ORIN 112
Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, - Jọ̀ọ́, fún wa ní àlàáfíà - Tó o ṣèlérí pó o máa fún wa - Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. - Ìgbàgbọ́ tí a ní - Nínú Jésù Ọmọ rẹ - Ló mú ká sún mọ́ ọ, ká sì - Wà lálàáfíà pẹ̀lú rẹ. 
- 2. Ẹ̀mí rẹ ń ṣèrànwọ́ - Láyé tó ṣókùnkùn yìí. - Ọ̀rọ̀ rẹ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀, - Ó ń tọ́ wa, ó ń pa wá mọ́. - Láìpẹ́, Ìjọba rẹ - Yóò fòpin sí ‘ṣòro wa. - Ṣùgbọ́n báyìí, ràn wá lọ́wọ́ - Ká lè máa wà lálàáfíà. 
- 3. Àwa ìránṣẹ́ rẹ - Ní ọ̀run àti láyé, - O fìfẹ́ kó gbogbo wa jọ; - À ń kọ́wọ́ ti ’Jọba rẹ. - Láìpẹ́, yóò dé sáyé, - Yóò sì fòpin sí ogun. - Àwọn olódodo máa yọ̀, - Wọn yóò máa gbé lálàáfíà. 
(Tún wo Sm. 4:8; Fílí. 4:6, 7; 1 Tẹs. 5:23.)