé inú ọpọlọ láàárín ìṣẹ́jú àáyá méje. (3) Sìgá mímu máa ń di bára kú torí wọ́n sábà máa ń mu ún láwọn ibi tí wọ́n bá ti ń jẹun, tí wọ́n ti ń mutí, tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n ti ń wá ìtura kúrò lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Síbẹ̀, bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ Earline àti Frank, èèyàn lè jáwọ́ nínú àṣà tó ń di bárakú tó sì ń pani lára yìí. Bó bá jẹ́ pé o máa ń mu sìgá, tó o sì fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀, tó o bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, ó lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun fún ẹ.
-
-
Rọ̀ Mọ́ Ìpinnu RẹJí!—2010 | July
-
-
Rọ̀ Mọ́ Ìpinnu Rẹ
“Rírọ̀ mọ́ ìpinnu téèyàn ṣe láti jáwọ́ nínú sìgá mímu ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu.”— Ìwé kan tó ń jẹ́,“Stop Smoking Now!”
LẸ́NU kan, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, ohun kan ni pé, o gbọ́dọ̀ ṣe tán láti rọ̀ mọ́ ìpinnu tó o ṣe. Báwo lo ṣe lè rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ? Ọ̀nà kan ni pé kó o ronú nípa bí ìgbésí ayé rẹ á ṣe sunwọ̀n sí i bó o bá jáwọ́ nínú sìgá mímu.
Wàá ní àjẹṣẹ́kù. Bí ẹnì kan bá ń mu páálí sìgá kan lójúmọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ná tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún náírà sórí sìgá lọ́dún. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Gyanu láti orílẹ̀-èdè Nepal sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé owó kékeré kọ́ ni mo fi ṣòfò lórí sìgá mímu.”
Ó yẹ kí ayé rẹ túbọ̀ ládùn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Regina lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Ìgbà tí mo jáwọ́ nínú sìgá mímu ni mo bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun, ńṣe ni ayé mi wá ń dáa sí i.” Béèyàn bá jáwọ́ nínú sìgá mímu, òun fúnra rẹ̀ máa mọ̀ ọ́n lára pé agbára ìtọ́wò àti ìgbóòórùn òun ti sunwọ̀n sí i, á wá dẹni tó túbọ̀ ní okun nínú, ìrísí rẹ̀ á sì túbọ̀ fani mọ́ra.
Ìlera rẹ lè sunwọ̀n sí i. “Ì báà jẹ́ ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé tàbí àgbà, ló jáwọ́ nínú sìgá mímu, kì í pẹ́ rárá tí wọ́n fi máa ń rí i tí ìlera wọn á sunwọ̀n sí i.”—Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Wàá túbọ̀ dá ara rẹ lójú. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Henning lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Mo jáwọ́ nínú sìgá mímu torí pé mi ò fẹ́ kí sìgá di ọ̀gá mi. Èmi ni mo fẹ́ máa darí ara mi.”
Tẹbí-tọ̀rẹ́ ló máa jàǹfààní. “Bó o bá ń mu sìgá, . . . Ò ń ṣèpalára fún ìlera àwọn tó wà ní àyíká rẹ. . . . Ìwádìí fi hàn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró àti àìsàn ọkàn ń pa lọ́dọọdún látàrí bí èéfín sìgá táwọn ẹlòmíì mu ṣe ń kó sí wọn lágbárí.”—Ẹgbẹ́ Tó Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Wàá mú inú Ẹlẹ́dàá rẹ dùn. “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní . . . mímọ́, [lọ́nà] tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.”—Róòmù 12:1.
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sylvia lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Ní gbàrà tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run kò fẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan tó ń ṣàkóbá fún ara wa, ńṣe ni mo pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè gba pé kéèyàn ṣe ju rírọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀ lọ. A tún lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì, títí kan tẹbí-tọ̀rẹ́. Kí ni wọ́n lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́?
-
-
Wá Ìrànlọ́wọ́Jí!—2010 | July
-
-
Wá Ìrànlọ́wọ́
“Bí ẹnì kan bá . . . lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.”—Oníwàásù 4:12.
PẸ̀LÚ ìtìlẹ́yìn àwọn míì, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti borí ọ̀tá, ì báà jẹ́ èèyàn ni ọ̀tá náà tàbí ohun míì. Torí náà, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, á dáa kó o wá ìrànlọ́wọ́ tẹbí-tọ̀rẹ́ tàbí ẹlòmíì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tọkàntọkàn tó sì jẹ́ onísùúrù.
