ORIN 147
Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà ṣe ìlérí pé - Ayé yóò wà títí láé. - ‘Àwọn ọlọ́kàn tútù’ yóò - Wà láàyè títí láé. - (ÈGBÈ) - A ó wà láàyè láéláé, - Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Jáà. - Olóòótọ́ ni Baba. - Ọ̀rọ̀ rẹ yóò ṣẹ. 
- 2. Ayé yóò di Párádísè; - A ó dọmọ òmìnira. - Jèhófà yóò máa ṣàkóso, - Ayé yóò lálàáfíà. - (ÈGBÈ) - A ó wà láàyè láéláé, - Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Jáà. - Olóòótọ́ ni Baba. - Ọ̀rọ̀ rẹ yóò ṣẹ. 
- 3. Láìpẹ́ àwọn òkú yóò jí, - Ìbànújẹ́ kò sí mọ́. - Ọlọ́run yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ - Nu omijé wa nù. - (ÈGBÈ) - A ó wà láàyè láéláé, - Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Jáà. - Olóòótọ́ ni Baba. - Ọ̀rọ̀ rẹ yóò ṣẹ. 
(Tún wo Àìsá. 25:8; Lúùkù 23:43; Jòh. 11:25; Ìfi. 21:4.)