ORIN 23
Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso
- 1. Ìjọba Jáà ti bẹ̀rẹ̀. - Ẹ yin Kristi Ọba rẹ̀. - Olúwa wa ti ń ṣàkóso lọ́run. - Ẹ jẹ́ ká yin Ọlọ́run, - Kí gbogbo wa kọrin sí i, - Torí pé ó gbé - Kristi sórí ìtẹ́ Rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀? - Òótọ́ àti òdodo ni. - Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá? - Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀. - Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí - Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀. 
- 2. Kristi ń ṣàkóso báyìí. - Amágẹ́dọ́nì dé tán. - Láìpẹ́, ayé Èṣù yìí máa pa run. - Àkókò nìyí fún wa, - Ká wàásù fónírẹ̀lẹ̀, - Kí wọ́n lè dúró - sọ́dọ̀ Jèhófà lónìí. - (ÈGBÈ) - Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀? - Òótọ́ àti òdodo ni. - Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá? - Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀. - Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí - Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀. 
- 3. A mọyì Ọba wa yìí - Tí Ọlọ́run yàn fún wa. - Jáà ló fi jọba, a sì ń bọ̀wọ̀ fún un. - Ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà - Pé kó ṣojúure sí wa. - Láìpẹ́, yóò máa - jọba lórí ohun gbogbo. - (ÈGBÈ) - Kí n’Ìjọba Jèhófà ńmú bọ̀? - Òótọ́ àti òdodo ni. - Nǹkan mìíràn wo ni yóò mú wá? - Ìyè tòótọ́ àti ayọ̀. - Ẹ yin Ọba ‘láṣẹ torí - Ìfẹ́ àtòdodo rẹ̀. 
(Tún wo 2 Sám. 7:22; Dán. 2:44; Ìfi. 7:15.)