O lè wá ìrànlọ́wọ́ àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu, torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ, wọ́n á sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè jáwọ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Torben lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tó wúlò gan-an làwọn míì ṣe fún mi.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Abraham lórílẹ̀-èdè India sọ pé: “Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí ìdílé mi àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n jáwọ́ nínú sìgá mímu.” Àmọ́ nígbà míì, ohun téèyàn nílò ju ìrànlọ́wọ́ tẹbí-tọ̀rẹ́ lọ.
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bhagwandas sọ pé: “Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ni mo fi mu sìgá, àmọ́ nígbà tí mo wá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà àìmọ́, mo pinnu láti jáwọ́. Mo gbìyànjú láti dín iye sìgá tí mò ń mu kù. Mo fi àwọn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ àwọn agbaninímọ̀ràn. Àmọ́ gbogbo èyí kò ṣiṣẹ́ rárá. Nígbà tó yá, lọ́jọ́ kan mo sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún Jèhófà Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, mo jáwọ́ nínú sìgá mímu!”
Ohun míì tó yẹ kó o ṣe ni pé, kó o múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó o dojú kọ. Kí ni àwọn ìṣòro wọ̀nyí? A ó ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
ǸJẸ́ Ó YẸ KÓ O LO OÒGÙN?
Bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu ṣe ń lo oògùn lóríṣiríṣi, irú bí èròjà olóró inú sìgá tí wọ́n máa ń fi sára awọ, ti wá sọ ṣíṣe àwọn oògùn náà di iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn èyíkéyìí, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn àǹfààní wo ló wà níbẹ̀? Wọ́n ní àwọn ìtọ́jú kan tó máa ń jẹ́ kéèyàn jáwọ́ nínú sìgá mímu máa ń jẹ́ kí àìfararọ tó máa ń wáyé nígbà téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ dín kù. Àmọ́ ṣá, àríyànjiyàn ṣì wà lórí bí àǹfààní rẹ̀ á ṣe pẹ́ tó.
Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀? Àwọn oògùn kan wà tó máa ń fa àwọn ìṣòro, irú bíi kí èébì máa gbéni, ìdààmú ọkàn tàbí kéèyàn máa ronú láti pa ara rẹ̀. Tún fi sọ́kàn pé, ńṣe ni àwọn ìtọ́jú tí wọ́n máa ń fi èròjà olóró inú sìgá ṣe wulẹ̀ jẹ́ lílo oògùn olóró lọ́nà míì, èyí pẹ̀lú sì léwu. Òótọ́ ibẹ̀ ni pe, ńṣe làwọn tó bá ń lo irú àwọn oògùn yìí ṣì ń sọ oògùn olóró di bára kú.
Àwọn àfidípò wo ló wà? Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn kan tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu, ìdá méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] nínú ọgọ́rùn-ún [100] ló sọ pé ńṣe làwọn kàn jáwọ́ ńbẹ̀, àwọn ò lo oògùn kankan.
-
-
Múra Sílẹ̀ De ÌṣòroJí!—2010 | July
-
-
Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro
“Mo pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, nígbà tí mo ro ti àkóbá tó lè ṣe fún ìlera ọmọ wa tuntun. Torí náà, mo lẹ àkọlé náà, ‘Má Ṣe Mu Sìgá’ sínú ilé wa. Àmọ́, kò ju wákàtí kan lọ lẹ́yìn náà tí sìgá fi bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí mu gan-an, bí mo ṣe ṣáná sí sìgá kan nìyẹn.”—Yoshimitsu, Japan.
OHUN tó ṣẹlẹ̀ sí Yoshimitsu yìí fi hàn pé àwọn ìṣòro kan máa dojú kọ ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu. Bákan náà, ìwádìí fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó tún pa dà mu sìgá lẹ́yìn tí wọ́n ti pinnu láti jáwọ́ ńbẹ̀ ló tún sọ ọ́ dàṣà. Torí náà, bó o bá ń gbìyànjú láti jáwọ́, ó ṣeé ṣe kó o kẹ́sẹ járí tó o bá múra sílẹ̀ de ìṣòro. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó sábà máa ń yọjú?
