ORIN 38
Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
- 1. Ó nídìí t’Ọ́lọ́run fi jẹ́ kó o rí òótọ́, - Tó sì mú ọ wá sínú ìmọ́lẹ̀. - Ó rọ́kàn rẹ, ó rí gbogbo bó o ṣe ńsapá - Kóo lè sún mọ́ ọn, kó o lè ṣohun tó tọ́. - O ṣèlérí fún un pé wàá ṣèfẹ́ rẹ̀. - Ó dájú pé yóò máa ràn ọ́ lọ́wọ́. - (ÈGBÈ) - Ó fẹ̀jẹ̀ Jésù rà ọ́; - ti Jèhófà ni ọ́. - Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, - yóò fún ọ lágbára. - Yóò máa tọ́ ẹ sọ́nà, - yóò sì máa dáàbò bò ọ́. - Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, - yóò fún ọ lágbára. 
- 2. Ọlọ́run fọmọ rẹ̀ rúbọ nítorí rẹ, - Torí Ó fẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí. - B’Ọ́lọ́run kò ṣe fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dù ọ́, - Kò ní ṣàì fún ọ lókun tóo nílò. - Yóò rántí ìgbàgbọ́ àtìfẹ́ rẹ; - Ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ó fẹ̀jẹ̀ Jésù rà ọ́; - ti Jèhófà ni ọ́. - Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, - yóò fún ọ lágbára. - Yóò máa tọ́ ẹ sọ́nà, - yóò sì máa dáàbò bò ọ́. - Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, - yóò fún ọ lágbára. 
(Tún wo Róòmù 8:32; 14:8, 9; Héb. 6:10; 1 Pét. 2:9.)