ORIN 96
Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
(Òwe 2:1)
- 1. Ìwé kan wà tó ṣeyebíye jù lọ, - Tó ń mú ‘rètí, ayọ̀, àlàáfíà wá. - Ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ lágbára gan-an; - Ó ń lani lóye, ó ń fúnni níyè. - Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìwé yẹn. - Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ ọ́. - Àwọn èèyàn yìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an, - Ó sì fẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn. 
- 2. Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí ‘ṣẹ̀dá ṣe bẹ̀rẹ̀, - Bí Ọlọ́run ṣe dá àgbáyé yìí. - Wọ́n sọ bọ́kùnrin pípé náà ṣe dẹ́ṣẹ̀, - Tó sì pàdánù Párádísè náà. - Wọ́n sọ̀rọ̀ áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀, - Tó ta ko Ọlọ́run, tó fẹ̀sùn kàn án. - Èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àtikú fún wa, - Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Jèhófà yóò ṣẹ́gun! 
- 3. Inú wa ń dùn gan-an lákòókò táa wà yìí - Pé Jèhófà ti fọmọ rẹ̀ jọba. - Èyí ló ń mú ká wàásù ìhìnrere; - À ń sọ̀rọ̀ ìbùkún ọjọ́ ‘wájú. - Ìwé ìṣúra tí Jèhófà fún wa, - Gbogbo ayé ló máa ṣe láǹfààní. - Ìwé tó yẹ kí gbogbo wa máa kà ni; - Ó ń jẹ́ ká ní àlàáfíà Ọlọ́run. 
(Tún wo 2 Tím. 3:16; 2 Pét. 1:21.)