ORIN 49
Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣèfẹ́ Jáà. - Àwa yóò máa hùwà ọgbọ́n. - Tá a bá ńṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé - A fẹ́ máa mú inú rẹ̀ dùn. 
- 2. Ẹrú olóòótọ́, olóye - Ń kéde ògo rẹ fáráyé. - Wọ́n ń bọ́ wa lásìkò tó yẹ, - Kí a lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ. 
- 3. Fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ - Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ. - Ká ṣohun tó máa gbé ọ ga, - Ká sì máa mú inú rẹ dùn. 
(Tún wo Mát. 24:45-47; Lúùkù 11:13; 22:42.)