ORIN 87
Ẹ Wá Gba Ìtura
- 1. Ayé Sátánì tá à ń gbé yìí burú gan-an; - A nílò ẹ̀kọ́ Ọlọ́run. - Torí kò sí ohun tí a lè dá ṣe, - Àfi ká rí ìtọ́sọ́nà. - Àwọn ìpàdé wa máa ń tuni lára; - Wọ́n ń jẹ́ ká túbọ̀ nírètí. - Wọ́n ń mú kígbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, - Wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí. - A ó máa rí i pé à ń wá sípàdé déédéé - Ká lè múnú Jèhófà dùn. - A gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n lo àkókò wa; - Ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. 
- 2. Jèhófà mọ àwọn ohun tá a nílò, - Ó sì ti pèsè wọn fún wa. - Ẹrú olóòótọ́ àtàwọn alàgbà; - Wọ́n ń fún wa nítọ̀ọ́ni tó dáa. - Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa, - Yóò ṣe wá lọ́pọ̀ àǹfààní. - Ẹgbẹ́ ará kárí ayé wà níbẹ̀, - Gbogbo wa nífẹ̀ẹ́ ara wa. - Ṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára, - A kò bẹ̀rù, a kò jáyà. - A ó máa rí i pé à ń wá sípàdé déédéé - Bá a ṣe ń retí ayé tuntun. 
(Tún wo Sm. 37:18; 140:1; Òwe 18:1; Éfé. 5:16; Jém. 3:17.)