ORIN 35
Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”
- 1. A nílò ìfòyemọ̀ gan-an lónìí - Ká lè mọ ohun tó tọ́; - Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù - Tí a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe. - (ÈGBÈ) - Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi. - Múnú Jáà dùn. - Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì - Nífòyemọ̀, - Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù! 
- 2. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé - Ká wàásù ìhìn rere. - Ká kọ́ àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ - Kí wọ́n ṣèfẹ́ Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi. - Múnú Jáà dùn. - Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì - Nífòyemọ̀, - Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù! 
- 3. Tá a bá ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù, - Ọkàn wa máa balẹ̀ gan-an. - Àlàáfíà Ọlọ́run wa yóò máa ṣọ́ - Ọkàn àti èrò wa. - (ÈGBÈ) - Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi. - Múnú Jáà dùn. - Yóò bù kún wa báa ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì - Nífòyemọ̀, - Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù! 
(Tún wo Sm. 97:10; Jòh. 21:15-17; Fílí. 4:7.)