ORIN 115
A Mọyì Sùúrù Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà, alágbára gíga; - Ìwọ fẹ́ràn ohun tó tọ́. - Ìwà búburú pọ̀ láyé, - Ó sì ń mú ká máa kérora. - A mọ̀ pé o ṣì máa fòpin sí i - Lákòókò tó tọ́ ní ojú rẹ. - (ÈGBÈ) - Ìrètí wa ń lágbára sí i, - A dúpẹ́, a yin orúkọ rẹ. 
- 2. Ẹgbẹ̀rún ọdún lójú èèyàn - Dà bí ọjọ́ kan lójú rẹ. - Ọjọ́ ńlá rẹ yóò dé láìpẹ́; - Kì yóò falẹ̀, béèyàn ṣe ń rò. - Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni o kórìíra, - O fẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ yí pa dà. - (ÈGBÈ) - Ìrètí wa ń lágbára sí i, - A dúpẹ́, a yin orúkọ rẹ. 
(Tún wo Neh. 9:30; Lúùkù 15:7; 2 Pét. 3:8, 9.)