ORIN 83
“Láti Ilé dé Ilé”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Láti ilé délé. - Iṣẹ́ ìwàásù wa ń kárí - Gbogbo ilẹ̀ ayé. - Tọmọdé tàgbà wa ló ń ṣe - Iṣẹ́ pàtàkì yìí. - Káwọn èèyàn bàa lè mọ̀ pé - Jésù ti ń ṣàkóso. 
- 2. Báwo laráyé ṣe máa gbọ́ - Láìsí oníwàásù? - Báwo ni wọ́n ṣe máa ké pe - Ẹni tí wọn kò mọ̀? - Ó pọn dandan fún wa láti - Kọ́ wọn lọ́r’Ọlọ́run. - Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí - Máa jẹ́ kí wọ́n gbà là. 
- 3. Kí gbogbo wa lọ máa wàásù - Ìròyìn ayọ̀ náà. - Ó kù sọ́wọ́ àwọn èèyàn - Láti yàn fúnra wọn. - Ká jẹ́ kí gbogbo aráyé - Morúkọ Jèhófà, - Kí wọ́n sì fìyìn fún Jésù - Àti Ìjọba Rẹ̀. 
(Tún wo Ìṣe 2:21; Róòmù 10:14.)