Á máa wù ẹ́ gan-an láti mu sìgá: Èyí sábà máa ń le gan-an lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó o bá jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó sì máa tó nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì kí ara rẹ tó balẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń mu sìgá nígbà kan sọ pé: “Ìgbà míì wà tó máa ń wu èèyàn gan-an láti mu sìgá, tó bá sì tún yá kò ní fi bẹ́ẹ̀ wuni mọ́.” Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, sìgá kàn lè ṣàdédé wù ẹ́ mu. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fara balẹ̀. Dúró fún nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún, wàá rí i pé kò ní wù ẹ́ mu mọ́.
Àwọn ìṣòro míì: Téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sìgá mímu sílẹ̀, oorun lè máa kùn ún ṣáá tàbí kó ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì lè máa sanra sí i. Lára àwọn ìṣòro tó tún lè jẹ yọ ni, ara ríro, ara yíyún, ìlàágùn, ikọ́ àti ìṣesí tó ṣàdédé yí ń pa dà, èyí tí kì í jẹ́ kéèyàn ní sùúrù, tó lè mú kéèyàn tètè máa bínú tàbí tó lè fa ìsoríkọ́. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìṣòro yìí ló máa ń lọ sílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí mẹ́fà.
Láàárín àkókò líle koko yìí, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ:
● Máa sùn dáadáa.
● Máa mu omi tàbí omi èso dáadáa. Máa jẹ oúnjẹ tó máa ṣara lóore.
● Máa ṣe eré ìmárale níwọ̀n tó yẹ.
● Mí kanlẹ̀, kó o sì máa wò ó bíi pé ò ń rí afẹ́fẹ́ tó mọ́ tó ò ń mí sínú.
Àwọn nǹkan tó lè mú kí sìgá máa wù ẹ́ mu: Èyí kan àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tàbí èrò tó lè mú kó o fẹ́ láti mu sìgá. Bí àpẹẹrẹ, bóyá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tó o bá ń mu ọtí tàbí nǹkan míì, ńṣe lo máa ń mu sìgá pẹ̀lú rẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, má ṣe máa pẹ́ rárá nídìí ọtí tàbí ohun mímu mìíràn. Tó bá yá, wàá máa fẹ̀sọ̀ gbádùn àwọn ohun tó o bá ń mu.
Síbẹ̀, sìgá ṣì lè máa wù ẹ́ mu, bó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tó o ti fi í sílẹ̀. Torben tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún tí mo ṣíwọ́ sìgá mímu, ó ṣì máa ń wù mí mu nígbà tá a bá ń mu kọfí ní ibiṣẹ́.” Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, tó bá yá sìgá kò ní wù ẹ́ mu mọ́ nígbà tó o bá ń ṣe àwọn ohun tó máa ń jẹ́ kó wù ẹ́ mu tẹ́lẹ̀, wàá sì lè tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ sìgá mímu.
Ọ̀rọ̀ ọtí mímu tún wá yàtọ̀ o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bó o bá ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó lè gba pé kó o má ṣe mutí rárá, kó o má sì lọ síbi táwọn èèyàn ti ń mutí, torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá ló tún máa ń pa dà sínú àṣà náà nígbà tí wọ́n bá ń mutí. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀?
● Ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba ọtí díẹ̀ lo mu, ó máa jẹ́ kí sìgá túbọ̀ máa wù ẹ́ mu.
● Táwọn èèyàn bá ń mutí, wọ́n sábà máa ń mu sìgá.
● Ọtí mímu kì í jẹ́ kéèyàn lè ronú bó ṣe yẹ, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn máa hùwà àìnítìjú. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: ‘Wáìnì máa ń gba ète rere kúrò.’—Hós. 4:11.
Àwọn tó ò ń bá kẹ́gbẹ́: Máa fọgbọ́n yan ọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, yẹra fún àwọn tó ń mu sìgá àtàwọn tó lè fi sìgá lọ̀ ẹ́. Bákan náà, yẹra fún àwọn tó lè mú kó o juwọ́ sílẹ̀ nínú ìpinnu rẹ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, bóyá nípa fífi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́.
Ìmọ̀lára rẹ: Ìwádìí kan fi hàn pé, ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn tó tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá ni nǹkan máa ń tojú sú tàbí ni inú máa ń bí kí wọ́n tó pa dà sínú àṣà náà. Bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó mú kí sìgá máa wù ẹ́ mu, ńṣe ni kó o wá nǹkan míì ṣe, bóyá kó o mu omi, kó o jẹ ṣingọ́ọ̀mù tàbí kó o nasẹ̀ jáde lọ. Gbìyànjú láti máa ronú nípa ohun tó dáa, o lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kó o ka Bíbélì.—Sáàmù 19:14.
