ORIN 113
Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Yin Ọlọ́run àlàáfíà, - Ọlọ́run ìfẹ́. - Ó máa fòpin sí ogun, - Yóò mú ‘rẹ́pọ̀ wá. - Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi - Ọba Àlàáfíà, - Yóò ja ìjà òdodo; - Yóò málàáfíà wá. 
- 2. A kì í sọ̀rọ̀ búburú - Tó lè fa ìjà. - A ti dẹni àlàáfíà - Pẹ̀l’áwọn èèyàn. - Ó yẹ ká máa dárí ji - Àwọn tó ṣẹ̀ wá. - Yóò jẹ́ ká wà lálàáfíà - Bíi Jésù Kristi. 
- 3. Àlàáfíà Ọlọ́run wa - Máa ń mú ‘bùkún wá. - Àwọn òfin rẹ̀ dára; - A ó máa ṣègbọràn. - Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, - Ká wà lálàáfíà. - Láìpẹ́, àlàáfíà máa wà - Ní gbogbo ayé. 
(Tún wo Sm. 46:9; Àìsá. 2:4; Jém. 3:17, 18.)