Ṣọ́ra fún Àwáwí
● Mi ò ní fà ju ọwọ́ kan péré lọ.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó o bá fa sìgá lẹ́ẹ̀kan péré, ọpọlọ rẹ lè gba ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún èròjà olóró inú sìgá sínú fún wákàtí mẹ́ta. Ohun tí èyí sì sábà máa ń yọrí sí ni pé, ńṣe ni wàá tún pa dà sínú àṣà náà ní pẹrẹu.
● Sìgá ni mo máa fi ń pa ìrònú rẹ́.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ìwádìí fi hàn pé èròjà olóró inú sìgá máa ń mú kéèyàn ní àìfararọ tó pọ̀ sí i. Tó bá dà bíi pé sìgá mímu dín ìdààmú ọkàn rẹ kù, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwọn ìṣòro tó máa ń yọjú nígbà téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ kàn dín kù fúngbà díẹ̀ ni.
● Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń mu sìgá, mi ò rò pé mo lè jáwọ́.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Béèyàn bá ń ní èrò pé nǹkan ò lè dáa, kì í jẹ́ kéèyàn lè ní ìtẹ̀síwájú. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Torí náà, má ronú pé o ò lè jáwọ́ ńbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu lóòótọ́ lè ṣàṣeyọrí, bó bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, bí irú èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.
● Àwọn ìṣòro tí mò ń kojú nítorí pé mo fẹ́ fi sìgá mímu sílẹ̀ ti pọ̀ jù fún mi.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Òótọ́ ni pé, àwọn ìṣòro yẹn lè kọ́kọ́ ka èèyàn láyà, àmọ́ ká tó rí ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, gbogbo ẹ̀ máa dàwátì. Torí náà, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì! Bó bá tiẹ̀ tún ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún, ìmọ̀lára yẹn náà máa dàwátì láàárín ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, ìyẹn bí o kò bá tún tanná sí sìgá.
● Mo ní àìsàn ọpọlọ.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó bá jẹ́ pé ò ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ fún oríṣi àìsàn ọpọlọ kan, bóyá ìsoríkọ́ tàbí ọpọlọ dídàrú, sọ fún dókítà rẹ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ó ṣeé ṣe kí inú rẹ̀ dùn gan-an láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, bóyá kó ṣe ìyípadà díẹ̀ nínú ìtọ́jú tó ń fún ẹ, kí ìpinnu tó o ṣe yìí má bàa ṣe ìpalára kankan fún ìlera rẹ tàbí kó má bàa ṣèdíwọ́ fún oògùn tó ò ń lò.
● Bí mo bá tún fẹnu kan sìgá pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni màá gbà pé mi ò lè ṣàṣeyọrí.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé o tún mu sìgá nígbà tó o ní ìṣòro kan, ọ̀rọ̀ rẹ kò tíì kọjá àtúnṣe, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì, ńṣe ni kó o ṣara gírí. Béèyàn bá ṣubú, kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣàṣeyọrí mọ́, àmọ́ ẹni tó ṣubú, tó sì kọ̀ láti dìde ni kò lè ṣàṣeyọrí. Torí náà, túbọ̀ máa sapá. Bó pẹ́ bó yá, wàá ṣàṣeyọrí!
Wo àpẹẹrẹ Romualdo, ẹni tó fi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] mu sìgá, àmọ́ tó ti jáwọ́ nínú rẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mi ò lè ka iye ìgbà tí mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, gbogbo ìgbà tí mo bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ ni inú mi máa ń bà jẹ́, tó sì máa ń ṣe mí bíi pé aláṣetì ni mí. Àmọ́, nígbà tí mo ṣe ìpinnu tó lágbára pé mo fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, tí mi ò sì yéé gbàdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́, mo bọ́ lọ́wọ́ sìgá mímu ní gbẹ̀yìn-gbẹ́yín.”
Nínú àpilẹ̀kọ kan tó kù nínú ọ̀wọ́ yìí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó wúlò díẹ̀ sí i tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàṣeyọrí nínú ìsapá rẹ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó LÉWU NÍ GBOGBO Ọ̀NÀ
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà ń lo tábà. Wọ́n tiẹ̀ máa ń ta àwọn nǹkan tí wọ́n mú jáde látara tábà láwọn ilé ìtajà tí wọ́n ti máa ń ta àwọn oúnjẹ tó lè mú kéèyàn túbọ̀ ní ìlera tó dáa àti oògùn ìbílẹ̀. Síbẹ̀, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ọ̀nà yòówù kéèyàn gbà lo tábà, ewu wà ńbẹ̀.” Èyíkéyìí lára àwọn àrùn tí tábà máa ń fà ló lè já sí ikú, irú bí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àtàwọn òpó ẹ̀jẹ̀. Àwọn aboyún tó ń mu sìgá tiẹ̀ lè ṣèpalára fún ọmọ wọn. Àwọn ọ̀nà wo tiẹ̀ ni wọ́n máa ń gbà lo àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe?
Bídì (sìgá àwọn ará Éṣíà): Oríṣi sìgá tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi yìí ló wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà. Sìgá yìí yàtọ̀, torí pé eérú, èròjà olóró inú sìgá àti èéfín tó máa ń ti ara rẹ̀ jáde pọ̀ ju tàwọn sìgá yòókù lọ.
Tábà: Wọ́n máa ń lọ̀ ọ́ mọ́ àwọn nǹkan míì, wọ́n á wá fi ewé tábà pọ́n ọn tàbí kí wọ́n pọ́n ọn sínú bébà tí wọ́n fi ewé tábà ṣe. Èròjà tó wà nínú tábà yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú àwọn sìgá yòókù, ìdí nìyẹn tí èròjà olóró inú tábà fi lè gba ẹnu wọ inú ara láì tiẹ̀ ṣáná sí i rárá.
Sìgá tí wọ́n lọ òdòdó olóòórùn dídùn mọ́: Èyí jẹ́ àpapọ̀ tábà àti òdòdó olóòórùn dídùn. Tábà inú rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá nígbà tí ìdá mẹ́rin yòókù jẹ́ òdòdó olóòórùn dídùn. Eérú, èròjà olóró àti èéfín tó máa ń jáde látara rẹ̀ pọ̀ ju tàwọn sìgá yòókù lọ.
Ìkòkò: Mímu ìkòkò kì í ṣe àṣà tó dáa téèyàn lè fi rọ́pò sìgá mímu, méjèèjì ló lè fa àrùn jẹjẹrẹ àtàwọn àrùn míì.
Tábà tí kò léèéfín: Irú bíi tábà tí wọ́n máa ń jẹ, áṣáà àti gutkha, ìyẹn tábà tí wọ́n máa ń lọ èròjà atasánsán mọ́, èyí tó wọ́pọ̀ ní apá Gúúsù Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà. Látẹnu ni èròjà olóró inú rẹ̀ ti máa ń wọ inú ẹ̀jẹ̀ lọ. Gbogbo ọ̀nà ni tábà tí kò léèéfín fi léwu bíi tàwọn oríṣi tábà yòókù.
Àwọn ìkòkò olómi: Bí wọ́n ṣe ṣe èyí ni pé, èéfín tábà á gba àárín omi kọjá kó tó di pé èèyàn fà á ságbárí. Síbẹ̀ kò dájú pé èyí máa dín èròjà olóró tó ń lọ sínú ẹ̀dọ̀ fóró kù, tó fi mọ́ èròjà tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
BÓ O ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN ẸNI TÓ BÁ FẸ́ JÁWỌ́
● Ní èrò tó dáa. Ó sàn kó o máa gbóríyìn, kó o sì máa sọ̀rọ̀ rere fún ẹni náà ju kó o máa ṣàròyé, kó o sì máa nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀ lọ. Ó dáa kó o sọ pé, “Mo ronú pé wàá ṣàṣeyọrí tó o bá tún gbìyànjú” ju kó o sọ pé, “O tún ti fìdí rẹmi, àbí?”
● Máa dárí jini. Ńṣe ni kó o gbójú fo ìbínú tàbí ìjákulẹ̀ látọ̀dọ̀ ẹni tó ń sapá láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára bíi, “Mo mọ̀ pé kò rọrùn, àmọ́ inú mi dùn fún bó o ṣe ṣe é.” Má ṣe sọ pé, “Ó kúkú sàn fún ẹ nígbà tó ò ń mu sìgá ju báyìí lọ!”
● Jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ńṣe ni kó o máa ní sùúrù kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu “ní gbogbo ìgbà,” tàbí àsìkò yòówù kó jẹ́, kó o sì máa fara da ohun yòówù kí onítọ̀hún ṣe sí ọ.
-
-
O Lè Ṣàṣeyọrí!Jí!—2010 | July
-
-
O Lè Ṣàṣeyọrí!
ÀKÓKÒ ti tó fún ẹ báyìí láti “jẹ́ onígboyà kí o sì gbé ìgbésẹ̀.” (1 Kíróníkà 28:10) Paríparí rẹ̀, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táa jẹ́ kí àṣeyọrí rẹ túbọ̀ dájú?
Dá ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́. Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tó Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú dábàá pé bó o bá ti pinnu láti fi sìgá mímu sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ tó o máa fòpin sí i pátápátá ju ọ̀ṣẹ̀ méjì lọ sígbà yẹn. Èyí á jẹ́ kó o lè rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ. Sàmì sí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ lórí kàlẹ́ńdà, sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, má sì ṣe yí ọjọ́ náà pa dà, láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí.
Ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè jáwọ́. Àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí wà lára ohun tó o lè kọ, o sì tún lè kọ àwọn nǹkan míì tó lè mú kó o rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ:
● Ìdí tó o fi fẹ́ jáwọ́
● Nọ́ńbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn tó o lè pè tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún mu sìgá
● Àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ẹsẹ Bíbélì tó o lè máa ronú lé tí kò ní jẹ́ kó o yẹ ìpinnu rẹ, irú bíi Gálátíà 5:22, 23
Máa mú àkọsílẹ̀ rẹ dání nígbà gbogbo, kó o sì máa kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́. Kódà lẹ́yìn tó o bá ti jáwọ́, rí i pé ò ń ka àkọsílẹ̀ náà nígbàkigbà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o tún mu sìgá.
Jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó lè mú kó o tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Kó tó di ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tó o bá fẹ́ mu sìgá. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé gbàrà tó o bá ti jí láràárọ̀ lo máa ń mu sìgá, rí i pé o ò mu sìgá láàárín nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́yìn tó o bá jí. Bó bá jẹ́ pé o máa ń mu sìgá nígbà tó o bá ń jẹun tàbí ní gbàrà tó o bá jẹun tán, rí i pé o ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Má ṣe máa lọ síbi tí wọ́n bá ti ń mu sìgá. Nígbà tó o bá dá wà, máa ṣe ìdánrawò nípa sísọ̀rọ̀ sókè pé: “Ẹ ṣeun. Mi ò mu sìgá mọ́.” Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti jáwọ́ ní ọjọ́ tó o ti yàn. Ṣíṣe àwọn nǹkan yìí á tún máa rán ẹ létí pé, láìpẹ́ o máa di ẹni tí kì í mu sìgá mọ́.
Múra sílẹ̀. Bí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ ṣe ń sún mọ́, wá àwọn nǹkan ìpanu sí ìtòsí, àwọn nǹkan bíi: kárọ́ọ̀tì, ṣingọ́ọ̀mù, ẹ̀pà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Máa rán tẹbí-tọ̀rẹ́ létí ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kó tó di ọjọ́ náà, kó àwọn agolo tí ò ń ṣẹ́ eérú sìgá sí àti ìṣáná kúrò nílẹ̀ àti ohunkóhun tó lè mú kí sìgá tún wù ẹ́ mu, irú bí àwọn sìgá tó lè wà káàkiri nínú ilé, nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, nínú àpò rẹ tàbí ní ibi iṣẹ́ rẹ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ó rọrùn láti mú sìgá tó o ti fi sínú àpótí kan jáde ju kó o béèrè lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ kan tàbí kó o ra páálí kan. Bákan náà, máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà lẹ́yìn tó o bá ti jáwọ́.—Lúùkù 11:13.
Àìmọye èèyàn ló ti “fòpin sí” àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti sìgá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ èké àti apanilára tí wọ́n ní nígbà kan. Ìwọ náà lè fòpin sí àjọṣe àárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ burúkú yìí. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìlera rẹ á sunwọ̀n sí i, wàá sì ní òmìnira fàlàlà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Máa mú àkọsílẹ̀ rẹ dání nígbà gbogbo, kó o sì máa kà á lákàtúnkà lójoojúmọ́
-